Fífami Láti Inú Kùrukùru
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ AMERICA
ÀWỌN olùṣèwádìí tí ń ṣiṣẹ́ ní Chile ti ṣàṣeyọrí ní ṣíṣàmúlò ọ̀nà àtijọ́ kan tí àwọn ará Arébíà ń gbà fa omi láti inú kùrukùru. Lẹ́tà ìròyìn Health InterAmerica ṣàlàyé pé: “Omi inú kùrukùru tó ń gbára jọ sórí àwọn ewé, tí ó wá ń kán sínú àwọn àgbá kéékèèké tí a ṣe sí ẹsẹ̀ àwọn igi ólífì, ti ń bomi rin àwọn igi náà nínú aṣálẹ̀ Oman fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.” Dípò àwọn igi ólífì, àwọn olùṣèwádìí na àwọn àwọ̀n ńlá sí àgbègbè olókè ní aṣálẹ̀ ibi tí kùrukùru, tí òkun máa ń gbé wá, ń bò déédéé. Àwọn àwọ̀n tí wọ́n jọ àwọ̀n ńlá tí a ń ta síbi ìṣeré volleyball náà ń gba ẹ̀kán omi láti inú kùrukùru náà sára. Èyí ń kán sínú gọ́tà kan tí ó lọ sínú páìpù kan, tí ń gbé omi náà lọ sínú àgbá omi kan.
Chungungo, abúlé kékeré kan tí ó wà ní aṣálẹ̀ etíkun àríwá Chile, ti fẹ̀rí hàn pé ìlànà náà gbéṣẹ́. Ìwé ìròyìn IDRC Reports, tí Ibùdó Ìṣèwádìí Ìṣẹ̀lẹ̀ Tuntun Kárí Ayé ní Kánádà gbé jáde, sọ pé, lọ́dún 14 sẹ́yìn, àwọn olùgbé Chungungo kò ní orísun omi aláìníyọ̀ kankan ládùúgbò wọn. Àwọn ọkọ̀ olómi máa ń gbé omi 5,000 lítà wá lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, ìdílé kọ̀ọ̀kan sì nílò lítà 3 sí 14 lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọpẹ́lọpẹ́ àwọ̀n 75 tí a nà sórí òkè ńlá tí ó yọ sókè abúlé náà tí ń gba omi inú kùrukùru lónìí, ọ̀pọ̀ yanturu omi tí ó jẹ́ 11,000 lítà ń ṣàn wọ Chungungo, tí ó sì ń pèsè 30 lítà omi fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ará abúlé náà lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Olùṣèwádìí náà, Òmọ̀wé Robert Schemenauer, onímọ̀ physics nípa kùrukùru, sọ pé, ìlànà fífa omi inú kùrukùru ti mú kí ìlera àwọn tí ń gbé àwọn abúlé sunwọ̀n sí i. “Olúkúlùkù ń jẹ ewébẹ̀ àti èso tí wọ́n já láti inú ọgbà ewébẹ̀ àti ọgbà igi eléso tiwọn fúnra wọn.”
Kì í ṣe pé omi láti inú kùrukùru dára fún ìlera pípé nìkan ni, àmọ́ kò wọ́n pẹ̀lú. Ọ̀mọ̀wé Schemenauer sọ pé, ìgbékalẹ̀ àwọ̀n abọ́ọ́dé kan ń náni tó 75,000 dọ́là (ti United States) ní ìfiwéra pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là tí a nílò láti ṣe ìsédò kan. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ilẹ̀ gbígbẹ mìíràn lágbàáyé lè jàǹfààní láti inú ìlànà yí, àwọn àjọ àgbáyé kò jára mọ́ gbígbà pé èyí jẹ́ ọ̀nà míràn tí a lè fi máa pèsè omi.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Lápá òsì: Àwọn àwọ̀n, tí ń gbá ẹ̀kán omi inú kùrukùru jọ, lórí àwọn òkè ńlá
Nísàlẹ̀: Àwòrán nẹ́ẹ̀tì tí a sún mọ́ dáradára
[Credit Line]
Àwọn fọ́tò: IDRC