Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(O lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 27. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde náà, “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
D1. Iṣẹ́ wo ni wọ́n mọ̀ mọ Jésù ní àgbègbè ìbílẹ̀ rẹ̀? (Máàkù 6:3)
2. Ní Róòmù, Kristẹni wo ni ìyá rẹ̀ jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí Pọ́ọ̀lù tí Pọ́ọ̀lù fi pe obìnrin náà ní ìyá òun? (Róòmù 16:13)
3. Ní Hébúrónì, àwọn amí tí Mósè rán jáde rí àwọn ọkùnrin wo tí ìtóbi wọn lọ́nà arà ọ̀tọ̀ dẹ́rù bá àwọn mẹ́wàá lára wọn gan-an tí wọ́n fi bẹ̀rù láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà? (Númérì 13:22, 32, 33)
4. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n tí wọ́n ń lò láyé ìgbàanì, báwo ni òróró ólífì tí wọ́n ń fi ṣe ìfòróróyàn mímọ́ ti pọ̀ tó? (Ẹ́kísódù 30:24)
5. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí “orúkọ ènìyàn búburú”? (Òwe 10:7)
6. Ibo ni ìtọ̀wọ́ ìsìnkú Jékọ́bù dúró sí fún ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣọ̀fọ̀ kí wọ́n tó sin ín ní hòrò Mákípẹ́là? (Jẹ́nẹ́sísì 50:10)
7. Kí ló dé tí Ọba Páṣíà náà, Ahasuwérúsì, fi pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ láti lọ mú Ayaba Fáṣítì wá síwájú òun? (Ẹ́sítà 1:10, 11)
8. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló ṣamọ̀nà sí ikú Ábúsálómù? (Sámúẹ́lì Kejì 18:9)
9. Kí ni Kálébù gbé kalẹ̀ bí ẹ̀bùn fún ẹni yòó wù tó bá lè ṣẹ́gun Déb írì? (Jóṣúà 15:16)
10. Ní fífi ipò jíjẹ́ ẹni ayérayé rẹ̀ hàn, àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà fi ṣàpèjúwe ara rẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá? (Ìṣípayá 1:8; 21:6)
11. Kí ni ẹ̀wù ìbílẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣọ̀fọ̀ ní àkókò tí a kọ Bíbélì? (Jẹ́nẹ́sísì 37:34)
12. Nígbà tí ó ń kọ ìkésíni Dáfídì, ta ni Básíláì dámọ̀ràn pé kí ó gba ipò òun ní ààfin ọba? (Sámúẹ́lì Kejì 19:37)
13. Nípa sísọ ohun wo ni wọ́n fi dá Pọ́ọ̀lù sí lọ́wọ́ ìnàlọ́rẹ́ nígbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù? (Ìṣe 22:24-29)
14. Ibo ni Ọba Sọ́ọ̀lù ti kàn sí abókùúsọ̀rọ̀? (Sámúẹ́lì Kíní 28:7)
15. Lọ́nà ìfiṣeyẹ̀yẹ́, kí ni àwọn ará Róòmù fi sí ọwọ́ ọ̀tún Jésù, tí wọ́n wá ń fi gbá a ní orí lẹ́yìn náà? (Mátíù 27:29, 30)
16. Aṣẹ́wó tẹ́lẹ̀ rí wo ló wá di ìyá ńlá Jésù? (Mátíù 1:5)
17. Òkúta mímú wo ní Sípórà, ìyàwó Mósè, fi kọlà fún ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ìjábá? (Ẹ́kísódù 4:25, NW)
18. Nípa kí ni a óò dá àwọn tí a bá jíǹde lẹ́jọ́? (Ìṣípayá 20:12)
19. Orúkọ ta ló túmọ̀ sí “Alátakò”? (Sekaráyà 3:1)
20. A kò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀sùn kan tí a bá fi kan “àgbà ọkùnrin” kan àyàfi tí a bá fi kí ni tì í lẹ́yìn? (Tímótì Kíní 5:19)
21. Ta ló fàṣẹ ọba mú Jeremáyà lórí ẹ̀sùn èké náà pé ó ń gbìyànjú láti sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Bábílónì? (Jeremáyà 37:13, 14)
22. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ákáánì, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wo ló ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Jóṣúà 7:4, 5)
23. Ẹnì kan tó dáńgájíá tí kò bá fẹ́ láti ṣiṣẹ́ ni a kò gbọ́dọ̀ gbà láyè láti ṣe ki ni? (Tẹsalóníkà Kejì 3:10)
24. Nítorí pé wọ́n burú, àwọn ọmọkùnrin Júdà méjì wo ni Jèhófà pa? (Jẹ́nẹ́sísì 38:7-10)
25. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, a lè fìyà ikú jẹ́ni fún kíkùnà láti pa kí ni mọ́? (Ẹ́kísódù 31:14, 15, NW)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Iṣẹ́ káfíńtà
2. Rúfọ́ọ̀sì
3. Àwọn Ánákímù, tábí àwọn ọmọ Ánákì, tí wọ́n ṣì mú fún àwọn àtọmọdọ́mọ Néfílímù
4. Hínì kan
5. Yóò rà
6. Átádì
7. Láti fi ẹwà rẹ̀ han àwọn ènìyàn
8. Nígbà tó ń gun ìbaaka kan lọ, orí rẹ̀ kọ́ sáàárín ẹ̀ka igi ńlá kan, ó sì rọ̀ sókè ní agbedeméjì òfuurufú òun ilẹ̀
9. Fífi ọmọbìnrin rẹ̀ Ákúsà, fúnni láya
10. “Alfa àti Omega, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin”
11. Aṣọ ọ̀fọ̀
12. Kímúhámù
13. Pé òun jẹ́ ará Róòmù
14. Ẹ́ń-dórì
15. Esùsú
16. Ráhábù
17. Akọ òkúta
18. Nípa àwọn “nǹkan wọnnì tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn”
19. Sátánì
20. Àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta
21. Íríjà
22. Áì
23. Jẹun
24. Éérì àti Ónánì
25. Sábáàtì