ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/8 ojú ìwé 26-27
  • Ìrànwọ́ fún Ẹsẹ̀ Ríro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrànwọ́ fún Ẹsẹ̀ Ríro
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣerẹ́gí, Àṣà Ìṣoge, àti Ẹsẹ̀
  • Àwọn Ìsọfúnni Pàtàkì Nípa Bàtà Rírà
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìrìn Rírìn Ṣe Eré Ìmárale?
    Jí!—2004
Jí!—1997
g97 10/8 ojú ìwé 26-27

Ìrànwọ́ fún Ẹsẹ̀ Ríro

“ẸSẸ̀ yí fẹ́ pa mí o!” Dájúdájú, àsọdùn ni ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, ìṣòro ẹsẹ̀ ríro le gan-an ní United States tí ó fi jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ní ń ṣiṣẹ́ ìtọ́jú ẹsẹ̀.

Lẹ́yìn ṣíṣàtúnyẹ̀wò iṣẹ́ abẹ ẹsẹ̀ tí ó lé ní 2,000 tí ó ṣe láàárín ọdún 14, Dókítà Michael Coughlin, oníṣẹ́ abẹ egungun títò, ṣe àwárí amúnitagìrì kan. Ó sọ pé: “Lọ́nà kàyéfì, mo rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn obìnrin ni mo ṣe gbogbo iṣẹ́ abẹ wọ̀nyí fún.” Kí ló dé tí àwọn obìnrin fi máa ń ní ìṣòro ẹsẹ̀ ní pàtàkì?

Ìṣerẹ́gí, Àṣà Ìṣoge, àti Ẹsẹ̀

Ìwádìí kan tí a ṣe láàárín obìnrin 356 jálẹ̀ sí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àwọn 9 lára àwọn 10 tí ń wọ bàtà tó jẹ́ pé, ní ìpíndọ́gba, ó kéré fún ẹsẹ̀ wọn ju èyí tó bá wọn mu lọ! Apá kan lára ìṣòro náà wà nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe bàtà àwọn obìnrin. Oníṣẹ́ abẹ egungun títò náà, Francesca Thompson, ṣàlàyé pé: “Àwọn aṣebàtà kì í lo ègé pẹlẹbẹ abẹ́ bàtà tí ó lè jẹ́ kí ẹ̀yìn bàtà kéré kí imú rẹ̀ sì fẹ̀ mọ́.”a

Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń wọ bàtà wò, ọ̀pọ̀ obìnrin ń rí i pé nígbà tí imú rẹ̀ bá rọ̀ wọ́n lọ́rùn, ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń ṣò; àmọ́ tí ẹ̀yìn bàtà náà bá rọ̀ wọ́n lọ́rùn, imú rẹ̀ ń fún wọn. Àwọn mìíràn máa ń mú bàtà tí ẹ̀yìn rẹ̀ rọ̀ wọ́n lọ́rùn, tí imú rẹ̀ fún, mímú ìdàkejì rẹ̀ ti lè yọrí sí kí ó máa jábọ́ lọ́wọ́ ẹ̀yìn bí wọ́n ṣe ń gbẹ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Ó jọ pé rírún iwájú ẹsẹ̀ mọ́ imú bàtà kò dára tó. Ṣùgbọ́n ṣáá, àwọn aṣebàtà tún fi ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà díẹ̀ kún bí ẹ̀yìn bàtà ṣe ga sí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kà á sí oge, ẹ̀yìn bàtà tí ó ṣe gogoro máa ń kó gbogbo ìfàro sórí ẹran abẹ́ àtàǹpàkò ẹsẹ̀, ó sì ń fipá ti ẹsẹ̀ síwájú sí imú bàtà tí ó ti lè fún jù tẹ́lẹ̀. Dókítà David Garrett, tí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹsẹ̀, sọ pé: “Kò sí ohun tí ń jẹ́ bàtà onígìgìrísẹ̀ gogoro tó bára dé.” Àwọn kan sọ pé bópẹ́bóyá bàtà onígìgìrísẹ̀ gogoro lè wá ṣèpalára fún ẹsẹ̀, kókósẹ̀, iṣu ẹsẹ̀, orúnkún, àti ẹ̀yìn ẹni tí ń wọ̀ ọ́. Wọ́n tún lè ké àwọn ẹran ẹsẹ̀ àti iṣan ẹsẹ̀ kúrú, tí ó lè mú kí àwọn tí ń sáré tètè fi ara pa lọ́nà líle ní pàtàkì.

Ẹsẹ̀ obìnrin kan kì í mú ara bá ìyà tí a fi jẹ ẹ́ mu. Ní gidi, bí a ti ń dàgbà sí i, ó jọ pé iwájú ẹsẹ̀ máa ń fẹ̀—kódà lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti di àgbàlagbà tán. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ ti gìgìrísẹ̀. Dókítà Thompson sọ pé: “Egungun kan ṣoṣo ni gìgìrísẹ̀ ní, bí ó sì ṣe kéré gan-an nígbà tí a jẹ́ ọmọ ọdún 14 ló kéré nígbà tí a bá di ẹni ọdún 84.” Èyí mú kí ó tilẹ̀ túbọ̀ ṣòro fún obìnrin kan láti rí bàtà tí ó bá a mu dáadáa láti gìgìrísẹ̀ dé ọmọ ìka.

Àwọn Ìsọfúnni Pàtàkì Nípa Bàtà Rírà

Pẹ̀lú bí ìṣerẹ́gí bàtà àti àṣà ìṣoge ti ń gbéjà ko àwọn obìnrin, báwo ni wọ́n ṣe lè ṣèdíwọ́ fún ẹsẹ̀ ríro? Ìdáhùn náà bẹ̀rẹ̀ láti ilé ìtabàtà. Àwọn ògbógi kan dámọ̀ràn àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí:

● Lọ ra bàtà ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ẹsẹ̀ rẹ bá ti wú díẹ̀.

● Wọ bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì wò—má wọ ẹsẹ̀ kan péré wò.

● Rí i dájú pé ẹ̀yìn bàtà náà ṣe rẹ́gí lẹ́sẹ̀ àti pé gígùn, fífẹ̀, àti gíga imú bàtà náà tó.

● Mọ̀ pé ilé ìtajà náà lè ní kápẹ́ẹ̀tì tí wọ́n kó tìmùtìmù sábẹ́ rẹ̀ gan-an, tí èyí sì ń mú kí bàtà tí kò báni mu tilẹ̀ rọni lọ́rùn fún ìgbà díẹ̀.

● Má ṣe ra bàtà tí wọ́n fi awọ líle tí ń dán bọ̀rọ́bọ̀rọ́ tàbí èyí tí wọ́n fi kẹ́míkà ṣe awọ rẹ̀. Láìdàbí awọ rírọ̀ tàbí awọ onírun múlọ́múlọ́, irú àwọn awọ yẹn kì í ràn bí o bá ń rìn.

● Bí o bá ra bàtà onígìgìrísẹ̀ gogoro, gbìyànjú kíkó awọ sí inú wọn kí ó lè mú ìtẹ́nú rẹ̀ pọ̀ sí i. Ronú nípa wíwọ bàtà onígìgìrísẹ̀ gogoro fún àkókò díẹ̀, kí ó sì máa pa dà wọ èyí tí ẹ̀yìn rẹ̀ túbọ̀ lọ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fún gbogbo ọjọ́ kan.

Ní àfikún sí ohun tó wà lókè yí, máa rántí ní gbogbo ìgbà pé bàtà gbọ́dọ̀ rọ̀ ọ́ lọ́rùn nígbà tí o rà á. Lòdì sí ohun tí ọ̀pọ̀ gbà gbọ́, kò sí ohun tí ń jẹ́ pé kò ní tani lẹ́sẹ̀ mọ́ tó bá ti pẹ́ tí a ti ń wọ̀ ọ́. Dókítà Coughlin kìlọ̀ pé: “Má ṣe jẹ́ kí olùtajà rí ọ mú láé pé bàtà tí ń ta ọ́ lẹ́sẹ̀ náà yóò rọ̀ ọ́ lọ́rùn tó bá ti pẹ́ tí o ti ń wọ̀ ọ́. Ohun kan ṣoṣo tí yóò ní ìpalára ni ẹsẹ̀ rẹ.”

Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ onímú ṣóńṣó tí ẹ̀yìn rẹ̀ rọni lọ́rùn tàbí èyí tí imú rẹ̀ rọni lọ́rùn tí ẹ̀yìn rẹ̀ ṣò ni yíyàn kan ṣoṣo tí o ní ńkọ́? Dókítà Annu Goel, tí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹsẹ̀, sọ pé, o gbọ́dọ̀ pinnu èyí tí ó rọrùn jù lọ láti ṣàtúnṣe rẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀nà méjì la lè gbà ṣe èyí. Lákọ̀ọ́kọ́, o lè ra bàtà tí imú rẹ̀ fẹ̀ tó, kí o sì kó ìtẹ́nú sí i láti mú kí ẹ̀yìn rẹ̀ túbọ̀ ṣe rẹ́gí. . . . Ìwéwèé àfìṣọ́raṣe kejì jẹ́ láti ra bàtà tí ẹ̀yìn rẹ̀ rọ̀ ọ́ lọ́rùn, kí o sì fẹ imú rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní gbogbogbòò, èyí ń ṣiṣẹ́ fún kìkì àwọn bàtà tí wọ́n fi awọ ṣe.”

Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ti máa ń rin ìwọ̀n ìfojúdíwọ̀n kìlómítà 15 lóòjọ́, yóò dára kí wọ́n yẹ bàtà wọn wò. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn American Health ti sọ, “nípa lílo ẹsẹ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ lọ́wọ̀—ní pàtàkì nípa wíwọ bàtà tí ó ṣe rẹ́gí lẹ́sẹ̀—o lè ṣèdíwọ́ fún kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìṣòro ẹsẹ̀ ṣe ọ́ páàpáà.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Ègé pẹlẹbẹ abẹ́ bàtà” ni ohun tí ó ní ìrísí ẹsẹ̀ tí wọ́n ṣe bàtà lé lórí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìṣòro Mẹ́rin Wíwọ́pọ̀ Jù Lọ Tí Ẹsẹ̀ Ń Ní

Ẹran lílé. Èyí ni ibi tí ó wú nínú ẹran abẹ́ àtàǹpàkò. Tí kì í bá ṣe pé àbímọ́ni ni, ó lè jẹ́ bàtà tí ó fún tàbí onígìgìrísẹ̀ gogoro ló fà á. Lílo ooru tàbí fífi omi dídì sí i lè gbani lọ́wọ́ ìrora fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ a nílò iṣẹ́ abẹ láti mú ẹran lílé kúrò pátápátá.

Ìka ẹsẹ̀ títẹ̀. Bàtà tí ń kó ìfàro púpọ̀ jù bá iwájú ẹsẹ̀ lè fa kí àwọn ìka ẹsẹ̀ tẹ̀ sísàlẹ̀. A lè nílò iṣẹ́ abẹ láti ṣàtúnṣe àbùkù náà.

Kókó. Àwọn ibi yíyọkókó onírìísí òkòtó ní ìka ẹsẹ̀, tí ìfigbora àti ìfàro ń ṣokùnfà, máa ń jẹ́ nítorí wíwọ bàtà tí ó fún jù nígbà míràn. Títọ́jú wọn ní ilé lè dín in kù fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ iṣẹ́ abẹ sábà máa ń pọn dandan láti ṣàtúnṣe àwọn ìka tó lábùkù tí ń fa ìfigbora.

Èépá. Àwọn ìpele awọ nínípọn tí ó ti kú ń dáàbò bo ẹsẹ̀ lọ́wọ́ ìfigbora léraléra. Rírẹ wọ́n sínú omi lílọ́wọ́ọ́rọ́ àti iyọ̀ Epsom lè mú wọn rọ̀. Ṣùgbọ́n má ṣe gbìyànjú láti rẹ́ wọn, nítorí èyí lè fa àkóràn àrùn.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́