“N Kò Fìgbà Kankan Ṣàníyàn Láti Ka Jí!”
Ọ̀rọ̀ tí akẹ́kọ̀ọ́ kan, tí ń kọ́ Ẹ̀kọ́ Nípa Àyíká, ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ tí ó wà ní San Jose, California, sọ nìyẹn. Ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Mo lérò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn náà pé ìwé ìròyìn náà yóò wulẹ̀ wàásù fún mi pé—‘Máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì’ tàbí, ‘O gbọ́dọ̀ di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’ Síbẹ̀, nígbà tí mo ka ìtẹ̀jáde yìí (January 8, 1996, ‘Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Tí À Ń Wu Léwu—A Ha Lè Gbà Á Là Bí?’), ó yà mí lẹ́nu pé kókó ọ̀rọ̀ gidi ló sọ! Àwọn àpilẹ̀kọ náà ní àwòrán kan tí ó pèsè ìsọfúnni nípa ‘Díẹ̀ Lára Àwọn Lájorí Ìṣòro Àyíká Ayé,’ tí ó fi àwòrán ojú ilẹ̀ àwọn ibi tí pípa igbó run, pàǹtírí onímájèlé, bíba àyíká jẹ́, àìtó omi, àwọn ẹ̀yà ohun alààyè tí ó wà nínú ewu àkúrun, àti bíba ilẹ̀ jẹ́, ti ń ṣẹlẹ̀ hàn.
“Di báyìí, n kò tí ì bímọ, àmọ́ mo ń dààmú lórí bóyá bí mo bá bí, wọn yóò rí afẹ́fẹ́ mímọ́ gaara mí, àwọn ọgbà tí wọn ó ti máa ṣeré, tàbí omi mímu láti máa wà láàyè nìṣó. . . . Mo yìn yín fún àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí.”
Ní báyìí ìpínkiri Jí! jẹ́ mílíọ̀nù 18.3 nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan ní 80 èdè, tí 56 nínú wọn ń jáde nígbà kan náà. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti máa ka ìwé ìròyìn yí déédéé, jọ̀wọ́ kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ, lórí tẹlifóònù tàbí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.