Wá Gbọ́ Àwíyé Náà “Ìgbàgbọ́ àti Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ”
O ha lè mọ ọjọ́ ọ̀la rẹ ní gidi bí? Ohun kan ha wà tí o lè ṣe láti wádìí ohun tí yóò jẹ́?
Àwíyé náà fún gbogbo ènìyàn, tí ó jẹ́ apá fífanimọ́ra nínú Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yóò fi ìdí tí ìrètí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ fi wà fún ọjọ́ ọ̀la amọ́kànyọ̀ hàn. O lè gbọ́ ọ̀rọ̀ náà ní ọ̀gangan kan tí ó sún mọ́ ilé rẹ, nítorí pé, bẹ̀rẹ̀ láti oṣù yí, a óò sọ ọ́ ní onírúurú àpéjọpọ̀ jákèjádò Náìjíríà.
Kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí wọ́n ṣe ìwé ìròyìn yí jáde láti mọ ọ̀gangan àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọ jù lọ. A to àwọn àdírẹ́sì gbogbo ọ̀gangan àpéjọpọ̀ náà ní Nàìjíríà sínú Jí!, ìtẹ̀jáde June 8.