ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/8 ojú ìwé 12-17
  • Ọkùnrin Tó Ṣí Ayé Payá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọkùnrin Tó Ṣí Ayé Payá
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀dọ́ Ìránṣẹ́ Ọba Tó Di Aláìṣojo Arìnrìn-Àjò Ojú Òkun
  • Ọba Sípéènì Yóò Tẹ́tí sí I Bí?
  • “Itú Ìfòkunsọ̀nà Títóbijùlọ Nínú Ìtàn”
  • Ìrírí Agbonijìgì ní Pàsífíìkì
  • Àjálù—Èrò Àfọkànfẹ́ Kan Fẹnu Kọ́lẹ̀
  • Àgbákò Nígbà Ìrìn Pa Dà Sílé
  • Orúkọ Magellan Kò Pa Run
  • A Fi Gbogbo Ọkàn Wa Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Atànmọ́lẹ̀ fún Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Jí!—1997
g97 11/8 ojú ìwé 12-17

Ọkùnrin Tó Ṣí Ayé Payá

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA

NÍGBÀ tí àwọn ènìyàn kọ́kọ́ lọ sínú òṣùpá, wọ́n mọ ibi tí wọ́n ń lọ àti bí wọn yóò ṣe débẹ̀, ní pàtó. Wọ́n sì lè bá àwọn tó wà nílé sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ferdinand Magellana kó ọkọ̀ òkun àfigigbẹ́ kéékèèké márùn-ún—tí ọ̀pọ̀ lára wọn gùn ní nǹkan bíi mítà 21, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọkọ̀ eléjò òde òní—tí ó gbéra láti Sípéènì ní 1519, wọ́n forí lé ibi àìmọ̀. Wọ́n sì wà láwọn nìkan pátápátá.

Lára àwọn bírà ìfòkunṣọ̀nà tó jẹ́ ti aláìṣojo àti onígboyà jù lọ nínú ìtàn, àwọn ìrìn àjò Magellan lójú omi jẹ́ mánigbàgbé ní Sànmánì Ìṣàwárí Gígadabú náà—sànmánì ìgboyà òun ìbẹ̀rù, ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ òun ìbìnújẹ́, Ọlọ́run òun Mámónì. Ẹ jẹ́ kí a wá pa dà sẹ́yìn, sí nǹkan bí 1480, nígbà tí a bí Ferdinand Magellan ní ìhà àríwá ilẹ̀ Potogí, kí a sì mọ àràmàǹdà ọkùnrin tó ṣí ayé payá náà, àti àwọn ìrìn àjò rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́.

Ọ̀dọ́ Ìránṣẹ́ Ọba Tó Di Aláìṣojo Arìnrìn-Àjò Ojú Òkun

Ìdílé Magellan jẹ́ gbajúmọ̀, nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àṣà, nígbà tí Ferdinand ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, wọ́n pè é sí ààfin gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ọba. Níhìn-ín, yàtọ̀ sí pé ó kọ́ ẹ̀kọ́ ìwé, ó tún mọ̀ ní tààrà nípa itú tí àwọn ọkùnrin bíi Christopher Columbus pa, ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ darí dé láti àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà lẹ́yìn tí ó ti ṣàwárí ọ̀nà ojú òkun ní ìhà ìwọ̀ oòrùn lọ sí Erékùṣù Spice (Indonesia) lílókìkí náà. Láìpẹ́, Ferdinand ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lálàá ọjọ́ tí òun náà lè gbọ́ ìró ìgbòkun tí ń lù gbàgbà lókè orí òun, kí òun sì fojú rí ìṣàntérétéré omi òkun tí ẹnì kan kò débẹ̀ ṣáájú òun.

Ó bani nínú jẹ́ pé wọ́n pa Ọba John tó jẹ́ alátìlẹ́yìn rẹ̀ ní 1495, Ọba Manuel, tí ọrọ̀ jẹ lọ́kàn ju ìṣàwárí lọ, sì gorí ìtẹ́. Nítorí ìdí kan, Manuel kò fẹ́ràn Ferdinand, ọmọ ọdún 15 náà, ó sì pa àwọn ìtọrọ àyè rẹ̀ láti rin ìrìn àjò ojú òkun tì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ṣùgbọ́n nígbà tí Vasco da Gama pa dà dé láti Íńdíà, tó sì kó ẹrù àwọn nǹkan amóúnjẹ-tasánsán bọ̀, Manuel róye ọrọ̀ rẹpẹtẹ. Níkẹyìn, ó fún Magellan láyè láti rin ìrìn àjò ojú òkun ní 1505. Magellan forí lé Ìlà Oòrùn Áfíríkà àti Íńdíà nínú ọ̀wọ́ ọkọ̀ ogun ojú omi ilẹ̀ Potogí kan, láti lọ gba àkóso òwò àwọn nǹkan amóúnjẹ-tasánsán náà lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò ará Arébíà. Lẹ́yìn náà, ó rin ìrìn àjò ológun mìíràn lọ síwájú dé Malacca.

Nígbà ìjà ráńpẹ́ kan ní Morocco ní 1513, Magellan forúnkún pa yánnayànna. Nítorí náà, ó tiro jálẹ̀ ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ ni. Ó bẹ̀bẹ̀ pé kí Manuel ṣàfikún owó ìfẹ̀yìntì òun. Ṣùgbọ́n kèéta Manuel kò dín kù rárá lójú àwọn ìwà akin, ìrúbọ, àti ìgbójúgbóyà tí Magellan fi hàn ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ó yọ̀ǹda rẹ̀ láìní ànító rárá láti máa gbé ìgbésí ayé gbajúmọ̀ ní ipò tálákà.

Ní àkókò àìláyọ̀ lílékenkà yí nínú ìgbésí ayé Magellan, ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ kan, olókìkí arìnrìn-àjò ojú òkun náà, João de Lisboa, bẹ̀ ẹ́ wò. Àwọn méjèèjì jíròrò bí wọ́n ṣe lè gba el paso—ọ̀nà tóóró kan tí àhesọ fi hàn pé ó la Gúúsù Amẹ́ríkà kọjá—níhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn, kí wọ́n fi dé Erékùṣù Spice, kí wọ́n sì wá la òkun tí Balboa ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí nígbà tí ó ń gba ilẹ̀ tóóró Panamania kọjá. Wọ́n gbà gbọ́ pé ìhà kejì òkun yìí ni Erékùṣù Spice wà.

Magellan wá ń yán hànhàn láti ṣe ohun tí Columbus kùnà láti ṣe—láti rí ọ̀nà ìhà ìwọ̀ oòrùn dé Ìlà Oòrùn, tí ó gbà gbọ́ pé ó yá ju ọ̀nà ìlà oòrùn lọ. Ṣùgbọ́n ó nílò ìrànwọ́ owó. Nítorí náà, bí ó ṣì ṣe ń joró ìrunú bíburújáì ti Manuel, ó ṣe ohun tí Columbus náà ṣe ní ọdún díẹ̀ ṣáájú—ó wá ìtìlẹ́yìn ọba Sípéènì.

Ọba Sípéènì Yóò Tẹ́tí sí I Bí?

Pẹ̀lú àwòrán ilẹ̀ àwọn afòkunṣọ̀nà tí Magellan gbé kalẹ̀, ó ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ̀dọ́ aláṣẹ Sípéènì, Charles Kíní, tí ó lọ́kàn ìfẹ́ sí ọ̀nà ìwọ̀ oòrùn tí Magellan ń wéwèé lọ sí àwọn Erékùṣù Spice, nítorí èyí yóò jẹ́ kí wọ́n yẹ àwọn ọ̀nà ọkọ̀ òkun ilẹ̀ Potogí sílẹ̀. Láfikún, Magellan sọ fún un pé ó ṣeé ṣe kí àwọn Erékùṣù Spice tilẹ̀ wà ní ẹkùn ilẹ̀ Sípéènì gan-an, kó máà sí ní ilẹ̀ Potogí!—Wo àpótí “Àdéhùn Tordesillas.”

Charles jẹ̀wọ̀. Ó fún Magellan ní ọkọ̀ òkun márùn-ún tí ó ti gbó láti tún ṣe fún ìrìn àjò náà, ó fi í ṣe ọ̀gákọ̀ àgbà ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun náà, ó sì ṣèlérí pé òun yóò fún un nínú èrè tí wọ́n bá rí nínú àwọn nǹkan amóúnjẹ-tasánsán tó bá kó bọ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Magellan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ṣùgbọ́n nítorí pé Ọba Manuel fàrékérekè gbìyànjú láti dènà ìwéwèé náà, ó lé ní ọdún kan kí ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun náà tó múra ìrìn àjò ojú omi rẹ̀, tó jẹ́ mánigbàgbé, tán.

“Itú Ìfòkunsọ̀nà Títóbijùlọ Nínú Ìtàn”

Ní September 20, 1519, àwọn ọkọ̀ San Antonio, Concepción, Victoria, àti Santiago—láti orí èyí tó tóbi jù dé orí èyí tó kéré jù—tẹ̀ lé ọkọ̀ Trinidad, tó tóbi ṣìkejì, tó jẹ́ ọkọ̀ apàṣẹ tí Magellan wọ, bí wọ́n ṣe forí lé Gúúsù Amẹ́ríkà. Ní December 13, wọ́n dé Brazil, bí wọ́n sì ti dojú kọ Pão de Açúcar, tàbí Òkè Ńlá Sugarloaf, wọ́n wọ ìyawọlẹ̀ omi òkun rírẹwà ti Rio de Janeiro láti ṣe àwọn àtúnṣe, kí wọ́n sì kó oúnjẹ jọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń bá a lọ síhà gúúsù, síbi tí ń jẹ́ Ajẹntínà nísinsìnyí, wọ́n sì ń fìgbà gbogbo wá el paso, ọ̀nà àbákọjá fífarasin náà tó lọ sí òkun mìíràn. Láàárín àkókò kan náà, ojú ọjọ́ túbọ̀ ń tutù sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn òkìtì yìnyín. Níkẹyìn, ní March 31, 1520, Magellan pinnu láti lo ìgbà òtútù ní èbúté títutù ti San Julián.

Ìrìn àjò náà ti fi ìlọ́po mẹ́fà ju ìrìn àjò àkọ́kọ́ tí Columbus rìn la Àtìláńtíìkì já lọ—síbẹ̀, a kò ì rí ọrùn omi kankan! Ìṣarasíhùwà pẹ̀lú kò mórí yá lọ́nà bí ojú ọjọ́ ní San Julián kò ṣe mórí yá, àwọn ọkùnrin náà, títí kan àwọn ọ̀gákọ̀ àti ọ̀gá òṣìṣẹ́ mélòó kan sì ń fẹ́ pa dà sílé lọ́nàkọnà. Kò yani lẹ́nu nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa pé Magellan yára gbé ìgbésẹ̀ onípinnu, ìṣọ̀tẹ̀ náà kùnà, wọ́n sì pa méjì lára àwọn olórí ìṣọ̀tẹ̀ náà.

Bí ó ṣe sábà máa ń rí, rírí àjèjì ọkọ̀ òkun ní èbúté náà ta ìfẹ́ ìtọpinpin àwọn olùgbé àdúgbò náà tí wọ́n sín gbọnlẹ̀—tí wọ́n sì tóbi—jí. Bí àwọn olùṣèbẹ̀wò náà ti rí ara wọn bí aràrá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òmìrán wọ̀nyí, wọ́n pe ilẹ̀ náà ní Patagonia—láti inú ọ̀rọ̀ èdè Spanish tó túmọ̀ sí “ẹsẹ̀ ńlá”—orúkọ tó ń jẹ́ di òní. Wọ́n tún rí ‘ìkookò òkun tó tóbi tó ọmọ màlúù, àti pẹ́pẹ́yẹ ńlá aláwọ̀ dúdú òun funfun tí ń lúwẹ̀ẹ́ lábẹ́ omi, tí ń jẹja, tó sì ní àgógó bíi ti adìyẹ.’ Dájúdájú o mọ̀ ọ́n—kìnnìún òkun àti ẹyẹ penguin!

Ìjì líle máa ń jà lójijì léraléra ní igun ìpẹ̀kun ayé, àdánù àkọ́kọ́ sì bá ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun náà kí ìgbà òtútù tó parí—ọkọ̀ Santiago kékeré náà fọ́ yángá. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n rìnnà kore, nítorí pé wọ́n rí àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ tó fọ́ náà yọ. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọkọ̀ mẹ́rin yòó kù, bí àfòpiná kéékèèké tí àárẹ̀ ti mú lábẹ́ agbára ìjì líle olómi-dídì tí kò dẹwọ́, ń fi agídí wọ́ lọ síhà gúúsù, sínú omi tí ó túbọ̀ ń tutù sí i—títí di October 21. Bí wọ́n ti ń tukọ̀ lọ lórí omi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dì tán, wọ́n tẹjú mọ́ ọ̀nà kan tó lọ sí ìwọ̀ oòrùn. Ṣé El paso nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni! Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n yí dà, wọ́n sì gba ọ̀nà ọrùn omi tí a wá mọ̀ sí Ọrùn Omi Magellan lẹ́yìn náà! Síbẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan tàbààwọ́n sí àkókò ayọ̀ àṣeyọrí yìí. Ọkọ̀ San Antonio ṣáà dàwátì láàárín àwọn ìsokọ́ra dídíjú ọ̀nà omi àti erékùṣù ọrùn omi náà, ó sì pa dà sí Sípéènì.

Àwọn ọkọ̀ ojú omi mẹ́ta tó kù, tí àwọn ẹsẹ̀ odò tẹ́ẹ́rẹ́ tí kò ṣíni lórí àti àwọn òkè tí òjò dídì bo orí wọn wà lọ́tùn-ún lósì wọn, gba ọrùn omi oníhílàhílo náà. Ní ìhà gúúsù, wọ́n kófìrí iná ṣó ṣò ṣó, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ láti àwọn ibùdó àwọn ará Íńdíà, nítorí náà wọ́n pe ilẹ̀ yẹn ní Tierra del Fuego, “Ilẹ̀ Iná.”

Ìrírí Agbonijìgì ní Pàsífíìkì

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ márùn-ún tó kún fún ìpọ́njú, wọ́n dé orí òkun kan tó parọ́rọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí Magellan fi pè é ní Pàsífíìkì. Àwọn ọkùnrin náà gbàdúrà, wọ́n kọ àwọn orin ìyìn, wọ́n sì yin àwọn ìbọn wọn láti fi gbóríyìn fún ìjagunmólú wọn. Ṣùgbọ́n ayọ̀ wọn kò tọ́jọ́. Ègbé tó ju ohunkóhun tí wọ́n tí ì rí lọ wà níwájú fún wọn, nítorí pé èyí kọ́ ni òkun kékeré tí wọ́n ti ń retí—ńṣe ló wà lọ salalu, ebi sì túbọ̀ ń pa àwọn ọkùnrin náà, ó túbọ̀ ń rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì túbọ̀ ń ṣàìsàn sí i.

Antonio Pigafetta, onígboyà ará Ítálì kan, ní àkọsílẹ̀ kan. Ó kọ ọ́ pé: “Wednesday, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù November, 1520, a . . . wọ òkun Pàsífíìkì, níbi tí a gbé lóṣù mẹ́ta àti ogún ọjọ́ láìkó oúnjẹ wọlé . . . Ògédé bisikíìtì lílọ̀ tó ti bu, tó ní ìdin, tó sì ń run ìgbẹ́ eku . . . , la ń jẹ, omi tó láwọ̀ ìyeyè, tó sì ń ṣíyàn-án la sì ń mu. A tún jẹ pọ̀nmọ́ . . . , lẹ́búlẹ́bú pákó tí a rẹ́, àti àwọn eku tí a ń ra ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ṣílè méjì àbọ̀, a ò sì tilẹ̀ wá rí èyí tó pọ̀ tó.” Nítorí náà, bí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn àríwá ti fẹ́ lu ìgbòkun wọn, tí omi mímọ́gaara sì bọ́ sábẹ́ ọkọ̀ òkun wọn, àrùn jeyínjeyín mú kí ìlera àwọn ọkùnrin náà jagọ̀. Nígbà tí wọ́n fi dé àwọn Erékùṣù Mariana, ní March 6, 1521, 19 nínú wọn kú.

Àmọ́ níhìn-ín, nítorí ìkóguntini àwọn ará erékùṣù náà, ìwọ̀nba oúnjẹ tuntun díẹ̀ ni wọ́n lè kó jọ kí wọ́n tó tún máa tukọ̀ lọ. Níkẹyìn, ní March 16, wọ́n kófìrí ilẹ̀ Philippines. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gbogbo àwọn ọkùnrin náà jẹun kánú, wọ́n sinmi, ìlera àti okun wọn sì dọ̀tun.

Àjálù—Èrò Àfọkànfẹ́ Kan Fẹnu Kọ́lẹ̀

Bí Magellan ti jẹ́ ọkùnrin ẹlẹ́mìí ìsìn gidigidi, ó yí ọ̀pọ̀ olùgbé àdúgbò náà àti àwọn alákòóso wọn lọ́kàn pa dà sí ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ṣùgbọ́n ìtara rẹ̀ náà ló tún fa ìparun rẹ̀. Ó lọ́wọ́ sí awuyewuye ẹ̀yàsẹ́yà kan, ó sì kó 60 ọkùnrin péré kojú 1,500 ọmọ ìbílẹ̀, ní gbígbàgbọ́ pé ọfà afọ́nkùúta, ìbọn àgbétèjìká ńlá, àti Ọlọ́run yóò mú ìṣẹ́gun dájú fún òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n pa òun àti mélòó kan lára àwọn ológun rẹ̀. Nǹkan bí ẹni ọdún 41 ni Magellan nígbà náà. Pigafetta tó jẹ́ adúróṣinṣin kédàárò pé: ‘Wọ́n pa ẹni àwòkọ́ṣe wa, alanilójú wa, ìtùnú wa, àti amọ̀nà wa tòótọ́.’ Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, nǹkan bí ọ̀gá òṣìṣẹ́ 27 tí wọ́n wulẹ̀ ń wòran láti inú ọkọ̀ ojú omi wọn ni àwọn ìjòyè tí wọ́n ti jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀ pa.

Nígbà tí Magellan kú, ibi ojú mọ̀ ló kú sí. Níwájú díẹ̀ síhà gúúsù ni àwọn Erékùṣù Spice wà, tí Malacca, ibi tí ó ti jà ní 1511, sì wà níhà ìwọ̀ oòrùn. Bí ó bá jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí èrò àwọn òpìtàn kan, ó kọjá sí Philippines lẹ́yìn ogun Malacca, a jẹ́ pé, ní gidi, ó rìn lórí òkun yí ayé po—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, bí a ti rí i, kì í ṣe nínú ìrìn àjò kan ṣoṣo. Ó ti gba ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn wọ Philippines.

Àgbákò Nígbà Ìrìn Pa Dà Sílé

Kò ṣeé ṣe láti máa lo ọkọ̀ òkun mẹ́ta mọ́, nítorí iye ènìyàn kéréje ló kù, nítorí náà, wọ́n ri ọkọ̀ Concepción, wọ́n sì gbé ọkọ̀ méjì tó kù dé ibi tí wọ́n ń lọ, àwọn Erékùṣù Spice. Lẹ́yìn tí wọ́n ti di ẹrù nǹkan amóúnjẹ-tasánsán kún wọn, àwọn ọkọ̀ méjèèjì gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Potogí mú àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ Trinidad, wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé.

Ṣùgbọ́n lábẹ́ ìdarí Juan Sebastián de Elcano, tó wà lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ tẹ́lẹ̀, ọkọ̀ Victoria sá là. Ní yíyẹra fún gbogbo èbúté yàtọ̀ sí ọ̀kan, wọ́n fara wewu ní gbígba ọ̀nà àwọn ara Potogí ládùúgbò Ìyawọlẹ̀ Omi Good Hope. Síbẹ̀síbẹ̀, ọgbọ́n àìdúró-kóúnjẹ-sọ́kọ̀ pani lára gidigidi. Nígbà tí wọ́n fi dé Sípéènì níkẹyìn ní September 6, 1522—ọdún mẹ́ta tí wọ́n ti lọ—ènìyàn 18 péré, tí ara wọn kò dá, tí wọ́n sì ti rù kan egungun, ló wà láàyè. Síbẹ̀, àwọn ni afòkunṣọ̀nà tó kọ́kọ́ yí ayé po láìṣeéjá-níkoro. De Elcano sì jẹ́ akọni. Lọ́nà tí ó ṣòro gbà gbọ́, ẹrù nǹkan amóúnjẹ-tasánsán tọ́ọ̀nù 26 tí ọkọ̀ Victoria rù bọ̀ mú èrè tó pọ̀ tó láti fi kájú gbogbo ohun tí ìrìn àjò àwárí náà náni látòkè délẹ̀!

Orúkọ Magellan Kò Pa Run

Wọ́n fi ipò tó tọ́ sí Magellan nínú ìtàn dù ú lọ́pọ̀ ọdún. Nítorí bí ìryìn àwọn ọ̀gákọ̀ tó ṣọ̀tẹ̀ náà ṣe ṣi àwọn ará Sípéènì lọ́nà, wọ́n ba orúkọ rẹ̀ jẹ́, ní wíwípé ó ti le koko jù, kò sì tóótun. Àwọn Potogí kà á sí ọ̀dàlẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn àkọsílẹ̀ rẹ̀ pòórá nígbà tí ó kú, bóyá àwọn tí àkọsílẹ̀ náà ti lè tú láṣìírí ló palẹ̀ rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ọpẹ́lọpẹ́ Pigafetta tí kó ṣeé fà bọ abẹ́ náà—ọ̀kan lára àwọn afòkunṣọ̀nà 18 tó yí ayé po náà—àti àwọn bíi 5 tí wọ́n jọ rìnrìn àjò náà, a ní àkọsílẹ̀ díẹ̀ bó ti wú kó kéré tó nípa ìrìn àjò ojú òkun alájàálù, síbẹ̀ tí ó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, yí.

Bí àkókò ti ń lọ, ìtàn pa èrò dà, a sì ń bọlá tó yẹ fún orúkọ náà, Magellan, nísinsìnyí. Ọrùn omi kan ń jẹ́ orúkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni Àwọn Ìṣùpọ̀ Ìràwọ̀ Magellan—àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ méjì tó wà ní ìhà gúúsù, tí àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ rẹ̀ kọ́kọ́ ṣàpèjúwe—àti ọkọ̀ ìṣèwádìí gbalasa òfuurufú ti Magellan. Láìsí pé a sì ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ń sọ ọ́, Magellan ló sọ òkun tó tóbi jù lágbàáyé—Pàsífíìkì—lórúkọ.

Ní tòótọ́, Richard Humble, kọ̀wé nínú ìwé The Voyage of Magellan pé, “a kò rin ìrìn àjò ẹ̀dá ènìyàn tó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ mọ́ títí ọkọ̀ Apollo 11 fi balẹ̀ sórí Òṣùpá ní ọdún 447 lẹ́yìn náà.” Kí ló mú kí ìrìn àjò náà ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, ó fi hàn pé àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà kì í ṣe apá kan ilẹ̀ Éṣíà, wọn kò sì sún mọ́ ọn, gẹ́gẹ́ bí Columbus ti rò tẹ́lẹ̀. Lọ́nà kejì, níparí ìrìn àjò náà, ìyàtọ̀ ọjọ́ kan nínú àkọsílẹ̀ déètì fi hàn pé ó yẹ kí ibì kan wà, tí àgbáyé fẹnu kò pé ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan ti ń mọ́ wá. Níparí, gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì náà, Isaac Asimov, ṣe sọ, ó fi hàn pé ńṣe ni ayé rí bíríkítí. Dájúdájú, ní ti èyí tí a sọ kẹ̀yìn yí, Magellan fi ohun tí Bíbélì tìkárarẹ̀ ti ń sọ láti 2,250 ọdún sẹ́yìn hàn lọ́nà gbígbéṣẹ́. (Aísáyà 40:22; fi wé Jóòbù 26:7.) Kò sí iyè méjì pé ìyẹn yóò ti dùn mọ́ ọkùnrin tó lẹ́mìí ìsìn gidigidi náà, tó sì ṣí ayé payá, nínú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ rẹ̀ lédè Potogí ni Fernão de Magalhães.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

Àdéhùn Tordesillas

Bí àgbáyé gbígbòòrò ṣe ń ṣí payá sí ilẹ̀ Potogí àti Sípéènì, wọ́n ṣe àdéhùn láti pín ẹ̀tọ́ òwò àti ìṣàkóso lórí àwọn ilẹ̀ tuntun náà. Nípa bẹ́ẹ̀, lábẹ́ ìdarí Póòpù Alexander Kẹfà àti Póòpù Julius Kejì, wọ́n pààlà kan tó la ibi tí a mọ̀ sí Brazil lónìí já. Àwọn ilẹ̀ tí wọ́n bá rí ní apá ìlà oòrùn ààlà yí yóò jẹ́ ti ilẹ̀ Potogí; èyí tó kù, ti Sípéènì. Láìfọgbọ́nyọ, Magellan dábàá fún Ọba Manuel ti ilẹ̀ Potogí pé nígbà tí wọ́n bá gbé ààlà náà láti ìkángun kan dé èkejì ayé, ó ṣeé ṣe kí àwọn Erékùṣù Spice bọ́ sí ìpínlẹ̀ ti Sípéènì. Àkíyèsí àtọkànwá yìí, tí ó gbé karí Òkun Pàsífíìkì tí o kéré ju bó ti rí lọ kan, kàn án lábùkù gidigidi. Lọ́nà títakora, Magellan fi hàn pé òun kò tọ̀nà. Síbẹ̀síbẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún un ní ìdí púpọ̀ sí i láti wá ìtìlẹ́yìn ọba ilẹ̀ Sípéènì.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ohun Tí Ojú Atukọ̀ Ojú Omi Àtètèkọ́ṣe Ń Kàn

Ìgbésí ayé kòlàkòṣagbe atukọ̀ ojú omi kì í ṣe ìtibìkan-débìkan gbígbádùnmọ́ni ṣáá, pàápàá, bí ó bá jẹ́ ìrìn àjò ìṣàwárí gígùn lójú omi—tí ó sábà máa ń gba ọ̀pọ̀ ọdún. Díẹ̀ nínú ohun tí ojú atukọ̀ ojú omi máa ń kàn nìyí:

• Ibùgbé híhá gádígádí lọ́nà bíbaninínújẹ́ àti àìsí ibi ìkọ̀kọ̀

• Ìjẹniníyà rírorò lọ́pọ̀ ìgbà, tó wà lọ́wọ́ ìfẹ́ ọkàn ọ̀gákọ̀ náà

• Àrùn jeyínjeyín àti ikú nítorí àìní fítámì C

• Ikú nítorí ọkọ̀ rírì, ebi, òùngbẹ, àìríhunbora, àti àwọn ọmọ ìbílẹ̀

• Ìgbẹ́ ọ̀rìn tàbí ibà jẹ̀funjẹ̀fun tí omi alárùn àti eléèérí ń fà

• Májèlé inú oúnjẹ tí oúnjẹ bíbàjẹ́ àti oúnjẹ tí kòkòrò ti wọ̀ ń fà

• Ibà tí gígé tí eku tébi ń pa bá géni jẹ ń fà

• Àrùn typhus, tí àwọn iná tó wà ní ara àti aṣọ dídọ̀tí ń fà

• Nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ, ìrètí pípadà-déléláàyè kò ju ìrètí kíkú lọ

[Credit Line]

Century Magazine

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ìrìn Àjò Magellan, 1519 sí 1522

⇦••• Ọ̀nà ◻ Ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ìrìn àjò

Ọrùn Omi Magellan

Wọ́n pa Magellan ní Philippines

Apá tó kẹ́yìn tí Juan Sebastián de Elcano tukọ̀ gbà

[Credit Line]

Magellan: Giraudon/Art Resource, NY; àwòrán ilẹ̀ àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.; ohun èlò àfiwòfuurufú: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Adler Planetarium

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ferdinand Magellan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

“Victoria,” ọkọ̀ òkun tó kọ́kọ́ rin àgbáyé yí po. Nínú ọkọ̀ márààrún tí Magellan lò, ẹyọ kan ló kéré jù ú lọ, ó sì kó ènìyàn 45. Ọkọ̀ òkun náà gùn ní nǹkan bíi mítà 21

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn ohun èlò àfimọ̀nà: agogo onígò ń díwọ̀n àkókò, astrolabe sì ń díwọ̀n igun tí ọkọ̀ òkun náà bá wà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́