ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìran Kan Tí Kò Nírètí
  • Ẹrù Wúruwùru Ń Dí Ibùdó Gbalasa Òfuurufú Lọ́wọ́
  • Àwọn Ìnàkí Aríjàgbá
  • Àwọn Amusìgá ní Éṣíà
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Àlùfáà Dẹwọ́ Ìlànà Rẹ̀ Lórí Ìbálòpọ̀
  • Bí Ìpápánu Ṣe Ń Ba Eyín Jẹ́
  • Ìgbàgbọ́ Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Nínú Ọlọ́run
  • Àwọn Fáírọ́ọ̀sì Arìnkáyé
  • Odò Ganges Ń Gbẹ
  • Jíjalè Lójú Òkun Ń Pọ̀ Sí I
  • Bó O Ṣe Lè Máa Tọ́jú Eyín Rẹ
    Jí!—2005
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Bí Eyín Ìgbín Limpet Ṣe Rí
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ìran Kan Tí Kò Nírètí

Ìwé agbéròyìnjáde The Australian sọ pé àwọn ìwádìí tí ń ṣàfiwéra àwọn ọmọ ọdún 15 sí 24 òde òní pẹ̀lú àwọn èwe ìran méjì sẹ́yìn ti fi hàn pé ìjoògùnyó, ìwà ọ̀daràn, àti ìpara-ẹni, ti lọ sókè. Richard Eckersley, olùṣàtúpalẹ̀ ètò lílo búrùjí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ tí ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ṣàkópọ̀ èrò ọ̀pọ̀ èwe òde òní pé: “Àwọn èwe gbà gbọ́ pé ó yẹ kí ìgbésí ayé máa runi sókè, kí ó máa múni lórí yá, pé àwọn ní láti máa bójú tó ara àwọn, pé àwọn gbọ́dọ̀ lómìnira fàlàlà láti yan ọ̀nà ìgbésí ayé, pé àwọn ìjọba kò lè yanjú àwọn ìṣòro ẹgbẹ́ àwùjọ, àti pé àwọn fúnra àwọn kò lágbára láti yí àwọn ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà pa dà.” Ọmọdébìnrin ọlọ́dún 15 kan, tí ń jẹ́ Shanu, sọ pé: “Iye ènìyàn ń pọ̀ sí i, a sì ní láti máa jìjàdù lórí iṣẹ́ tí kò pọ̀, ibùgbé tí kò tó, gbogbo nǹkan tí kò tó.”

Ẹrù Wúruwùru Ń Dí Ibùdó Gbalasa Òfuurufú Lọ́wọ́

Lẹ́yìn ọdún 11, àwọn tí ń lo ibùdó gbalasa òfuurufú ti Rọ́ṣíà náà, Mir, ń kọ́ láti kojú ìṣòro kan tí kò ṣàjèjì sí àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé—ohun tí ó yẹ kí a ṣe sí gbogbo ohun èlò tí a kó jọ. Nítorí pé gbalasa òfuurufú kò tẹ̀wọ̀n, a ní láti so àwọn ohun àìgbọ́dọ̀-mánìí bí aṣọ tí a ń wọ̀ ní gbalasa òfuurufú, àwọn okùn kọ̀ǹpútà, páálí oúnjẹ, àwọn ohun ìṣiṣẹ́, àti àwọn ẹ̀yà ara ohun èlò mọ́ ilẹ̀, òrùlé, àti ògiri. Àmọ́ bí a ti so àwọn ẹrù wúruwùru wọ̀nyí tí ó ga tó 30 sẹ̀ǹtímítà sí gbogbo ibi tí àyè wà, ńṣe ni àwọn ògiri Mir túbọ̀ ń há sí i. Nígbà tí a bá ṣèfilọ́lẹ̀ Ibùdó Gbalasa Òfuurufú Àgbáyé tuntun, ohun kan tí ó ṣeé ṣe kí àwọn arìnrìn-àjò lọ sínú gbalasa òfuurufú ní ni ohun ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́sí tí a ṣe sínú ibùdó náà. A óò mọrírì ìyẹn gan-an láìsíyèméjì, nítorí pé, títí di báyìí, lẹ́yìn tí àwọn olùgbé inú Mir bá jẹun tán, wọ́n ní láti lu àwọn agolo di pẹlẹbẹ, kí wọ́n kó wọn pa dà sínú àpótí oúnjẹ, kí wọ́n sì so wọ́n mọ́ ara àwọn ògiri.

Àwọn Ìnàkí Aríjàgbá

Ewu kan tí ó ṣàjèjì kojú àwọn awakọ̀ ní ọ̀kan lára àwọn òpópó tí ọkọ̀ ti ń lọ tí ó sì ń bọ̀ jù ní Gúúsù Áfíríkà níbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí—ọ̀wààrà òkò tí agbo àwọn ìnàkí kan ń sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ṣe sọ, àwọn ìnàkí náà dènà de àwọn ọlọ́kọ̀ níbi òkè ńlá kan lójú ọ̀nà tó wà láàárín Cape Town àti Johannesburg. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tí ì gbọ́ ìròyìn pé àwọn ènìyàn kankan fara pa tàbí pé ọkọ̀ kankan ṣèjàǹbá, àwọn ọlọ́pàá ètò ìrìnnà ọkọ̀ lọ sọ̀kò láti lé àwọn ẹranko náà lọ kúrò ní òpópó náà. Ìròyìn nípa ẹni tó ja àjàṣẹ́gun nínú ìjà ogun òkò jíjù láàárín àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ìnàkí náà kò tí ì ṣe kedere.

Àwọn Amusìgá ní Éṣíà

A fojú díwọ̀n pé ní Vietnam, àwọn ọkùnrin ti ń mu sìgá fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 73 nínú ọgọ́rùn-ún. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association ṣe sọ, èyí ni “iye àwọn ọkùnrin tó pọ̀ jù lọ tí ń mu sìgá lágbàáyé.” Lọ́nà àfiwéra, ó jọ pé kìkì ìpín 4 ó lé díẹ̀ nínú ọgọ́rùn-ún ni àwọn obìnrin ará Vietnam tí ń mu sìgá. Bákan náà ni ó rí ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Éṣíà tó fara kan òkun Pàsífíìkì. Bí àpẹẹrẹ, ní Indonesia, ìpín 53 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin àti ìpín 4 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ní ń mu sìgá; nígbà tí ó jẹ́ pé ní China, ìpín 61 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin àti ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ní ń mu sìgá

Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Àlùfáà Dẹwọ́ Ìlànà Rẹ̀ Lórí Ìbálòpọ̀

Ìwé ìròyìn The Christian Century ròyìn pé ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ àlùfáà Ìjọ Episcopal kan ní Virginia “ti dẹwọ́ ìlànà tí ó ti gbé kalẹ̀ láti ọdún 25 wá, tí ó kà á léèwọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́ àti òṣìṣẹ́ àbójútó láti hùwà ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó tàbí ìbẹ́yàkan-náà-lòpọ̀.” Alága ìgbìmọ̀ náà, Peter J. Lee, sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká tẹ́wọ́ gba òtítọ́ ọ̀rọ̀, ọjọ́ orí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ àlùfáà ti lé ní 30 ọdún tàbí 40 ọdún. Kò sí àwọn obìnrin alábòójútó, kò sì sí àyẹ̀wò òru láti mọ ẹni tó wà lórí bẹ́ẹ̀dì tàbí tí kò sí lórí bẹ́ẹ̀dì.” Láti ọdún 11 tó kọjá wá, iye àwọn tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ àlùfáà náà ti fi ìpín 33 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù. Láfikún sí i, láti ọdún 25 wá, ìpíndọ́gba ọjọ́ orí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ń wọ ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ àlùfáà náà ti lọ sókè láti ọdún 27 sí 40. Lee sọ pé: “Ohun tí èmi gẹ́gẹ́ bí alága ìgbìmọ̀ ń gbìyànjú láti ṣe ni láti ṣèdíwọ́ fún dídu ẹni ọdún 28 kan láǹfààní wíwọ ilé ẹ̀kọ́ náà nítorí pé a rí i pé ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àfẹ́sọ́nà rẹ̀.”

Bí Ìpápánu Ṣe Ń Ba Eyín Jẹ́

Ó pẹ́ tí a ti mọ̀ pé dídín àwọn ìpápánu oníṣúgà kù lè ṣèrànwọ́ láti gbógun ti ìbàjẹ́ eyín. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìwé atọ́nà ìtọ́jú eyín fún ìdílé náà, How to Keep Your Family Smiling, ṣe wí, ohun tí ó ṣe pàtàkì gidi ni láti kíyè sí àkókò tí o ń jẹ ìpápánu àti bí ó ti ń ṣe lemọ́lemọ́ tó. Nígbà tí àwọn ohun jíjẹ aládùn àti àwọn èròjà carbohydrate tí a ti yọ èérí inú rẹ̀ dà nù bá fara kan èérí ìdí eyín rẹ, yóò di ásíìdì kan. Ìwé pẹlẹbẹ náà sọ pé, ásíìdì yí yóò wá gbógun ti kèrékèré tí ó bo eyín rẹ fún nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú. Láàárín àkókò yí, eyín lè bẹ̀rẹ̀ sí í díbàjẹ́. Síwájú sí i, “èyí lè máa ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí o bá jẹ ìpápánu aládùn tàbí onítáàṣì.” Nítorí náà, bí o bá ń fẹ́ jẹ ìpápánu, “ó sàn kí o jẹ gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan,” kí o tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ásíìdì bo eyín rẹ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jíjá ìpápánu kan náà jẹ ní àkókò gígùn ń yọrí sí ìgbóguntì ásíìdì fún ìgbà gígùn. Láti ṣèrànwọ́ fún dídènà ìbàjẹ́ eyín, àwọn oníṣègùn ìtọ́jú eyín dámọ̀ràn pé kí o máa fọ eyín rẹ lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́, ó kéré tán. Bákan náà, má gbàgbé láti fi fọ́nrán òwú ìfọyín fọ àwọn àlàfo àárín eyín rẹ lójoojúmọ́.

Ìgbàgbọ́ Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Nínú Ọlọ́run

Ní 1916, afìṣemọ̀rònú ará Amẹ́ríkà kan, James Leuba, wádìí lẹ́nu 1,000 onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí a wulẹ̀ ṣà láìròtì bóyá wọ́n gba Ọlọ́run gbọ́. Kí ni ìdáhùn wọn? Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó dáhùn, ìpín 42 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́. Leuba sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run yóò dín kù bí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ bá ṣe ń tàn kálẹ̀ sí i. Nísinsìnyí, tí ó ti lé ní 80 ọdún lẹ́yìn náà, Edward Larson, ti Yunifásítì Georgia, ti tún ṣe irú ìwádìí olókìkí tí Leuba ṣe tẹ́lẹ̀ náà. Ní lílo àwọn ìbéèrè àti ọ̀nà ìgbàṣe kan náà, Larson béèrè lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá, àti àwọn onímọ̀ ìṣirò bóyá wọ́n gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run kan tí ń bá àwọn ẹ̀dá ènìyàn ṣe nǹkan ní tààrà. Àbájáde ìwádìí náà fi hàn pé nǹkan bí iye onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan náà lónìí, nǹkan bí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún, sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Larson ṣe sọ, “Leuba ṣinú rò bóyá nípa èrò inú ẹ̀dá ènìyàn tàbí nípa agbára tí sáyẹ́ǹsì ní láti tẹ́ gbogbo ohun tí ẹ̀dá ènìyàn nílò lọ́rùn.”

Àwọn Fáírọ́ọ̀sì Arìnkáyé

Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé àwọn ibi ìdàgbẹ́sí inú ọkọ̀ òfuurufú máa ń ní àwọn kẹ́míkà tí a retí pé yóò máa pa àwọn fáírọ́ọ̀sì nínú, ṣùgbọ́n àwọn fáírọ́ọ̀sì kan máa ń la wíwà tí wọ́n wà nínú kẹ́míkà náà já. Mark Sobsey, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa àyíká ní Yunifásítì Àríwá Carolina, rí i pé, èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára àwọn ìgbẹ́ tí òun yẹ̀ wò nínú àwọn ọkọ̀ tí ń lọ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè, tó balẹ̀ ní United States ló ní àwọn alààyè fáírọ́ọ̀sì nínú. Ní United States, wọ́n sábà máa ń da kẹ́míkà sí ìgbẹ́ tí wọ́n bá dà láti inú ọkọ̀ òfuurufú ní àwọn ibùdó tí a ti ń ṣàbójútó ìyàgbẹ́ kí wọ́n tó dà wọn sí àyíká ìdàgbẹ́sí lẹ́yìn náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ewu náà wà pé àwọn kan lára àwọn fáírọ́ọ̀sì náà lè ṣètànkálẹ̀ àwọn àrùn bí àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele A àti E, àrùn lọ́rùnlọ́rùn, àti àrùn rọpárọsẹ̀. Sobsey fi kún un pé: “Bí àwọn àìsàn tí àwọn ọkọ̀ òfuurufú lágbàáyé lè mú kí ó ràn ṣe pọ̀ tó ń kọni lóminú gidigidi.”

Odò Ganges Ń Gbẹ

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn Híńdù ka odò Ganges, tí a mọ̀ sí Ganga ní Íńdíà, sí odò mímọ́. Odò Ganges tún jẹ́ ẹ̀mí iṣẹ́ àgbẹ̀ ní gbogbo ibi tó gbà kọjá. Ṣùgbọ́n, ìwé ìròyìn India Today sọ pé omi rẹ̀ yára ń gbẹ nísinsìnyí, èyí sì ń mú kí ilẹ̀ gbígbẹ tó gbòòrò máa yọrí láàárín ibi tí omi rẹ̀ dé nísinsìnyí àti ibi tó ń dé tẹ́lẹ̀. A rí bí ìṣàn rẹ̀ ṣe dín kù gidigidi náà gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àìtó òjò àti àfikún nínú bí a ṣe ń lo omi rẹ̀ lápá òkè fún ìbomirinko. Ní àfikún sí pé ó ń wu iṣẹ́ àgbẹ̀ léwu ní àgbègbè náà, ìròyìn náà sọ pé, ìgẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ olókùúta tí àìsí omi ń fà lè mú kí a má lè tukọ̀ gba èbúté Calcutta.

Jíjalè Lójú Òkun Ń Pọ̀ Sí I

Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìjọba Lórí Ìrìn Àjò Lójú Òkun Lágbàáyé sọ pé jíjalè lójú òkun ń pọ̀ sí i—láti 90 ìṣẹ̀lẹ̀ ní 1994 sí ìṣẹ̀lẹ̀ 226 lọ́dún méjì péré lẹ́yìn náà. Pípọ̀ tó ń pọ̀ sí i yìí ń dààmú àwọn oníṣòwò òṣìṣẹ́ ológun ojú omi àti àwọn arìnrìn-àjò afẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe kí iye náà gan-an fi bí ìlọ́po méjì jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Telegraph ti London sọ pé “ọ̀pọ̀ àwọn tó ni ọkọ̀ ojú omi kì í ṣòpò fẹjọ́ sùn nítorí pé ìwádìí tí yóò tẹ̀ lé e lè fa ìfiǹkanfalẹ̀ tí ń pani lára gidigidi.” Àwọn àgbègbè tí ó léwu gan-an ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ni Òkun Mẹditaréníà lẹ́bàá Albania òun Libya àti Òkun Gúúsù Ilẹ̀ China. Aṣojú Oníṣòwò Ológun Ojú Omi Ilẹ̀ Britain kan rọ ilẹ̀ Britain pé kí ó múpò aṣáájú nínú ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè kan tí àjọ UN gbé kalẹ̀ láti gbógun ti àwọn olè ojú omi náà. Ṣùgbọ́n, ìwé agbéròyìnjáde náà ròyìn pé, agbẹnusọ kan fún àwọn tó ní ọkọ̀ ojú omi sọ pé “òun kò rò pé ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe àjọ UN kankan lè ṣe ohunkóhun nípa ìṣòro náà nítorí pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìkọlù náà ń wáyé láàárín omi àdúgbò.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́