Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Inú Ìkòkò Ọ̀rá Kan
Ìpayà ogun jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ìrírí mi níbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, ní pàtàkì, àwọn ìrírí ti sísá kiri láti gba ẹ̀mí wa là ní apá ìparí Ogun Àgbáyé Kejì, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin péré. Ìdílé wa ẹlẹ́ni-méje ti ń gbé Ìlà Oòrùn Prussia, tí ó jẹ́ apá kan Germany, nígbà náà.
MO RANJÚ sínú òkùnkùn bíbanilẹ́rù náà, mo ń gbọ́ ìró ẹgbẹ́ ọmọ ogun ajubọ́ǹbù ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan tí ń bọ̀. Lójijì, ìbùyẹ̀rì tó lè fọ́ni lójú àti ìbúgbàù tó lè dini létí finá ran àwọn táǹkì epo tó wà ní mítà mélòó kan níwájú. Ọkọ̀ ojú irin tí a wọ̀ mì jìgìjìgì lójú irin rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ké rara. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, àwọn ajubọ́ǹbù náà lọ, a sì ń bá ìrìn àjò wa nìṣó.
Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, mo jí lójú oorun ìdákúrekú kan, mo sì rí obìnrin kan tí ń ké rara, tí ń gbìyànjú láti jáde kúrò nínú iyàrá ìkẹ́ransí inú ọkọ̀ ojú irin tí a ń wọ̀ lọ. Bàbá dí i lọ́wọ́, ó sì fà á pa dà sínú ọkọ̀. Obìnrin náà ti sùn nítòsí ilẹ̀kùn, tòuntọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí ó ta jí, ó rí i pé òtútù ti mú ọmọ náà pa. Àwọn ọkùnrin gbé òkú náà jù sínú òjò dídì níta, bí ìbànújẹ́ sì ti bo ìyá náà mọ́lẹ̀, ó ń gbìyànjú láti ṣílẹ̀kùn, kí ó bẹ́ sítà, kí ó sì kú níbẹ̀ pẹ̀lú ọmọ rẹ̀.
Láti gbógun ti òtútù lílekoko náà, àdògán fífẹ̀ kan wà ní àárín iyàrá ọkọ̀ kékeré tí a wà náà. A ń lo igi díẹ̀ tó wà ní ìkángun kan nínú iyàrá ọkọ̀ náà láti máa fi se ọ̀dùnkún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọ̀dùnkún ni a fi ń ṣe ibùsùn wa pẹ̀lú, nítorí sísùn lórí wọn ń mú ara wa móoru díẹ̀ ju orí ilẹ̀ẹ́lẹ̀ iyàrá ọkọ̀ náà tó ti dì lọ.
Èé ṣe tí a fi ń sá kiri láti gba ẹ̀mí wa là? Báwo ni ìdílé wa ṣe là á já bí ìsáǹsá fún ọ̀pọ̀ oṣù? Ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín.
Jíjẹ́ Ìran Júù
A bí mi ní December 22, 1940—àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ márùn-ún—ní Lyck, Ìlà Oòrùn Prussia (nísinsìnyí Elk, Poland). Inúnibíni ìsìn ti fipá mú kí àwọn baba ńlá mi tí wọ́n jẹ́ Júù fi Germany sílẹ̀ ní apá ìparí àwọn ọdún 1700. Wọ́n kó lọ sí Rọ́ṣíà nínú ọ̀kan lára àwọn ìṣíkiri elérò púpọ̀ ńláǹlà tí ó wà nínú ìtàn. Lẹ́yìn náà ní 1917, kí a lè bọ́ lọ́wọ́ inúnibíni lòdì sì àwọn Júù ní Rọ́ṣíà nígbà náà, bàbá mi àgbà tó jẹ́ Júù ṣí lọ sí Ìlà Oòrùn Prussia láti abúlé rẹ̀ nítòsí Odò Volga.
Baba àgbà gba ìwé ẹ̀rí ọmọ ìbílẹ̀ Germany, ó sì jọ pé Ìlà Oòrùn Prussia jẹ́ ibi ààbò kan. Àwọn tí ó ní orúkọ àbísọ Júù pààrọ̀ orúkọ sí ti Íńdíà-òun-Europe. Nípa bẹ́ẹ̀, bàbá mi, Friedrich Salomon, di ẹni tí a mọ̀ sí Fritz. Nídà kejì, Màmá jẹ́ ará Prussia ní tirẹ̀. Òun àti Bàbá, tí ó jẹ́ akọrin, ṣègbéyàwó ní 1929.
Ó jọ pé ìgbésí ayé jẹ́ aláyọ̀, ọjọ́ ọ̀la sì nírètí fún àwọn òbí mi. Màmá àgbà, Fredericke, àti Màmá màmá àgbà, Wilhelmine, jùmọ̀ ní oko ńlá kan, tí ó já sí ilé kejì fún àwọn òbí mi àti àwa ọmọ wọn. Orin kó apá pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé ìdílé wa. Màmá máa ń lùlù nínú ẹgbẹ́ oníjó Bàbá.
Ìfipágbalẹ̀ Nazi
Ní 1939, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń tọ́ka ibi bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn nínú ìṣèlú. Ohun tí Adolf Hitler pè ní ojútùú pátápátá sí ìṣòro àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í da àwọn òbí mi láàmú. Àwa ọmọ kò mọ̀ nípa jíjẹ́ tí a jẹ́ ìran Júù, a kò sì mọ̀ nípa rẹ̀ títí tí Màmá fi kú ní 1978—ọdún mẹ́sàn-án lẹ́yìn tí Bàbá ti kú.
Kí ẹnikẹ́ni má baà fura pé Bàbá jẹ́ Júù, ó dara pọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Germany. Níbẹ̀rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ olórin. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì kan tí ó mọ bí o ti jẹ́ látilẹ̀ wá ní kedere sọ pé Júù ni, nítorí náà, wọ́n fọ̀rọ̀ wá gbogbo ìdílé wa lẹ́nu wò, wọ́n sì yà wá ní fọ́tò. Àwọn ògbógi Nazi náà gbìyànjú láti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ ní ti bóyá a ní àwọn àmì ìdánimọ̀ Júù tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìrísí wa jọ ti ará Íńdíà-òun-Europe tó fún wọn, nítorí náà, lọ́nà àrìnnàkore, a kò fàṣẹ ọba mú wa, a kò sì fi wá sẹ́wọ̀n.
Nígbà tí Germany gbógun ti Poland ní September 1, 1939, ìbẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ ní ẹkùn ilẹ̀ wa tó lálàáfíà tẹ́lẹ̀. Màmá fẹ́ kó lọ síbi tó túbọ̀ láàbò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ Nazi fipá ṣèdíwọ́ fún ìdílé náà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, bí àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà ṣe ń wọlé bọ̀ síhà Ìlà Oòrùn Prussia nígbà ẹ̀ẹ̀rùn 1944, àwọn ará Germany pinnu láti kó àwọn ènìyàn kúrò ní Lyck àti àgbègbè rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ní July, wọ́n fún wa ní wákàtí mẹ́fà péré láti kó kúrò nílé wa.
Ìtúyáyájáde Oníjìnnìjìnnì
Jìnnìjìnnì bo Màmá. Kí ni ká mú? Ibo ni ká forí lé? Báwo la ó ṣe rìnrìn àjò náà? A ó ha pa dà wá láé bí? Ìwọ̀nba ṣín-ún ni ohun tí ìdílé kọ̀ọ̀kan lè kó. Màmá fọgbọ́n yan àwọn ohun kòṣeémánìí—títí kan ìkòkò amọ̀ ńlá kan tí ọ̀rá ẹran àti ègé ẹlẹ́dẹ̀ kéékèèké wà nínú rẹ̀—tí ó pọ̀ tó fún wa láti gbé nírọ̀rùn. Àwọn ìdílé mìíràn yàn láti kó àwọn ohun ìní wọn ṣíṣeyebíye ti ara.
Ní October 22, 1944, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Rọ́ṣíà wọ Ìlà Oòrùn Prussia. Òǹkọ̀wé kan ṣàlàyé pé: “Kò yani lẹ́nu pé àwọn sójà Rọ́ṣíà tí wọ́n ti rí bí a ṣe pa àwọn ìdílé tiwọn fúnra wọn nípakúpa, tí a sì dáná sun àwọn ilé àti irè oko wọn gbọ́dọ̀ fẹ́ láti gbẹ̀san.” Ìparundahoro náà múni gbọ̀n rìrì jákèjádò Ìlà Oòrùn Prussia, àwọn ènìyàn sì sá lọ nínú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì.
Nígbà yẹn, a ti di olùwá-ibi-ìsádi, tí ń gbé ìhà ìwọ̀ oòrùn jíjìnnà ní Ìlà Oòrùn Prussia. Ó jọ pé ọ̀nà àsálà kan ṣoṣo tí ó wà ni Òkun Baltic, nítorí náà, àwọn ènìyàn sá lọ sí ìlú èbúté ti Danzig (nísinsìnyí Gdansk, Poland). Níbẹ̀, wọ́n fipá gba àwọn ọkọ̀ òkun kan fún kíkó àwọn ènìyàn kúrò lágbègbè eléwu ní pàjáwìrì. Ìdílé wa tàsé ọkọ̀ ojú irin tí ó yẹ kí ó kó wa lọ wọ ọkọ̀ ojú omi ìkérò ti Germany náà, Wilhelm Gustloff, tí ó ṣíkọ̀ láti Gdynia, nítòsí Danzig, ní January 30, 1945. A gbọ́ lẹ́yìn náà pé àwọn ohun abúgbàù abẹ́ omi ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà fọ́ ọkọ̀ òkun náà, nǹkan bí 8,000 èrò inú rẹ̀ sì ṣègbé sínú omi oníyìnyín náà.
Bí ọ̀nà àsálà ojú òkun náà ti dí, a forí lé ìhà ìwọ̀ oòrùn. Nígbà tí Bàbá gba ìsinmi ráńpẹ́, ó dara pọ̀ mọ́ wa fún apá kan ìrìn àjò inú ọkọ̀ ojú irin náà, bí a ṣe júwe rẹ̀ nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀. Láìpẹ́, ó ní láti pa dà lọ sẹ́nu iṣẹ́ ológun, a sì ń bá ìrìn àjò jíjìn tó léwu náà lọ fúnra wa. Màmá ń tọ́jú ìkòkò ọ̀rá náà, ó sì ń bù ú díẹ̀díẹ̀ nígbà kọ̀ọ̀kan. Ó ń jẹ́ àfikún sí oúnjẹ díẹ̀díẹ̀ tí a ń rí kó jọ bí a ti ń lọ, tí ń mú kí a máa wà nìṣó nígbà òtútù gígùn náà. Ìkòkò ọ̀rá yẹn já sí ohun tó ṣeyebíye ju wúrà tàbí fàdákà èyíkéyìí lọ!
Níkẹyìn, a dé ìlú Stargard, níbi tí àwọn ọmọ ogun Germany àti Ẹgbẹ́ Alágbèé-lébùú Pupa ti ṣàgbékalẹ̀ ìpèsè oúnjẹ níwọ̀nba fún àwọn aláìní nítòsí ibùdókọ̀ ojú irin náà. Lójú ọmọ kékeré kan ti ebi ń pa, oúnjẹ yẹn jọ oúnjẹ amúniláyọ̀ kan. Láìpẹ́, a dé Hamburg, Germany, ebi ń pa wá, ó sì ti rẹ̀ wá, ṣùgbọ́n a láyọ̀ pé a wà láàyè. Wọ́n kó wa sí oko kan lẹ́bàá odò Elbe, pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n ará Rọ́ṣíà àti Poland tí wọ́n kó lójú ogun. Nígbà tí ogun ilẹ̀ Europe fi parí ní May 8, 1945, ipò wa jẹ́ aláìdáni-lójú gan-an.
Ìgbésí Ayé Gẹ́gẹ́ bí Olùwá-Ibi-Ìsádi
Àwọn ará America ti mú Bàbá lẹ́rú, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ dáradára, ní pàtàkì nígbà tí wọ́n mọ̀ pé akọrin ni. Wọ́n lo òye iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ fún ayẹyẹ Ọjọ́ Òmìnira wọn. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó jàjà sá là, ó sì rìnrìn àjò wá sí Hamburg, níbi tí a ti tún pàdé pọ̀ tayọ̀tayọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. A gbé inú ahéréko kékeré kan, láìpẹ́ sì ni àwọn màmá wa àgbà méjèèjì dé lálàáfíà, tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ wa.
Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́, àwọn olùgbé àdúgbò, títí kan Ìjọ Lutheran tiwa fúnra wa, bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra àwọn olùwá-ibi-ìsádi púpọ̀ náà. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, òjíṣẹ́ náà bẹ ìdílé wa wò. Ó jọ pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ń fínràn nípa pípẹ̀gàn ipò wa gẹ́gẹ́ bí olùwá-ibi-ìsádi. Inú bí Bàbá, ẹni tí ìrísí rẹ̀ jẹ́ ti alágbára, ó sì gbéjà ko oníwàásù náà. Màmá wa àti àwọn màmá wa àgbà dá Bàbá lẹ́kun. Ṣùgbọ́n ó wá gbé àlùfáà náà kúrò nílẹ̀ pátápátá, ó rù ú lọ sí ẹnu ọ̀nà, ó sì tì í síta. Láti ìgbà náà lọ, ó ka ìjíròrò ìsìn èyíkéyìí léèwọ̀ lábẹ́ òrùlé rẹ̀.
Láìpẹ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yí, Bàbá gba iṣẹ́ nílé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin ilẹ̀ Germany, a sì kó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú Hamburg, níbi tí a ti ń gbé inú iyàrá ọkọ̀ kan tí wọn kò lò mọ́. Lẹ́yìn náà, Bàbá kọ́ ilé kékeré kan fún wa. Àmọ́ ìkórìíra àwọn olùwá-ibi-ìsádi ń bá a lọ, bí mo sì ti jẹ́ ọmọdé kan, mo di ẹni tí a ń fìyà jẹ ní ti ara ìyára àti ti ìmọ̀lára lọ́wọ́ àwọn ọmọdé àdúgbò.
Ìsìn Tí Ìdílé Wa Yàn Láàyò
Bí ọmọdé kan, mo ń sùn nínú iyàrá kan náà pẹ̀lú àwọn màmá mi àgbà méjèèjì. Láìka àṣẹ Bàbá sí, bí Bàbá kò bá ti sí nílé, àwọn méjèèjì sábà máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, wọ́n ń kọ àwọn orin ìsìn, wọ́n sì ń ka Bíbélì wọn. Èyí ta ìdàníyàn tẹ̀mí mi jí. Nítorí náà, nígbà ti mo di ọmọ ọdún mẹ́wàá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rin nǹkan bíi kìlómítà 11 lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, mo sì ń rin nǹkan bíi kìlómítà 11 bọ̀, ní ọjọọjọ́ Sunday. Bí ó ti wù kí ó rí, mo ní láti sọ pé mo ní ìjákulẹ̀ nígbà tí a kò lè dáhùn púpọ̀ lára àwọn ìbéèrè tí mo ń béèrè tó pé kí ó tẹ́ mi lọ́rùn.
Lẹ́yìn náà, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn 1951, ọkùnrin kan tó múra nigín-nigín kanlẹ̀kùn ilé wa, ó sì fi ẹ̀dà kan ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọ Màmá. Ó sọ pé: “Ilé Ìṣọ́ ń fúnni ní òye nípa Ìjọba Ọlọ́run.” Ọkàn àyà mi yọ̀, nítorí ohun tí mo fọkàn fẹ́ nìyẹn. Màmá fọgbọ́n kọ̀ ọ́, ní kedere, nítorí àtakò tí Bàbá ń ṣe sí ìsìn. Bí ó ti wù kí ó rí, mo rọ̀ ọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi dẹwọ́, tí ó sì gba ẹ̀dà kan fún mi. Nígbà míràn lẹ́yìn náà, Ernest Hibbing pa dà wá, ó sì fi ìwé náà, “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ,” sílẹ̀ fún wa.
Ní nǹkan bí àkókò yí, ìjàǹbá ṣe Bàbá lẹ́nu iṣẹ́, ó sì ṣẹ́ lẹ́sẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé kò lè jáde nílé, tí ó sì ń bí i nínú gidigidi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n símẹ́ǹtì ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣì lè máa sún láńká kiri. Ó ń ṣe wá ní kàyéfì pé ó máa ń pòórá lọ́sàn-án, a sì ń rí i nígbà àtijẹun nìkan. Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún odindi ọ̀sẹ̀ kan. Mo kíyè sí i pé nígbàkigbà tí Bàbá bá pòórá, ìwé mi ń pòórá pẹ̀lú. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà àtijẹun kan, Bàbá sọ fún mi pé: “Bí ọkùnrin yẹn bá tún wá, mo fẹ́ rí i!”
Nígbà tí Arákùnrin Hibbing pa dà wá, ó yà wá lẹ́nu pé ńṣe ni Bàbá sọ ìwé náà sórí tábìlì gbì, ó sì wí pé: “Ìwé yìí ni òtítọ́!” Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí àkókò sì ti ń lọ, àwọn mẹ́ńbà míràn nínú ìdílé dara pọ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Arákùnrin Hibbing di atọ́nisọ́nà tí mo gbẹ́kẹ̀ lé àti ọ̀rẹ́ mi tòótọ́. Láìpẹ́, wọ́n lé mi kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi nítorí pé mo ń gbìyànjú láti ṣàjọpín àwọn ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́. Nítorí náà, mo kọ̀wé fi Ìjọ Lutheran sílẹ̀.
Ní July 1952, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n nípìn-ín nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láti ilé dé ilé. Lọ́jọọjọ́ Sunday, Arákùnrin Hibbing yóò rọ̀ mí láti tẹ́tí sí bí òun ṣé ń sọ ìsọfúnni náà fún àwọn onílé dáradára. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ó tọ́ka sí àwọn ilé kan tí a kọ́ tira, ó sì wí pé: “Tìrẹ ni gbogbo wọn láti dá ṣiṣẹ́ níbẹ̀.” Láìpẹ́, mo ṣẹ́pá ojora tó mú mi, mo sì kẹ́sẹ járí gidigidi ní bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ àti fífún wọn ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Láìpẹ́, mo tóótun fún ìrìbọmi ní àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà. Èmi àti Bàbá jọ ṣèrìbọmi ní March 29, 1953, lẹ́yìn náà, lọ́dún kan náà, Màmá ṣèrìbọmi. Níkẹyìn, gbogbo mẹ́ńbà ìdílé wa ṣèrìbọmi, títí kan ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, Erika; àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, Heinz, Herbert, àti Werner; àti àwọn màmá wa àgbà ọ̀wọ́n méjèèjì, tí wọ́n ti lé ní ẹni 80 ọdún dáradára nígbà náà. Lẹ́yìn náà, ní January 1959, mo di aṣáájú ọ̀nà, bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Ilẹ̀ Tuntun Kan
Bàbá ti sábà máa ń rọ̀ mí láti kúrò ní Germany, bí mo bá sì ronú sẹ́yìn, mo gbà pé èyí jẹ́ nítorí ìbẹ̀rù ìgbógunti-àwọn-Júù tí ó ń ní. Mo kọ̀wé béèrè àṣẹ láti kó lọ sí Australia, ní ríretí pé èyí yóò jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tí yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Papua New Guinea tàbí ní erékùṣù kan ní Pàsífíìkì. Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, Werner, jọ gúnlẹ̀ sí Melbourne, Australia, ní July 21, 1959.
Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, mo pàdé Melva Peters, tí ó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ní Ìjọ Footscray, a sì ṣègbéyàwó ní 1960. A fi ọmọbìnrin méjì, tí àwọn náà wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, tí wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún un, jíǹkí wa. A ti sapá gidigidi láti mú ìgbésí ayé wa rọrùn láìfi ohun kankan há a gádígádí tó bẹ́ẹ̀ tí a fi lè lépa àwọn góńgó tẹ̀mí ni kíkún sí i gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Melva jẹ́ aṣáájú ọ̀nà kan, títí àìlera fi ṣèdíwọ́ fún un láti máa bá a nìṣó. Ní báyìí, mo jẹ́ alàgbà kan, mo sì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà kan nínú Ìjọ Belconnen, ní ìlú ńlá Canberra.
Láti inú ìrírí tí mo ní nígbà ọmọdé, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ kí àwọn ìpèsè Jèhófà máa fún mi ní ayọ̀ òun ìtẹ́lọ́rùn. Gẹ́gẹ́ bí ìkòkò ọ̀rá màmá mi ti fi hàn, mo ti wá mọrírì rẹ̀ pé ìwàláàyè kò sinmi lórí wúrà tàbí fàdákà, bí kò ṣe lórí àwọn ohun ìní tí kò ṣeé máà ní, àti ní pàtàkì jù lọ, lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, àti lílo àwọn ohun tí ó ń fi kọ́ni.—Mátíù 4:4.
Àwọn ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ìyá Jésù, Màríà, sọ, jẹ́ òtítọ́ ní gidi pé: “[Jèhófà] ti fi àwọn ohun rere tẹ́ àwọn ẹni tí ebi ń pa lọ́rùn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ó sì ti rán àwọn wọnnì tí wọ́n ní ọlà lọ ní òfo.” (Lúùkù 1:53) Tayọ̀tayọ̀, mo lè ka ẹni 47 nínú ìdílé wa, tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́ Bíbélì, títí kan àwọn ọmọ ọmọ méje. (Jòhánù Kẹta 4) Èmi àti Melva, pẹ̀lú gbogbo àwọn wọ̀nyí, àti ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọ ọmọ wa nípa tẹ̀mí, ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu lábẹ́ ààbò, lábẹ́ àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Jèhófà, àti ìpàdépọ̀ kíkàmàmà pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wa mìíràn, nígbà tí a bá jí wọn dìde.—Bí Kurt Hahn ṣe sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn ẹgbẹ́ ogun Rọ́ṣíà ń wọ Ìlà Oòrùn Prussia, ní 1944
[Credit Line]
Sovfoto
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ẹ̀gbọ́n mi, Heinz àti Erika, Màmá, àwọn ẹ̀gbọ́n mi, Herbert àti Werner, àti èmi níwájú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Èmi àti ìyàwó mi, Melva
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìkòkò kan bí èyí, tí ọ̀rá kún inú rẹ̀, gbé ìwàláàyè wa ró