Àwọn Ará Etruria—Àdììtú Tí Ń Wà Nìṣó
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
“Ilẹ̀ Etruria lágbára gan-an débi pé òkìkí rẹ̀ kàn jákèjádò ayé.”—Livy, Opìtàn ní Ọ̀rúndún Kìíní.
TÍ Ó bá kan ti àwọn ará Etruria, o lè lérò pé o kò tilẹ̀ mọ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó bá jẹ́ álífábẹ́tì èdè Látìn ni a fi ń kọ èdè tí o ń sọ, o ń jàǹfààní àwọn ará Etruria láìmọ̀. Bí kì í bá ṣe ti àwọn ará Etruria, álífábẹ́tì èdè Látìn ì bá ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú a, b, g (bíi ti álífà, bẹ́tà, gámà ti èdè Gíríìkì tàbí áléfì, bétì, gímélì ti èdè Hébérù). Síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ èdè mọ̀ pé a, b, c ló bẹ̀rẹ̀ álífábẹ́tì èdè Etruria, èdè Etruria ṣì ṣòro láti lóye. Èyí sì jẹ́ apá kan péré lára àwọn àdììtú ilẹ̀ Etruria.
Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn òpìtàn ti ń méfò nípa orírun ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ jù lọ yìí. Nígbà tí àwọn ará Etruria rọ́wọ́ mú ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n gbé àjọṣe onílùú ńlá 12 kan kalẹ̀ tí ó ní ìsokọ́ra ìṣòwò tí ó lọ jìnnà dé ilẹ̀ Europe àti Àríwá Áfíríkà. Síbẹ̀, ní kìkì ọ̀rúndún mẹ́rin lẹ́yìn náà, agbára Róòmù tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀ pátápátá. Ṣùgbọ́n kí ni a mọ̀ nípa àwọn ará Etruria, èé sì ti ṣe tí àdììtú náà ṣì wà bẹ́ẹ̀?
Orírun Tó Jẹ́ Àdììtú
Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn òpìtàn, àwọn awalẹ̀pìtàn, àti àwọn onímọ̀ èdè ti ń ṣe kàyéfì nípa orírun àwọn ará Etruria. Ṣé wọ́n ṣí wá láti Lydia, ẹkùn ìpínlẹ̀ kan ní Éṣíà Kékeré, bí Herodotus ṣe fi hàn ni, àbí ọmọ ìbílẹ̀ Ítálì ni wọ́n, bí Díónísíù ti Halicarnassus ṣe sọ ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa? Ó ha lè jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni orírun wọn bí? Ohun yòó wù kí ìdáhùn náà jẹ́, àwọn ìyàtọ̀ ìran àti ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó wà láàárín àwọn àti àwọn ènìyàn tí wọ́n bá pààlà pọ̀ gan-an débi pé nísinsìnyí, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbésí ayé wọn kò dá wa lójú.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a mọ̀ pé àwọn ará Etruria gbilẹ̀ jákèjádò àárín gbùngbùn Ítálì láti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn ará Róòmù ń pè wọ́n ní Tusci, tàbí Etrusci, àgbègbè ibi tí wọ́n sì wà, láàárín Odò Arno ní ìhà àríwá àti Odò Tiber ní ìhà gúúsù, ni a wá mọ̀ sí Tuscany. Ní ìgbà kan, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ará Etruria nípa lórí nǹkan bí 50 lára àwọn èdè ìbílẹ̀ Ítálì ìgbàanì.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè àwọn ará Etruria ń lo irú álífábẹ́tì èdè Gíríìkì ìgbàanì, tí ń mú kí ó jọ pé ó rọrùn láti túmọ̀, ó yàtọ̀ gan-an sí ti àwọn èdè míràn tí a mọ̀. Apá púpọ̀ jù lọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ èdè àwọn ará Etruria kò ṣeé túmọ̀. Síbẹ̀, wọ́n ní ìwé púpọ̀, níwọ̀n bí ìwé ti kó ipa pàtàkì nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn, ní pàtàkì nínú àwọn ọ̀ràn ti ìsìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àpẹẹrẹ àkọlé lédè Etruria ló wà lóde òní—lára àwọn òkúta ibojì, àgé òdòdó, àti pósí tí a fi òkúta alabásítà ṣe—ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ péré ló wà lára wọn, nítorí náà, wọn kò ṣe àǹfààní kan lọ títí ní ṣíṣàlàyé orírun àwọn ọ̀rọ̀ Etruria àti ìtumọ̀ wọn.
Ìgbésí Ayé Wọn àti Aásìkí Wọn
A ṣètò àwọn ará Etruria jọ sí ìpínlẹ̀ ìlú ńláńlá tí ń dá ṣàkóso lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí àwọn ọba kọ́kọ́ ń ṣàkóso àti lẹ́yìn náà, àwọn aṣojú ìjọba. Àwọn ìlú ńlá wọ̀nyí para pọ̀ di àwùjọ Etruria kan, tí ó jẹ́ àwùjọ tí kò so pọ̀ ní ti ìsìn, ètò ọrọ̀ ajé, àti ìṣèlú. Wọ́n ṣe omi ẹ̀rọ sí àwọn ilé kan ní Etruria, wọ́n sì wà ní àwọn òpópó tí a fi òkúta tẹ́, tí ó ní àwọn ibi ìdàgbẹ́sí. Wọ́n ṣàmúlò àwọn ọ̀nà ọ̀gbàrá gidi gan-an. Àwọn ọba ilẹ̀ Etruria ló yí Róòmù fúnra rẹ̀ pa dà kúrò ní ọ̀wọ́ àwọn abúlé sí ìlú ńlá ẹlẹ́wà, tí a mọ ògiri yí ká, tí ó ní àwọn ibi ìdàgbẹ́sí tí ó já síra, títí kan Cloaca Maxima, tí a ṣì lè rí lónìí.
Aásìkí àwọn ará Etruria wá láti inú ọ̀pọ̀ ohun àmúṣọrọ̀ tí ó wà ní àwọn àgbègbè tí wọ́n ń ṣàkóso, bí ibi ìwakùsà irin tí ó wà ní erékùṣù Elba nítòsí wọn. Láti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn fún mẹ́táàlì lọ́rùn, àwọn ará Etruria ń da irin, fàdákà, àti bàbà—wọ́n tilẹ̀ ń ra agolo wọlé láti àwọn Erékùṣù Ilẹ̀ Britain. Ní àfikún sí àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, àgbègbè tí wọ́n wà jẹ́ kí wọ́n ní ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó dára fún iṣẹ́ àgbẹ̀ àti fífi ẹran jẹko, wọ́n ń ṣèmújáde ọkà, ólífì, àti àjàrà àti gẹdú. Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àdánidá wọ̀nyí àti òwò abẹ́lé àti òwò ilẹ̀ òkèèrè tó gbòòrò jẹ́ kí àwọn ará Etruria ní ètò ọrọ̀ ajé tí ó gbèrú.
Àwọn ará Etruria jẹ́ àgbà atukọ̀ ojú omi. Ní ọdún 540 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun ilẹ̀ Etruria àti Carthage ṣẹ́gun àwọn ará Gíríìkì, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fìdí òwò ilẹ̀ òkèèrè Etruria múlẹ̀. Níwọ̀n bí wọ́n ti hùmọ̀ ọkọ̀ ogun, wọ́n ṣe tán láti jagun. Àwọn ìmújáde bíi bucchero lílókìkí náà (ìkòkò amọ̀ dúdú) ni wọ́n ń kó gba ojú òkun lọ sí ilẹ̀ Sípéènì àti Íjíbítì jíjìnnà réré. Àwọn ará Etruria ń kó wáìnì gba àwọn ọ̀nà ìṣòwò orí ilẹ̀ lọ sí Gaul (ilẹ̀ Faransé) àti Germania (Germany), wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ tan òkìkí wọn kálẹ̀.
Bí Àwọn Ará Etruria Ṣe Ń Gbádùn Ayé Wọn
Àwọn iṣẹ́ ọnà àwọn ará Etruria wà lára àwọn orísun ìsọfúnni tí ó tí ì pẹ́ jù lọ, tí ó sì kún fún òye jíjinlẹ̀ jù lọ nípa wọn. Àwọn ará Etruria tí wọ́n fẹ́ràn afẹ́ ń ṣèmújáde àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onígóòlù ńláńlá, títí kan àwọn yẹtí, gbẹ̀dẹ̀ àlẹ̀máyà, ohun ọ̀ṣọ́ ọrùn, ohun ọ̀ṣọ́ àsomọ́wọ́, àti àwọn gbẹ̀dẹ̀ ọrùn. Kódà lónìí, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun àfidárà ọnà ṣe àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ńláńlá, ní lílo àwọn ìlẹ̀kẹ̀ onígóòlù tín-tìn-tín, ṣì jẹ́ ohun àwámáàrídìí. Ní àfikún sí àwọn abọ́ ìmumi, àwo, ife, àti àwọn àwo oúnjẹ tí wọ́n fi fàdákà àti àwọn mẹ́táàlì ṣíṣeyebíye mìíràn ṣe, àwọn ará Etruria ṣe ọnà, wọ́n sì gbẹ́ àwọn ohun mìíràn bí eyín erin.
Àwọn ohun gbígbẹ́, iṣẹ́ ọnà, àti àwòrán ara ògiri tí a ti rí ti ṣí bí àwọn ará Etruria ṣe ń gbádùn ayé wọn tó payá. Wọ́n gbádùn wíwo ìdíje fífi kẹ̀kẹ́ ogun sáré, ìdíje ẹ̀ṣẹ́ kíkàn, ìdíje ẹkẹ jíjà, àti àwọn eré àṣedárayá mìíràn. Ọba máa ń wo ìwọ̀nyí, bóyá lórí ìjókòó tí wọ́n fi eyín erin ṣe, tí àwọn ẹrú tí wọ́n kó mọ́ ìkógun rọ̀gbà yí ká. Aṣọ àwọ̀lékè elése àlùkò rẹ̀, tí ó jẹ́ àmì ipò rẹ̀, wá di ohun tí àwọn ará Róòmù ń lò. Ní ilé, yóò rọ̀gbọ̀kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ lákòókò oúnjẹ, yóò sì máa gbọ́ fèrè tàbí fèrè oníhòméjì, yóò sì máa wo oníjó kan, nígbà tí àwọn ẹrú rẹ̀ ń sìnrú fún un.
Ní ìyàtọ̀ gédégédé sí àwọn ará Gíríìkì tàbí àwọn ará Róòmù, àwọn obìnrin láwùjọ Etruria gbádùn ipò àparò-kan-ò-ga-jùkan-lọ ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Wọ́n lè ní ohun ìní, wọ́n sì gbádùn àwọn ayẹyẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Àwọn obìnrin Etruria ní orúkọ tiwọn àti orúkọ ìdílé, tí ó jẹ́ ẹ̀rí sísọ tí wọ́n sọ pé àwọn ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin.
Àwọn Ìgbàgbọ́ Ìsìn Ṣíṣàjèjì
Òpìtàn kan ní ọ̀rúndún kìíní pe àwọn ará Etruria ní “àwọn ẹni tí wọ́n fara fún ìsìn ju àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn lọ.” Àwọn ará Etruria ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run púpọ̀, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí àwọn mẹ́talọ́kan gan-an, tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì oníbẹta, tàbí onígbọ̀ngàn-mẹ́ta fún. Gbọ̀ngàn kọ̀ọ̀kan ní ère kan. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Etruria so pọ̀ mọ́ àwọn èrò àròsọ ti Bábílónì. Èyí tí ó gba iwájú jù lọ lára wọn ni èrò ìwàláàyè lẹ́yìn ikú àti ibùgbé àwọn òkú. Ńṣe ni wọ́n ń sin òkú tàbí kí wọ́n dáná sun ún. Bí wọ́n bá dáná sun ún, wọ́n máa ń da eérú rẹ̀ sínú ìgò tí ó ní oríṣiríṣi ìrísí. Lẹ́yìn gbígbé ìgò náà sínú sàréè, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ronú pé kò ṣeé máà ní fún ìwàláàyè ní ibùgbé àwọn òkú, wọn óò ṣe ààtò ìsìn, ìrúbọ, àti ìtọ́po-sójú-òòṣà. Wọ́n ń fi àwọn àwòrán àlẹ̀mógiri jíjojúnígbèsè ṣe ara sàréè àwọn ọlọ́rọ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tí ó ní onírúurú àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ nínú, tí ó máa ń fi àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí àwòrán onírúurú àwọn ẹ̀dá bíbanilẹ́rù hàn. Gẹ́gẹ́ bí orísun ìsọfúnni kan ti sọ, “àwọn ará Etruria máa ń fìgbà gbogbo nífẹ̀ẹ́ sí àwòrán ohun akójìnnìjìnnì-báni.”
A lè tọpa àṣà wíwo ẹ̀dọ̀ki, gẹ́gẹ́ bí irú ẹ̀kọ́ iṣẹ́ wíwò tí àwọn ará Etruria ń dán wò, pa dà lọ sí Bábílónì. (Fi wé Ìsíkẹ́ẹ̀lì 21:21.) Gbogbo apá ìgbésí ayé wọn àti ìpinnu ṣíṣe wọn ni ó so pọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́run. Àwọn ènìyàn máa ń wo ilẹ̀ tàbí òfuurufú fún àwọn àmì àpẹẹrẹ. Iṣẹ́ wíwò wọ́pọ̀ gan-an débi pé irú àwọn àṣà wọ̀nyí wá di èyí tí a mọ̀ sí disciplina Etrusca, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti Etruria.
Ìgbàwọlé àti Ìmúkúrò
Ní ọdún 509 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìlà ìdílé àwọn ọba Etruria tí ó ti ṣàkóso Róòmù fún ọ̀rúndún kan dópin. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ohun tí yóò wá ṣẹlẹ̀. Ní ìhà àríwá, ogun tí àwọn Celt ń gbé ń wu àwọn ará Etruria léwu, ìgbóguntì náà sì ń mú kí agbára tí àwọn ará Etruria ní lágbègbè yẹn bọ́. Ní ìhà gúúsù, ìjà ààlà ilẹ̀ láìdáwọ́dúró pẹ̀lú àwọn ará Ítálì ìgbàanì ń jin ìpìlẹ̀ agbára wọn lẹ́sẹ̀, ó sì ń fún pákáǹleke abẹ́lé níṣìírí láwùjọ.
Ní ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, àgbègbè ilẹ̀ Etruria ti wà lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù. Bí àkókò ìmúgbòòrò àṣà ìbílẹ̀ Róòmù, tàbí sísọ nǹkan di ti Róòmù ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní ọdún 90 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí wọ́n nawọ́ àǹfààní jíjẹ́ ọmọ ilẹ̀ Róòmù dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn Ítálì ìgbàanì, àwọn àmì ìkẹyìn tí a lè fi dá ilẹ̀ Etruria mọ̀ pòórá. Wọ́n ní kí àwọn ará Etruria máa sọ èdè Látìn, wọ́n sì gbà wọ́n sínú àgbègbè ilẹ̀ Róòmù. Ó ṣe kedere pé ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Róòmù ló sapá láti túmọ̀ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ pa àwọn ìwé tí a kọ lédè Etruria mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Etruria pòórá nínú àkọsílẹ̀ ìtàn. Ṣùgbọ́n ó tún fi ohun kan sílẹ̀.
Ogún Tí Ó Tí Ì Pẹ́ Jù
Ogún ilẹ̀ Etruria ṣì wà ní Róòmù lónìí pàápàá. Ọwọ́ àwọn ará Etruria ni àwọn ará Róòmù ti jogún tẹ́ńpìlì Capitoline wọn, tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn mẹ́talọ́kan náà, Júpítà, Juno, àti Minerva; àwọn tẹ́ńpìlì oníbẹta wọn; àwọn ògiri ìlú ńlá wọn àkọ́kọ́; àti àwọn ibi ìdàgbẹ́sí wọn tí ń fa ìgbẹ́ kúrò ní Ibi Ìpàdé náà. Kódà ilẹ̀ Etruria ni ìkookò Capitoline náà, (Lupa Capitolina), àmì ilẹ̀ Róòmù, ti pilẹ̀ ṣẹ̀. Ní àfikún, àwọn ará Róòmù ń ṣàmúlò díẹ̀ lára àwọn àṣà ìbílẹ̀ Etruria, bí àwọn ìdíje tí ó kan jíja àjàkú àti bíbá àwọn ẹranko jà. (Fi wé Kọ́ríńtì Kíní 15:32.) Láìsí àní-àní, irú ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé rẹ̀ pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ilẹ̀ Etruria.—Kọ́ríńtì Kejì 2:14.
A tún ti lo àwọn àmì láti ilẹ̀ Etruria ní ọ̀nà púpọ̀. Ọ̀pá àlùfáà ilẹ̀ Etruria, tí ó jọ ọ̀pá olùṣọ́ àgùntàn, ni a ti sọ pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pá oyè tí àwọn bíṣọ́ọ̀bù Kirisẹ́ńdọ̀mù ń lò. Àwọn ọ̀pá àṣẹ adájọ́ ti ilẹ̀ Etruria (àwọn ọ̀pá tí a so àáké sí àárín wọn) ni àwọn ará Róòmù ń lò gẹ́gẹ́ bí àmì àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àmì nígbà Ìyípadà Tegbòtigaga ilẹ̀ Faransé, òun sì ni ẹgbẹ́ Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ lò ní Ítálì ní ọ̀rúndún ogún.
Lójú ìsapá àpawọ́pọ̀ṣe tí àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣe ní híhú àwọn ohun àtijọ́ jáde, orírun àwọn ará Etruria àti apá púpọ̀ nínú ìgbésí ayé wọn ṣì jẹ́ àwámáàrídìí.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ETRURIA
ÍTÁLÌ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
1. Abo ìkookò Capitoline, àmì ìlú ńlá Róòmù, ẹ̀dà tí wọ́n fi idẹ ilẹ̀ Etruria ṣe, ti ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa
2. Èdè Etruria (lápá ọ̀tún) àti èdè Fòníṣíà (lápá òsì), ni a fi kọ ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ sí Uni (Astarte) sára àwọn òkúta oníwúrà wọ̀nyí
3. Pósí olókùúta ti àwọn tọkọtaya kan ní ilẹ̀ Etruria
4. Ọ̀nà olórùlé títẹ̀ kan ní ilẹ̀ Etruria láti ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn ará Róòmù kọ́ bí a ṣe ń kọ́ òrùlé títẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ará Etruria
5. Agbada tí àwọn ará Etruria fi ń po wáìnì àti ohun tí a ń gbé e kà ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa
[Credit Line]
Wàláà onígóòlù: Museo Nazionale di Villa Giulia, Roma; pósí olókùúta àti agbada: Musée du Louvre, Paris