“Ẹ Kó Ogójì Wá fún Mi. N Óò Pín Wọn”
Gẹ́gẹ́ bí apá kan iṣẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì wọn ní ìhà gúúsù Germany, Wolfgang àti aya rẹ̀, Waltraut, fi àwọn ẹ̀da Jí! lọ ọkùnrin kan ní ìgbà bíi mélòó kan. Ó máa ń kọ̀ ọ́, ó sì máa ń wí pé: “Mo ní ohun púpọ̀ láti kà.”
Síbẹ̀síbẹ̀, tọkọtaya náà wòye pé ọkùnrin náà lè ka àpilẹ̀kọ náà, “Mímú Èrò Òdì Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kúrò,” tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí!, November 22, 1996. Àpilẹ̀kọ náà sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan tí a sọ fún Ẹgbẹ́ Rotary kan ní California ní United States.
Nígbà tí Wolfgang ṣí ìwé ìròyìn náà sí ibi tí àpilẹ̀kọ náà wà, tí ó sì fi hàn ọkùnrin náà, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ó wá béèrè bí òun bá lè mú un dání. Ó sọ pé: “N óò kà á lálẹ́ yìí tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀, tí nǹkan sì dákẹ́ rọ́rọ́.”
Wolfgang àti aya rẹ̀ pàdé ọkùnrin náà ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà. Báwo ló ṣe hùwà pa dà? Ó sọ pé: “Àpilẹ̀kọ náà gbádùn mọ́ni.”
Kí ló jẹ́ kó wú u lórí tó bẹ́ẹ̀? Ó jọ pé òun pẹ̀lú ti ní àwọn èrò òdì kan nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá ronú pé dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ òun nínú Ẹgbẹ́ Rotary yóò gbádùn kíka àpilẹ̀kọ náà. Ó béèrè pé: “Ṣé o lè rí ẹ̀dá àpilẹ̀kọ náà díẹ̀ sí i?”
Waltraut béèrè pé: “Mélòó lo fẹ́?”
“Ẹ kó ogójì wá fún mi. N óò pín wọn.”
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan Jí! tàbí tí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé, fún ìsọfúnni, sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.