Yíyán Àwọn Ẹranko Ìgbẹ́
Bí ẹnì kan bá yán ní gbangba, àwọn ènìyàn lè rò pé kò mẹ̀yẹ ni—tàbí, pátápátá, pé ó rẹ̀ ẹ́ ni. Láìka ti ìlànà ìṣe sí, yíyán ní gidi ń ṣiṣẹ́ fún ète wíwúlò kan. Yíyán jẹ́ ìfatẹ́gùnsínú láìmọ̀ọ́mọ̀. A sábà ń yán ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tí àwọn ìgbòkègbodò ọjọ́ náà bá ti mú kí ó rẹ̀ wá tàbí ní òwúrọ̀ lẹ́yìn tí a bá jí. Yíyán jinlẹ̀ gan-an ń ṣiṣẹ́ láti mú kí ìpèsè afẹ́fẹ́ oxygen wa pọ̀ sí i, ó sì lè mú kí ara tù wá fún ìgbà díẹ̀; ó sábà máa ń jẹ́ apá kan ìgbésẹ̀ jíjí.
Àmọ́ ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ẹranko pẹ̀lú máa ń yán, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í sábà ṣe fún gbígba afẹ́fẹ́ lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i? Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fani lọ́kàn mọ́ra. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀bọ máa ń yán lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti lè sọ ohun kan. Ẹnu tí wọ́n fẹ̀ gbàgàdà náà àti ṣíṣí tí wọ́n ṣí eyín sílẹ̀ lọ́nà bíbanilẹ́rù náà jẹ́ ọ̀nà láti kìlọ̀ fún akọ ọ̀bọ abánidíje kan tàbí ẹnì kan tí ó lè fẹ́ pa á. Ìsọfúnni náà ni pé: ‘Ìbunijẹ mi lóró. Má ṣe sún mọ́ mi!’
A tún ti ṣàkíyèsí pé àwọn ológbò apẹranjẹ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Áfíríkà sábà máa ń nà, wọn óò sì yán kí wọ́n tó lọ dọdẹ. Bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn ènìyàn, yíyán àwọn ológbò ń ṣiṣẹ́ fún ète ìṣe àti ìgbòkègbodò ìwàláàyè—ti fífa afẹ́fẹ́ púpọ̀ sí i sínú ẹ̀dọ̀fóró. Èyí ń mú kí afẹ́fẹ́ oxygen tí ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i. Ọkàn àyà yóò wá sáré gbé e lọ sí àwọn apá ìbòmíràn lára, tí èyí sì ń pèsè agbára ojú ẹsẹ̀ fún fífi eré kikankikan lépa nǹkan ní ibi tí kò jìnnà.
Kódà, a ti ṣàkíyèsí pé àwọn ẹja pàápàá máa ń yán! Ìwé náà, Inside the Animal World, sọ nípa ẹja tí ó jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, “ó máa ń yán gẹ́gẹ́ bí àṣeṣáájú fún gbígbéra kánkán. . . . Ẹja kan lè yán pẹ̀lú nígbà tí ìmọ̀lára rẹ̀ bá ru sókè tàbí nígbà tí ó bá rí ọ̀tá kan tàbí tí ó bá rí oúnjẹ, ní gbogbo ìgbà tí ó bá nílò ìgbésẹ̀ yíyákánkán.”
Bóyá yíyán tí ń gbádùn mọ́ni jù lọ ni ti erinmi, tàbí Bẹhẹ́mọ́tù. Ẹ̀dá títóbi fàkìà yí lè ya ìyẹ̀wù ẹnu rẹ̀ fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ dé ìwọ̀n igun 150! Yíyán náà ń jẹ́ kí ògbólógbòó akọ erinmi kan lè fi ẹni tí ó jẹ́ ọ̀gá han olúkúlùkù erinmi tí ó wà nínú adágún omi tí ó wà. Ó tún ń ṣiṣẹ́ láti fi eyín hàn gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún olùyọjúràn tí yóò fẹ́ láti ṣàfojúdi wọ inú odò tí ó ń gbé.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣàìmú ipò ìbúramúramù kìnnìún kan wá sọ́kàn, yíyán kan—yálà ó jẹ́ yíyàn àtisùn, ti ìhalẹ̀mọ́ni, tàbí ti fífa agbára lásán ni—ń ṣiṣẹ́ fún ète ṣíṣàǹfààní kan. Ó wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan sí i nípa àgbàyanu ọgbọ́n ìṣẹ̀dá Olùṣàgbékalẹ̀ àwùjọ ẹranko!