“Jìbìtì Tí Ó Lókìkí Burúkú Jù Lọ Nínú Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀”
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRITAIN
Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, ọkùnrin Piltdown, tí wọ́n ṣàwárí ní 1912, ni “jìbìtì tí ó lókìkí burúkú jù lọ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ní ọ̀rúndún náà.” Ọdún 1953 ni wọ́n ṣí i payá pé ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn àyẹ̀wò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fi hàn pé, dípò kí ó jẹ́ ìsokọ́ra tí ó pòórá nínú àwọn ìsokọ́ra ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kan tí a finú rò nípa ibi tí ẹ̀dá ènìyàn ti wá, agbárí náà jẹ́ ti ènìyàn òde òní, tí párì ìsàlẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti elégbèdè kan. Ta ló gbé irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ kalẹ̀?
Fún ọ̀pọ̀ ọdún, a ti nàka ìfura sí Charles Dawson, amòfin tí ó tún jẹ́ ẹni tí ń fi ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ilẹ̀ àti ohun inú rẹ̀ pawọ́, tí ó rí òkú náà. Àwọn mìíràn tí a tún fura sí ni Alàgbà Arthur Keith, onítara ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tí ó tún jẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Àwọn Oníṣẹ́ Abẹ ti Aláyélúwà; òǹṣèwé ọmọ ilẹ̀ Britain náà, Alàgbà Arthur Conan Doyle; àti àlùfáà ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Pierre Teilhard de Chardin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹ̀rí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a wá ronú pé Dawson ló ṣe é.
Ní báyìí, a ti dárúkọ ọ̀daràn náà. Ẹni náà ni Martin A. C. Hinton, alábòójútó ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹranko tẹ́lẹ̀ rí ní Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Ìtàn Àdánidá ní London, tí ó kú ní 1961. Ní ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn, wọ́n ṣàwárí àpótí aṣọ ńlá kan tí ó jẹ́ ti Hinton nínú ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí náà. Wọ́n rí àwọn eyín erin, apá kan àkẹ̀kù erinmi kan, àti àwọn egungun mìíràn nínú rẹ̀, tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò kínníkínní. Wọ́n rí i pé ó ti fi èròjà iron àti manganese kun gbogbo rẹ̀ ní ìwọ̀n èyí tí ó fi kun àwọn egungun Piltdown náà. Àmọ́, kókó tí a fi gbá a mú gan-an ni ti èròjà chromium tí ó wà ní eyín náà, tí ó tún lò nígbà tí ó ń fi nǹkan kùn ún.
Ní sísọ òkodoro ọ̀títọ́ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Brian Gardiner, láti King’s College, London, sọ pé: “A mọ Hinton sí aṣẹ̀fẹ̀. . . . Àwọn lẹ́tà kan tí ó kọ fi èrò inú [rẹ̀] hàn.” Gardiner parí ọ̀rọ̀ pé: “Ó dá mi lójú bí àdá pé, òun ló ṣe é.” Ẹ̀rí náà fi hàn pé, Hinton ń wá ọ̀nà láti gbẹ̀san lára Arthur Smith Woodward, ọ̀gá rẹ̀, tí kò fún un ní àfiyèsí dáradára tàbí owó tí ó lérò pé ó jẹ́ ẹ̀tọ́ òun. Ó lu Woodward ní jìbìtì láìmọ̀, títí fi di ìgbà tí ó kú lọ́dún márùn-ún ṣáájú kí a tó tú gbàrọgùdù náà fó, ó fi ìdánilójú gbà pé ọkùnrin Piltdown jẹ́ ojúlówó. Ìbéèrè kan ṣoṣo tí a kò tí ì dáhùn ni pé, Kí ló dé tí Hinton kò jẹ́wọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Woodward fọwọ́ sí jìbìtì náà? Yóò jọ pé, ó jẹ́ nítorí pé ọkùnrin Piltdown ní ìtẹ́wọ́gbà kíákíá jákèjádò àwùjọ onímọ̀ ìjìnlẹ̀, Hinton ronú pé, òun kò ní yíyàn kankan àyàfi kí òun máà jẹ́wọ́.
Pẹ̀lú bí irú àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn bẹ́ẹ̀ ti fọwọ́ sí agbárí Piltdown, a tan àwọn aráàlù pẹ̀lú jẹ. Àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí jákèjádò ayé pàtẹ ẹ̀dà àti fọ́tò agbárí náà ní gbangba, tí àwọn ìwé àti àwọn ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà sì yára tan ìròyìn náà kálẹ̀. Àwọn àbáyọrí apanilára tí ẹ̀fẹ̀ tí Hinton ṣe pọ̀ jọjọ. Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Bíbélì náà ti bá a mu tó pé: “Bí òmùgọ̀ tí ń ju igi oníná, ọfà, àti ikú, ni ọkùnrin kan tí ó tan ẹlòmíràn jẹ tí ó sì wí pé ‘Mo ń ṣeré ni, ṣe o mọ̀!’ rí.”—Òwe 26:18, 19, Byington.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn ibi dúdú jẹ́ àfọ́kù agbárí ẹ̀dá ènìyàn
Gbogbo ibi mímọ́lẹ̀ tí a fi amọ̀ ṣe
Ibi dúdú jẹ́ àfọ́kù párì àti eyín elégbèdè