Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 26. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde náà, “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń fàyè gba àwọn elénìní rẹ̀ láti ṣẹ́gun àwọn ènìyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́, èé ṣe tí ó tún wá ń gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn? (Diutarónómì 32:27; Aísáyà 64:2; Náhúmù 1:2)
2. Orúkọ wo ni Réṣẹ́ẹ̀lì sọ ọmọkùnrin rẹ̀ kejì bí ó ṣe ń kú lọ nígbà ìbímọ? (Jẹ́nẹ́sísì 35:18)
3. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi àwọn ohun ìjà tẹ̀mí ti Kristẹni wé àwọn ti ìjà ogun ti ara, kí ló fi ìgbàgbọ́ wé? (Éfésù 6:16)
4. Nígbà tí Dáfídì ń sá lọ fún Ọba Sọ́ọ̀lù, ọ̀dọ̀ ọba wo ni ó ti rí ibi ìsádi? (Sámúẹ́lì Kíní 27:2)
5. Ní ìsanpadà fún kí ni Èṣù ṣèlérí pé òun yóò fún Jésù ní gbogbo àwọn ìjọba ilẹ̀ ayé? (Lúùkù 4:5-7)
6. Ìgbésẹ̀ kíákíá wo ni Fíníhásì gbé tí ó fòpin sí òjòjò àrànkálẹ̀ tí ó pa 24,000 ọmọ Ísírẹ́lì? (Númérì 25:7-9, NW)
7. Nípa lílo èdè wo ni Jóòbù fi tọ́ka sí i pé òun ti yẹ ikú sílẹ̀ lọ́nà tí kò ṣeé ṣàpèjúwe? (Jóòbù 19:20, NW)
8. Igi dúdú wo ni a sábà ń lò pẹ̀lú eyín erin láti fi ṣe ọ̀ṣọ́ inú ilé? (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 27:15)
9. Nítorí ìdí wo ni ọba Ásíríà náà, Tigilati-pílésà, ṣe gbógun ti Síríà, tí ó ṣẹ́gun Damásíkù, tí ó sì kó àwọn ìgbèkùn rẹ̀ lọ sí Kírì? (Àwọn Ọba Kejì 16:7-9)
10. Lẹ́yìn tí Dáfídì gbọ́ pé ọmọkùnrin àkọ́kọ́ tí Bátí-ṣébà bí fún òun ti kú, kí ni ó ṣe tó ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní kàyéfì? (Sámúẹ́lì Kejì 12:21)
11. Kí ni Jésù pè ní “fìtílà ara”? (Mátíù 6:22)
12. Lọ́nà wo ni Jèhófà sọ pé òun yóò gbà fa Gọ́ọ̀gù sínú ìgbóguntì rẹ̀ ìkẹyìn lòdì sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run? (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:4)
13. Lórí òkú ta ni Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì náà ti ṣe awuyewuye pẹ̀lú Èṣù? (Júúdà 9)
14. Ewéko wo ni Ọlọ́run pèsè láti ṣíji bo Wòlíì Jónà lẹ́yìn iṣẹ́ ìjíhìn rẹ̀ ní Nínéfè? (Jónà 4:6, NW)
15. Nítorí tí inú rẹ̀ dùn nígbà tí Ẹ́sítérì di ayaba rẹ̀, kí ni Ahasuwérúsì yọ̀ǹda fún àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ rẹ̀? (Ẹ́sítérì 2:18, NW)
16. Ta ni wọ́n fipá mú láti ṣèrànwọ́ láti ru òpó igi oró Jésù? (Lúùkù 23:26)
17. Àtọmọdọ́mọ Júdà wo ni kò ní ọmọkùnrin, tí ó wá fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ ará Íjíbítì, kí ìlà ìdílé rẹ̀ lè máa wà nìṣó? (Kíróníkà Kíní 2:34, 35, NW)
18. Kí Réṣẹ́ẹ̀lì tó kú nígbà ìbímọ, ìdánilójú wo ni agbẹ̀bí rẹ̀ fún un? (Jẹ́nẹ́sísì 35:17)
19. Àwọn èròjà wo tí a ń lò fún ìtọ́jú ẹwà ni a fi fún Ẹ́sítérì àti àwọn obìnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀? (Ẹ́sítérì 2:12, NW)
20. Ta ló mú ọ̀ràn àfirọ́pò fún Júdásì aláìṣòótọ́ wá sí àfiyèsí? (Ìṣe 1:15-22)
21. Ta ni bàbá Jésíbẹ́lì? (Àwọn Ọba Kìíní 16:31)
22. Àwọn ọkùnrin méjì wo ni Jèhófà fi sídìí àbójútó kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn? (Ẹ́kísódù 31:2, 6)
23. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fúnni nípa bíbúra láìnídìí? (Mátíù 5:37)
24. Ewéko olóòórùn dídùn wo ni ó jẹ́ pé Jésù nìkan ló mẹ́nu bà á nínú Bíbélì? (Mátíù 23:23)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Nítorí orúkọ mímọ́ rẹ̀—láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè agbéraga àti afọ́nnu wọ̀nyẹn sílẹ̀
2. Bẹni-ónì
3. Apata ńlá kan
4. Ọba Ákíṣì ti Gátì
5. “Ìṣe ìjọsìn kan”
6. Ó fi aṣóró kan gún ọkùnrin àti obìnrin náà ní àgúnyọ
7. “Ṣínńṣín, bí awọ eyín mi”
8. Igi eboni
9. Ọba Áhásì ti ilẹ̀ Júdà fún un ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀
10. Ó já ààwẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun
11. Ojú
12. Fífi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́
13. Òkú Mósè
14. Ewéko akèrègbè
15. Ìdáríjì ọba
16. Símónì ti Kírénè
17. Ṣéṣánì
18. Pé yóò bí ọmọkùnrin rẹ̀ láàyè
19. Òróró òjíá àti òróró básámù
20. Pétérù
21. Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì
22. Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù
23. “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́”
24. Efinrin