“Mo Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí fún Ọjọ́ Saturday Gbígbádùnmọ́ni Kan”
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÙKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NORWAY
Eivind Blikstad, tí ń kọ̀ròyìn fún ìwé agbéròyìnjáde ojoojúmọ́ ilẹ̀ Norway náà, Telemark Arbeiderblad, fi ohun tó wà lókè yí ṣe àkọlé àpilẹ̀kọ rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó sọ ìbínú rẹ̀ nípa ìpolówó ìwé, ìtajà lórí tẹlifóònù, àti ìbẹ̀wò sí ilé rẹ̀ láìṣe pé ó béèrè fún wọn—ní pàtàkì ní òròòwúrọ̀ Saturday. Lẹ́yìn náà, ó kọ̀wé pé:
“Wọ́n dé lójijì. Wọ́n wà lẹ́nu ọ̀nà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Lówùúrọ̀ Saturday. Wọ́n mú ìwé ìròyìn Jí!, nọ́ńbà 17, September 8, 1996 wá. [“Àwọn Amerind—Kí Ni Ìrètí Wọn fún Ọjọ́ Ọ̀la?”] Wọ́n béèrè bí mo bá fẹ́ láti ka ìwé ìròyìn náà nítorí pé ohun kan tí wọ́n gbà gbọ́ pé n óò nífẹ̀ẹ́ sí wà nínú rẹ̀. . . . Kí n tó lè sọ pé n kò fẹ́, ọ̀kan lára wọn tún sọ pé: ‘Àpilẹ̀kọ nípa àwọn Àmẹ́ríńdíà wà nínú rẹ̀. A mọ̀ pé o ti ń kọ ohun púpọ̀ nípa kókó ọ̀rọ̀ náà.’
“Mo há sí wọn lọ́wọ́ níbẹ̀. Nítorí bí a bá sọ̀rọ̀ ìwúrí síni, gbogbo ohun tó le lọ́kàn ẹni yóò fò lọ. Nínú ilé, nídìí oúnjẹ òwúrọ̀, ọkàn ìtọpinpin mi túbọ̀ ń yán hànhàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọjọ́ ọ̀la àwọn Àmẹ́ríńdíà jẹ́ ohun méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ bára dọ́gba. Mo gbé dígí mi sójú, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ní rírẹ ara mi sílẹ̀ díẹ̀, ṣé ẹ mọ bí ènìyàn ṣe máa ṣe tí ó bá ronú gan-an pé òun ń fi àkókò ṣòfò lórí ohun kan.
“Kí a má fa ọ̀rọ̀ gùn, ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí kọ nípa ipò tí àwọn Àmẹ́ríńdíà wà dára—ó dára gan-an. Mo dámọ̀ràn pé kí àwọn olùkọ́ ní Norway jáwọ́ ẹ̀tanú. Kí wọ́n kọ̀wé béèrè fún ẹ̀dà rẹ̀ fún gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn! Ìlò àwọn orísun ìtọ́ka rẹ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe, ọ̀nà ìgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ sì yéni yékéyéké. Ó tún kún fún àìlábòsí látòkèdélẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn tí ojú ìwòye àwọn Àmẹ́ríńdíà àti ti Àwọn Ẹlẹ́rìí ti yàtọ̀. Kò sí ìyannijẹ. Ìṣòro lílekoko kan ní àwọn ilẹ̀ mélòó kan tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Àmẹ́ríńdíà jẹ́ ti ìgbékalẹ̀ àwọn ilé tẹ́tẹ́. Ìwọ̀nyí ń pèsè iṣẹ́ tí wọ́n nílò gan-an, ṣùgbọ́n ó ń ṣe àwọn àkóbá nípa ti ìwà rere pẹ̀lú. Wọ́n fọgbọ́n jíròrò ọ̀ràn náà lọ́nà tí òǹkàwé yóò fi lóye bí ó ṣe rí láti jẹ́ Àmẹ́ríńdíà kan ní ọ̀rúndún wa.”
Blikstad parí ọ̀rọ̀ pé: “Bí ohun tí mo kà ti tù mí lára tó, mo ka àwọn ohun tó kù nínú Jí! tí mo ń kà náà. Ní àfikún sí i, àpilẹ̀kọ kan wà níbẹ̀ tí ń ru ìmọ̀lára sókè gan-an nípa àwọn ilé ìjọsìn àti ṣọ́ọ̀ṣì tí ń kógbá sílé ní àfonífojì ìwakùsà Rhondda, ní Wales. . . .
“Ṣé mo ti gbàgbé èrò tí mo ní pátápátá ni? Mo ha ti fi èrò àìgbà-pọ́lọ́runwà sílẹ̀ gba ti Àwọn Ẹlẹ́rìí láìjanpata ni bí? . . . Kì í ṣe lónìí ni ìyẹn yóò ṣẹlẹ̀. A nílò ìránnilétí déédéé nípa ìjẹ́pàtàkì mímú ẹ̀tanú kúrò. Ìgbà míràn tí mo bá rí i tí a ń fẹ̀sùn irọ́ kan Àwọn Ẹlẹ́rìí, ó kéré tán, mo mọ̀ pé wọn kò purọ́ nípa àwọn Àmẹ́ríńdíà.”
Nítorí ìbéèrè àkànṣe fún ìtẹ̀jáde Jí! tí ó sọ nípa àwọn Àmẹ́ríńdíà, a tẹ 37,000 ẹ̀dà sí i lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé Watchtower Society tó wà ní New York. Ìjọ kan ní Arizona, béèrè fún 10,000 láti pín in kárí ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ wọn lọ́nà àkànṣe.
Bí o bá fẹ́ láti ṣàkíyèsí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìsí ẹ̀tanú, má ṣàìkọ̀wé sí àwọn tí ń ṣe ìwé ìròyìn yí, ní lílo àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5, tàbí kí o tẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà ládùúgbò rẹ láago. A kò béèrè ohun àfidandangbọ̀nṣe kankan, a kò sì béèrè owó. Ìwọ yóò rí ìdáhùn tí ó ṣe sàn-án.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Ojú ará Àmẹ́ríńdíà: D. F. Barry Photograph, Thomas M. Heski Collection; Ará Àmẹ́ríńdíà tí ń jó: Men: A Pictorial Archive from Nineteenth-Century Sources/Dover Publications, Inc.; àwọn àgọ́ ṣúúṣùùṣú: Leslie’s; iṣẹ́ ọnà onígunmẹ́rin: Decorative Art; àwọn iṣẹ́ ọnà robotoroboto: Authentic Indian Designs