ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/22 ojú ìwé 32
  • Ó Mọyì Ilé Ìṣọ́ Ní Ti Gidi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Mọyì Ilé Ìṣọ́ Ní Ti Gidi
  • Jí!—1997
Jí!—1997
g97 10/22 ojú ìwé 32

Ó Mọyì Ilé Ìṣọ́ Ní Ti Gidi

Akẹ́kọ̀ọ́ kan, tó wà ní ìpele ẹ̀kọ́ kẹfà, ní Toledo, Ohio, U.S.A., sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ìjọ Roman Kátólíìkì ni mí, mo fẹ́ láti san àsansílẹ̀-owó fún ìwé ìròyìn yín dídára náà. Trevor ló mú mi nífẹ̀ẹ́ sí Ilé Ìṣọ́. Ẹ̀gbẹ́ mi ló ń jókòó ní kíláàsì. Ó ti tó ọdún kan báyìí tí a ti ń bá ọ̀rẹ́ wa bọ̀, ó sì ti kọ́ mi ní ohun púpọ̀ nípa Jésù, Jèhófà, àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Ẹgbẹ́ lèmi àti Trevor, a ga dọ́gba, ó sì ní ìfọkànsìn nínú ìsìn rẹ̀. Ó san àsansílẹ̀-owó fún Ilé Ìṣọ́, ó sì ń yá mi ní ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn rẹ̀. Mo fẹ́ràn àwọn àpilẹ̀kọ tí ó bọ́gbọ́n mu tí ẹ máa ń kọ. Mo lérò pé ẹ óò gbójú fo kókó náà pé n kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá, ẹ óò sì jẹ́ kí ń san àsansílẹ̀-owó fún ìwé ìròyìn yín.”

Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àti ìsìn púpọ̀ jákèjádò ayé ń gbádùn kíka Ilé Ìṣọ́ àti ìwé ìròyìn tí ó ṣìkejì rẹ̀, Jí! Lọ́dún tó kọjá nìkan, ó lé ní 900 mílíọ̀nù ẹ̀dà àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí tí a tẹ̀ jáde ní èdè tí ó lé ní 120!

Ìwọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní láti inú kíka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kan gbà tàbí kí a wá bá ọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́