Ohun Kan Tó Sàn Ju Òkìkí Ayé Lọ
Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí mo di gbajúmọ̀ oníṣẹ́ ọnà gbígbẹ́ ní Europe, oníṣẹ́ ọnà ẹlẹgbẹ́ mi kan fẹ̀sùn kàn mí pé: “O ti já iṣẹ́ ọnà kulẹ̀!” Kí n tó sọ ìdí tó ṣe fi ẹ̀sùn yẹn kàn mí, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe di oníṣẹ́ ọnà gbígbẹ́.
NÍ ABÚLÉ Aurisina, tí wọ́n ti bí mi, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọkùnrin ibẹ̀ ní ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ àtijọ́ kan tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta. Aurisina wà ní ìhà àríwá Ítálì nítòsí Trieste, kò sì jìnnà sí Yugoslavia àtijọ́. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún 15, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ tí a ti ń fọ́ òkúta ní abúlé náà. Ìyẹn jẹ́ ní 1939, ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Ṣíṣiṣẹ́ nídìí òkúta mú kí n fẹ́ láti di olókìkí oníṣẹ́ ọnà gbígbẹ́. Mo sì fẹ́ kí n máà kú títí ayé. Àwọn ìfẹ́ ọkàn méjèèjì jọ èyí tí kò lè ṣeé ṣe.
Nígbà tí ogun náà parí ní 1945, mo kó lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ní Róòmù. Níbẹ̀, mo ní in lọ́kàn láti forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọnà. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó nígbà tí ìfẹ́ ọkàn mi ṣẹ, tí wọ́n sì gbà mí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún mẹ́ta! Onírúurú àwọn àjọ tí ń pèsè ọrẹ àánú ló pèsè owóòná fún ẹ̀kọ́ mi.
Ebi Tẹ̀mí
Mo tún wá ọ̀nà láti paná ebi tẹ̀mí tí ń pa mí nípa lílọ sí àwọn ibi ìjọsìn, títí kan àwọn ti Ọmọ Ogun Ìgbàlà àti Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo. Mo tilẹ̀ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì àwọn onísìn Jesuit kan, lẹ́ẹ̀kan, mo sì lọ sí àpérò ọlọ́jọ́ mẹ́ta kan tí bíṣọ́ọ̀bù kan ti dáni lẹ́kọ̀ọ́. Lákòókò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, wọn kò gbà wá láyè láti bá ara wa sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n a gbájú mọ́ àdúrà, àṣàrò, ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bíṣọ́ọ̀bù náà.
Nígbà tó yá, mo wá mọ̀ pé ìgbàgbọ́ mi kò tí ì mókun. Mo bi bíṣọ́ọ̀bù náà léèrè pé: “Kí ló dé tí n kò tí ì mú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára dàgbà?”
Bíṣọ́ọ̀bù náà dáhùn pé: “Ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìgbàgbọ́ jẹ́, ẹni tí ó bá sì fẹ́ ló máa ń fi fún.” Ìdáhùn rẹ̀ já mi kulẹ̀ gan-an tí n kò fi wá Ọlọ́run mọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọnà mi nìkan.
Níní Òkìkí Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-Èdè
Lẹ́yìn tí mo jáde ilé ẹ̀kọ́ ní Róòmù ní 1948, mo gba ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ ọlọ́dún kan láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọnà ní Vienna, Austria. Mo parí ẹ̀kọ́ mi níbẹ̀ ní ọdún tó tẹ̀ lé e, mo sì gba ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi ní Ljubljana, Slovenia (tí ó jẹ́ apá kan Yugoslavia àtijọ́). Góńgó tí mo ń lépa nígbà náà ni láti lọ sí Paris, ilẹ̀ Faransé, ibùjókòó iṣẹ́ ọ̀nà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní 1951, wọ́n fún mi ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́ ní Stockholm, Sweden. Mo kó lọ síbẹ̀ pẹ̀lú èrò àtifi owó pa mọ́ kí n lè fi ran ara mi lọ́wọ́ láti lọ máa ṣe iṣẹ́ ọnà bí iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe mi ní Paris. Ṣùgbọ́n nígbà náà ni mo wá pàdé Micky, a sì ṣègbéyàwó ní 1952, a sì fi Stockholm ṣe ibùjókòó. Mo rí iṣẹ́ kan ní ilé iṣẹ́ kékeré kan níbi tí mo ti ń gbẹ́ òkúta, mábìlì, àti akọ òkúta. A fi díẹ̀ lára wọn pàtẹ ní Millesgarden, ọgbà ìtura àti ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí kan ní ìlú Lidingö, nítòsí Stockholm.
Mo ti kọ́ nípa ọ̀nà àtijọ́ kan tí a ń gbà rọ idẹ ní Róòmù—ìlànà àtè rírá—mo sì ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa rírọ idẹ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Ọnà àti ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Iṣẹ́ Ọnà ní Stockholm. Lẹ́yìn náà, wọ́n fún mi ní àǹfààní wíwọ ilé kan tí a ti ń rọ idẹ ní ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ìtagbangba ti Skansen ní Stockholm. Níbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà níwájú àwùjọ àwọn ènìyàn, ń óò fi idẹ tàbí òjé gbẹ́ nǹkan. Wọ́n tún háyà mi láti ṣàtúnṣe àwọn iṣẹ́ ọnà gbígbẹ́ àtọjọ́mọ́jọ́ tí wọ́n jẹ́ ti ọba ilẹ̀ Sweden ìgbà náà, Gustav Kẹfà, sí bí wọ́n ṣe rí tẹ́lẹ̀. Ìwọ̀nyí wà níbi tí a pàtẹ wọn sí ní Ààfin Aláyélúwà àti ní ilé olódi Drottningholm ní Stockholm.
Láàárín 1954 sí 1960, àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde àti àwọn aṣelámèyítọ́ iṣẹ́ ọnà kan sárá sí iṣẹ́ mi. Ọ̀pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ ọnà tí mo gbẹ́ ni wọ́n pàtẹ sójútáyé ní àwọn ìlú pàtàkìpàtàkì ní Europe, títí kan Stockholm, Róòmù, Ljubljana, Vienna, Zagreb, àti Belgrade. Ní Belgrade, Marshal Tito ra díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ọnà tí mo gbẹ́ fún àkójọ àdáni rẹ̀. Wọ́n pàtẹ àárín ara obìnrin kan títóbi tí mo fi akọ òkúta gbẹ́ níbi Àkójọ Iṣẹ́ Ọnà Ìgbàlódé ní Róòmù, wọ́n sì pàtẹ àwọn iṣẹ́ ọnà tí mo gbẹ́ sí ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Albertina ní Vienna. Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ọnà tí mo fi idẹ àti òjé gbẹ́ wà ní ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Ìgbàlódé ní Stockholm, iṣẹ́ ọnà mi kan tí mo fi idẹ gbẹ́ sì wà ní ibi Àkójọ Iṣẹ́ Ọnà Ìgbàlódé ní Ljubljana.
Mo Lọ́kàn Ìfẹ́ sí Ìsìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I
Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí a ti ṣègbéyàwó, Micky ṣàkíyèsí pé ọkàn ìfẹ́ mi ti ń sọjí pa dà sípa ìsìn. Mo ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ibo ni ìgbàgbọ́ tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe tán láti kú fún wà?’ Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn, bíi ti àwọn onísìn Pentecostal àti Adventist. Mo tilẹ̀ wádìí wò nípa ìsìn Ìsìláàmù àti ìsìn Búdà.
Ní 1959, kí n tó lọ síbi ìpàtẹ iṣẹ́ ọnà kan ní Milan, Ítálì, mo ṣèbẹ̀wò sí abúlé mi ní Aurisina fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Àwọn ará abúlé wí fún mi nípa ọkùnrin kan tí wọ́n sọ pé ó ní ìmọ̀ púpọ̀ nípa Bíbélì. Ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo ní àǹfààní láti bá a sọ̀rọ̀, ó fi àwọn ohun kan tí n kò tí ì rí rí hàn mí nínú Bíbélì. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ènìyàn jẹ́ ọkàn kan—kò ní ọkàn kan tí ó dá yàtọ̀ sí ara rẹ̀—àti pé ọkàn ènìyàn lè kú, kì í ṣe aláìlèkú bí àwọn ìsìn míràn ti ń fi kọ́ni.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4.
Síwájú sí i, ọkùnrin náà fi hàn mí pé nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, kì í ṣe ète rẹ̀ pé kí wọ́n máa kú, ṣùgbọ́n pé kí wọ́n máa yọ̀ títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Tọkọtaya àkọ́kọ́ náà kú nítorí pé wọ́n ṣe àìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15-17) Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé nípa pípèsè Ọmọkùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà, Ọlọ́run pèsè fún ẹ̀dá ènìyàn láti gbádùn ìfojúsọ́nà fún ìyè ayérayé, tí àìgbọràn Ádámù ti mú kí a pàdánù. (Jòhánù 3:16) Mo láyọ̀ gidigidi láti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun wọ̀nyí.—Orin Dáfídì 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.
Àkókò Ìyípadà Ńlá Kan
Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo pa dà sí Sweden, èmi àti Micky sì gbìyànjú láti wá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn. Àmọ́, a kò rí àdírẹ́sì wọn kankan. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, agogo ilẹ̀kùn wa dún, wọ́n sì wà lẹ́nu ọ̀nà wa! Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fi sílẹ̀ fún mi, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí ó fi dá mi lójú pé òtítọ́ wà nínú rẹ̀. Síbẹ̀, mo fẹ́ láti fìdí èrò mi múlẹ̀ nípa sísọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ kan, bíṣọ́ọ̀bù àgbà kan nínú ìjọ Kátólíìkì, tí mo jẹ́ ojúlùmọ̀ rẹ̀ nígbà tí mo ń kẹ́kọ̀ọ́ ní Róòmù láàárín àwọn ọdún tó kẹ́yìn àwọn ọdún 1940. Nítorí náà, ní January 1961, mo lọ rí i.
Ọ̀rẹ́ mi ló ń bójú tó gbogbo ìgbòkègbodò àwọn míṣọ́nnárì Kátólíìkì ní gbogbo àgbáyé nígbà náà. Ẹ wo irú ìyàlẹ́nu tí ń dúró dè mí! Ẹnu yà mí gidigidi láti mọ̀ pé bíṣọ́ọ̀bù àgbà náà kò tilẹ̀ ní ìmọ̀ àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú Bíbélì. Nígbà tí a ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá kú, ó wí pé: “Ohun tí a gbà gbọ́ nísinsìnyí lè wá já sí òdì kejì pátápátá.” Nígbà tí a sì jíròrò títọ́ka tí àpọ́sítélì Pétérù tọ́ka sí ìlérí Bíbélì nípa “àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun kan,” ohun tí ìlérí yìí túmọ̀ sí kò dá a lójú.—Pétérù Kejì 3:13; Aísáyà 65:17-25.
Nígbà tí mo pa dà sí Stockholm, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí, tí èmi àti aya mi ti di ojúlùmọ̀ rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Inú mi dùn láti rí bí ìfẹ́ tí Micky ní fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń pọ̀ sí i. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní February 26, 1961, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi, Micky sì ṣèrìbọmi lọ́dún tó tẹ̀ lé e.
Ṣíṣe Àwọn Ìyípadà Lẹ́nu Iṣẹ́
A bí ọmọbìnrin kan ní 1956 àti ọmọkùnrin jòjòló kan ní 1961. Nítorí tí a ti ní ìdílé kan láti pèsè fún báyìí, mo nílò iṣẹ́ gidi kan. Inú mi dùn nígbà ti mo rí ìkésíni kan gbà láti gbẹ́ ère ìrántí ńlá kan sí abúlé tí wọ́n ti bí mi. Yóò jẹ́ fún ìrántí àwọn ajagun abẹ́lẹ̀ tí wọ́n kú nínú Ogun Àgbáyé Kejì. Ère ìrántí náà ì bá ti jẹ́ iṣẹ́ tó mówó wọlé fún mi. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn gbígbé oríṣiríṣi kókó abájọ yẹ̀ wò—títí kan òtítọ́ náà pé n óò fi ìdílé mi àti ìjọ Kristẹni sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù, àti pé n óò lọ máa gbé ní ilẹ̀ kan tí ètò ìjọba Kọ́múníìsì ti gbilẹ̀, tí kò sì ní rọrùn láti lépa ire tẹ̀mí—n kò gba iṣẹ́ tí wọ́n fi lọ̀ mí náà.
Iṣẹ́ mìíràn kó mi sínú ìṣòro ẹ̀rí ọkàn. Wọ́n ní kí n ṣe ohun ọ̀ṣọ́ ńlá kan fún ibi ìsìnkú tuntun kan ní Sweden. Nígbà tí mo parí rẹ̀, wọ́n pè mí síbi ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn tí mo mọ̀ pé bíṣọ́ọ̀bù Stockholm ni yóò ṣíṣọ lójú iṣẹ́ mi, mo pinnu láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà wọn forí gbárí tààràtà pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Kọ́ríńtì Kejì 6:14-18.
Nítorí àìdánilójú nípa rírí iṣẹ́ tí ń lọ déédéé gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ ọnà gbígbẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòro fún mi láti pèsè ohun púpọ̀ tó fún àwọn àìní ìdílé mi nípa ti ara. (Tímótì Kíní 5:8) Tàdúràtàdúrà ni mo ronú nípa ohun tí mo lè máa ṣe jẹun. Lẹ́yìn náà, ayàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé kan gbé àpẹẹrẹ àwòrán ilé kan tí ó yà wá bá mi. Ó ní kí n ya fọ́tò rẹ̀. Níwọ̀n bí mo ti mọ̀ nípa fọ́tò yíyà dáradára nítorí ìrírí mi nínú yíya fọ́tò àwọn iṣẹ́ ọnà gbígbẹ́ mi, ó dùn mọ́ mi láti gba iṣẹ́ náà. Láàárín àwọn ọdún wọ̀nyẹn, àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé ńláǹlà ń lọ lọ́wọ́ ní Sweden, àìní sì wà fún yíya fọ́tò àwọn àpẹẹrẹ àwòrán ilé. Nípa bẹ́ẹ̀, mo rí iṣẹ́ púpọ̀ gan-an gbà lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ayàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé, mo sì lè pèsè fún ìdílé mi dáradára.
Àárín àkókò yí ni mo ṣèbẹ̀wò sí Àjọ Ohun Ìṣẹ̀dálẹ̀ Ítálì ní Stockholm láti kópa nínú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Mo mọ olùdarí àjọ náà, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti ṣètò láti bá a sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí ó mọ̀ pé n kò ṣe iṣẹ́ ọnà gbígbẹ́ mọ́ ló kígbe pé: “O ti já iṣẹ́ ọnà kulẹ̀!” Mo ṣàlàyé pé mo ní àwọn iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe tí ó wà nípò kíní sí Ọlọ́run àti ìdílé mi.
Mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé fún àkókò kan, iṣẹ́ ọnà ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Síbẹ̀síbẹ̀, mo wá mọ̀ pé bí mo bá ń bá iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe mi lọ, yóò jọ bíi pé mo ń gbìyànjú láti sin ọ̀gá méjì. (Mátíù 6:24) Ó dá mi lójú pé ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí mo lè ṣe ni wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nítorí náà, mo dá ṣe ìpinnu láti fi iṣẹ́ ọnà gbígbẹ́ tí mo ń ṣe sílẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run sì ti bù kún ìpinnu mi lọ́nà kíkọyọyọ.—Málákì 3:10.
Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Kristẹni
Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣí wá sí Sweden láti ìhà gúúsù àti ìhà ìlà oòrùn Europe bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìfẹ́ hàn sí òtítọ́ Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, bẹ̀rẹ̀ ní 1973, mo ní àǹfààní bíbá àwọn aṣíwọ̀lú tí ń sọ èdè Italian, Spanish, àti Serbo-Croatian ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti ṣèrànwọ́ láti dá àwọn ìjọ tuntun àti àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ fún àwùjọ àwọn tí ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí. Wọ́n yàn mí láti ṣètò àwọn àpéjọpọ̀ Kristẹni ní èdè Italian àti láti bójú tó àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn àpéjọpọ̀ náà. Nígbà tí àìní bá wà fún un, mo tún ní àǹfààní sísìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní bíbẹ àwọn ìjọ wò ní Sweden.
Ní àbáyọrí ṣíṣèrànwọ́ láti ṣètò fún àwọn àpéjọpọ̀ lédè Italian ní Sweden, mo kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Róòmù. Àwọn ará tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ítálì sọ fún mi pé àwọn alàgbà kò tó nínú ìjọ ní Ítálì nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí ń gbèrú sí i lọ́nà gígadabú níbẹ̀. Nítorí náà, ní 1987, èmi àti Micky kó lọ sí Liguria, nítòsí Genoa, Ítálì. Nígbà yẹn, àwọn ọmọ wa ti dàgbà, wọ́n sì ti ń dá gbọ́ bùkátà ara wọn. A gbádùn ọdún méjì tí a lò ní Ítálì lọ́nà àgbàyanu, a sì kópa nínú dídá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ ní Liguria. A rí ìmúṣẹ òtítọ́ ọ̀rọ̀ inú Òwe 10:22 (NW) lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀.”
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èmi àti Micky máa ń gbìyànjú láti ṣàkópọ̀ àwọn ìbùkún ṣíṣekókó tí a ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, wọn kò mọ níwọ̀n. Ní àfikún sí kíkópa nínú dídá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún wa láti ran àwọn ènìyàn bíi mélòó kan lọ́wọ́, títí kan àwọn ọmọ wa, dórí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi àti lẹ́yìn náà dórí dídi Kristẹni tí ó dàgbà dénú. N kò kábàámọ̀ nípa ìpinnu mi láti jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí gbajúmọ̀ oníṣẹ́ ọnà gbígbẹ́, nítorí pé mo ti yan iṣẹ́ ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ ń mérè wá náà, sísin Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ náà, Jèhófà. Èmi àti àwọn olólùfẹ́ mi ti tipa bẹ́ẹ̀ rí ìrètí fífẹsẹ̀múlẹ̀ kan fún ìyè ayérayé gbà, ọpẹ́ ni fún Jèhófà.—Bí Celo Pertot ṣe sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Mo ń gbẹ́ ọnà kan ní 1955
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Pẹ̀lú aya mi