Ojú ìwé 2
Ajàkálẹ̀ Àrùn Yóò Ha Dópin Láé Bí? 3-10.
Láìka ìlọsíwájú nínú ìmọ̀ ìṣègùn àti sáyẹ́ǹsì sí, ńṣe ni àjàkálẹ̀ àrùn àti àìsàn ń pọ̀ sí i. Àjàkálẹ̀ àrùn ní ọ̀rúndún ogún yìí ha jẹ́ ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa àkókò òpin bí? A óò ha rí ayé kan tí kò ti sí àìsàn láé bí?
Ọ̀nà Mẹ́fà Tí O Lè Gbà Dáàbò Bo Ìlera Rẹ 11
Kà nípa ohun mẹ́fà tí o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn tí ó lè fa àìsàn.
Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà—Báwo Lo Ṣe Lè Kojú Rẹ̀? 21
Bíbínú lọ rangbọndan àti ìwà ipá tí ń tìdí rẹ̀ jáde láàárín àwọn awakọ̀ jẹ́ ìṣòro tí ń pọ̀ sí i. Kí ni o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà?