Gbogbo Ìsìn Ló Ha Ń sìnni Lọ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Bí?
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn gbà gbọ́ pé gbogbo ìsìn jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó lọ sí ibì kan náà. Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn, ààtò ìsìn, àti àwọn ọlọ́run àjọ́sìnfún àwọn ìsìn jẹ́ irú kan náà. Fún àpẹẹrẹ, wo ère ìtàn ìwáṣẹ̀ Híńdù yìí, láti Kerala, Íńdíà, tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kẹjọ Sànmánì Tiwa.
Ohun arabaríbí ibẹ̀ ni pé akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìsìn ìgbàanì ń jọ́sìn. Fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn ará Gíríìkì ti ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa náà, Diodorus Siculus, ti sọ, ọlọ́run àwọn ará Ámónì náà, Mólékì, pẹ̀lú ní ìrísí ènìyàn àti orí akọ màlúù.
Èé ṣe tí àwọn ìjọra arabaríbí ṣe wà nínú onírúurú ìsìn jákèjádò ayé? Ṣé ibì kan náà ni àwọn ìsìn wọ̀nyí ti ṣẹ̀ wá ni? Wọ́n ha wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó lọ sí ibì kan náà ní tòótọ́ bí? Ọlọ́run ha fọwọ́ sí gbogbo wọn bí?
Àkọsílẹ̀ fífani-lọ́kànmọ́ra tí ó wà nínú ìwé Mankind’s Search for God nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ìdàgbàsókè àwọn ìsìn jàǹkànjàǹkàn lágbàáyé dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè gba ìwé yìí tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yí, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.