ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/22 ojú ìwé 25-27
  • Ijó Rave Ha Jẹ́ Amóríyá Aláìléwu Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ijó Rave Ha Jẹ́ Amóríyá Aláìléwu Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àyẹ̀wò Ìran Ijó Rave
  • Apá Tó Ríni Lára Nínú Ijó Rave
  • Ijó Rave Ha Wà fún Ọ ní Gidi Bí?
  • Oògùn Olóró—Kí Ló Fà á Táwọn Èèyàn Fi Ń lò Ó?
    Jí!—2001
  • Ṣó Yẹ Kí N Máa Lọ Ságbo Ijó Alẹ́?
    Jí!—2004
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Dènà Ẹ̀mí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/22 ojú ìwé 25-27

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ijó Rave Ha Jẹ́ Amóríyá Aláìléwu Bí?

“Nígbà tí mo bá ń jó, tí mo káwọ́ mi sókè, tí orin náà sì ń rìn mí lára, àwọn mìíràn tí ń jó máa ń fún mi lókun. Ńṣe ló dà bí ẹni tí ẹ̀mí mú.”—Gena.

BÁYÌÍ ni Gena ṣe ṣàpèjúwe ìmóríyá tó wà nínú wíwà níbi ijó rave. Àwọn àríyá oníjó, tó sábà máa ń jẹ́ àjómọ́jú yìí, kọ́kọ́ lókìkí ní Britain láàárín àwọn ọdún 1980. Ní báyìí, wọ́n ń yọrí níbi gbogbo lágbàáyé, títí kan Belgium, Kánádà, Germany, Íńdíà, New Zealand, Gúúsù Áfíríkà, àti United States.

Wọ́n máa ń jó ijó rave ní àwọn ilé ijó ẹgbẹ́, ilé ìkẹ́rùsí tí a ti pa tì, orí pápá tó ṣófo—ibikíbi tí àwọn ènìyàn bá ti lè kóra jọ sí ní gbogbo òru láti gbádùn ijó amẹ́mìígbóná, láìdáwọ́dúró. Nínú ìwé ìròyìn Sunday Times Magazine ti Johannesburg, Gúúsù Áfíríkà, Adam Levin kọ̀wé pé: “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ijó rave ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbapò lọ́wọ́ òde àríyá ilé ìgbafàájì alaalẹ́ gẹ́gẹ́ bí eré ìtura tí àwọn èwe ń yàn láàyò.” Ó fi kún un pé: “Bí àwọn ọmọ rẹ ọ̀dọ́langba kò bá ì sọ nǹkan kan nípa rẹ̀, a jẹ́ pé o kì í bá wọn fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀ ni.”

Àyẹ̀wò Ìran Ijó Rave

Ijó rave máa ń jẹ́ àṣírí lọ́pọ̀ ìgbà, tí a kì í sọ ibi tí a óò ti jó o ṣáájú ọjọ́ ijó náà. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí àwọn iná aláràbarà alágbèéká náà bá tàn, tí orin techno alùkìkì náà sì bẹ̀rẹ̀, àwọn èwe láti iye púpọ̀ díẹ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn, nínú ìmúra àrà ọ̀tọ̀ lè ti wà níbẹ̀. Katy, akẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún kejì ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, sọ pé: “Ńṣe ló ń dà bí ìdìpọ̀ ńlá àwọn ènìyàn tó ṣọ̀kan, tí wọ́n ń jó yí ká, tí wọ́n sì ń tú ìrunú ọkàn wọn jáde lọ́nà tó bá ìlù náà mu.

Bí ó ti wù kí ó rí, ijó rave kì í ṣe ijó kan lásán. Ó tún jẹ́ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, tàbí “ìran àfihàn” kan, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀dọ́ tí ń lọ síbẹ̀ ṣe kúndùn láti máa pè é. Ìgbàgbọ́ gbogbogbòò ni pé àwọn ìlànà ìpìlẹ̀ ijó rave jẹ́ àlàáfíà, ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ọ̀wọ̀—láìka ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, tàbí èrò nípa ìbálòpọ̀ sí. Ẹnì kan tí ó ni ilé ìtajà kan tí ń ta àwọn orin ijó sọ pé: “A ti ń gbìyànjú láti da àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ pọ̀ ní àwọn ibi ijó wọ̀nyí.” Ó fi kún un pé: “Èrò náà jẹ́ ti wíwà pa pọ̀, jíjó pa pọ̀ sì jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan láti ṣàṣeyọrí ìyẹn.”

Lójú àwọn èrò tó jọ pé ó wúni lórí bẹ́ẹ̀, o lè béèrè pé, ‘Kí ló lè ṣàìtọ́ nípa ijó rave?’ Ṣùgbọ́n ó tún ku apá kan nínú ìran ijó rave tí ó yẹ kí o ronú lé.

Apá Tó Ríni Lára Nínú Ijó Rave

Àwọn kan sọ pé a kì í mu ọtí líle níbi ijó rave. Bí ó ti wù kí ó rí, oògùn líle wọ́pọ̀. Brian tó máa ń lọ síbi ijó rave sọ pé: “Ẹnì kan ń ṣe kàyéfì bóyá àwọn ìran àfihàn rave kò ti ní ṣètẹ́wọ́gbà fún gbogbogbòò, ká ní kò sí oògùn líle púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ níbẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ènìyàn míràn ń ṣe kàyéfì lórí bóyá ohun kan ì bá wà tí ì bá máa jẹ́ ijó rave láìsí wọn.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé marijuana àti oògùn líle LSD ti gbajúmọ̀ ní àwọn ibi ijó rave kan, oògùn líle tí ó jọ pé àwọn oníjó rave yàn láàyò jù lọ ni oògùn líle MDMA, tí a mọ̀ sí Ecstasy ní gbogbogbòò. Ìjẹ́wọ́ náà ni pé oògùn líle Ecstasy kò léwu púpọ̀. Wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé ó wulẹ̀ ń fún wọn lókun láti fi gbogbo òru jó, ó sì ń mú kí ìmọ̀lára ayọ̀ wọn túbọ̀ lágbára sí i. Síbẹ̀, lábẹ́ àkọlé náà, “Oògùn Tó Gbajúmọ̀ Lè Ba Ọpọlọ Jẹ́,” ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, oògùn líle Ecstasy “lè nípa líléwu, onígbà pípẹ́ lórí àṣà ìjẹun, oorun, ìmọ̀lára, ìhùwà láìṣàtúnrò àti àwọn ìṣiṣẹ́ ọpọlọ mìíràn.” Kò sì mọ síbẹ̀. Dókítà Howard McKinney sọ pé: “Oògùn líle Ecstasy ti pa àwọn ènìyàn kan, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tó sì lo ìwọ̀n yíyẹ rẹ̀ ti nírìírí àìlùkìkì ọkàn àyà, àìṣiṣẹ́mọ́ ẹ̀dọ̀ki tàbí dídákú.” Dókítà Sylvain de Miranda ní ìdí rere láti sọ pé: “Ikú ni àwọn tí ń lọ síbi ijó rave, tí wọ́n ń lo oògùn líle Ecstasy, ń bá jó.”

Kódà, àwọn oògùn líle elégbòogi—bíi Herbal Acid, Acceleration, Ecstasy elégbòogi, tàbí Rush—lè jẹ́ eléwu. Bí àpẹẹrẹ, a ti gbọ́ pé lábẹ́ àwọn ipò kan, oògùn líle Acceleration elégbòogi lè ṣokùnfà ìkọlù àrùn ọkàn àyà àti ikú pàápàá.

Ní ti àwọn tí wọ́n ṣì fi ìtẹnumọ́ gbà pé àwọn oògùn líle tí wọ́n ń lò níbi ijó rave kò léwu, kókó mìíràn tún wà láti ronú lé. Ian Briggs, ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ará Kánádà, sọ pé ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn oògùn líle tí wọ́n ń tà pé ó jẹ́ oògùn líle Ecstasy kì í ṣe oògùn líle Ecstasy rárá. Ó wí pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ló jẹ́ oògùn líle PCP tàbí àwọn oògùn líle mìíràn. Aláìnílànà ni àwọn tí ń ta àwọn oògùn líle wọ̀nyí. Wọn kì í sí níbẹ̀ nígbà tí àwọn oògùn líle náà bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.”a

A gbà pé àwọn ijó rave kan lè máà ní ìlò oògùn líle nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ń lọ síbi ijó rave yóò gbà pé kò ṣeé ṣe lọ́pọ̀ ìgbà láti sọ tẹ́lẹ̀ bóyá èyíkéyìí, ọ̀pọ̀, tàbí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà níbi ijó rave yóò lo àwọn ohun tí kò bófin mu.

Ijó Rave Ha Wà fún Ọ ní Gidi Bí?

Kò sí ohun kan tí ó burú lọ́nà àdánidá nínú orin àti ijó, kì í sì í ṣe ohun tí kò yẹ láti gba fàájì. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé “àkókò fún ayọ̀” àti “àkókò fún ijó” wà. (Oníwàásù 3:4, Today’s English Version) Ó tún ṣíni létí pé: “Máa yọ̀ . . . nígbà èwe rẹ.” (Oníwàásù 11:9) Nítorí náà, Ẹlẹ́dàá fẹ́ kí o láyọ̀! Síbẹ̀síbẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa rántí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. (Jòhánù Kíní 5:19) Nípa bẹ́ẹ̀, kò gbọ́dọ̀ yani lẹ́nu pé onírúurú eré ìtura tí ayé yìí ń gbé lárugẹ sábà máa ń ní àwọn ohun tí kò gbámúṣé nínú.

Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn tí ń lọ síbi ijó rave. Wọ́n ha ń tẹ̀ lé ìṣílétí inú Bíbélì láti ‘wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí’ bí? (Kọ́ríńtì Kejì 7:1) Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn tí ń lọ síbi ijó rave máa ṣètìlẹ́yìn fún àlàáfíà, ìfẹ́, àti ìṣọ̀kan. Ṣùgbọ́n “ọgbọ́n tí ó sọ̀ kalẹ̀ wá láti òkè” ṣe ju pé ó “lẹ́mìí àlàáfíà” lọ; ó tún “mọ́ níwà.” (Jákọ́bù 3:15, 17) Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ìwà àwọn ti wọ́n sábà máa ń lọ síbi ijó rave ha bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, mu bí? Mo ha fẹ́ láti lo gbogbo òru pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run”?’—Tímótì Kejì 3:4; Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10; fi wé Aísáyà 5:11, 12.

Àwọn ìbéèrè pàtàkì láti ronú lé nìwọ̀nyí, nítorí pé Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “àwọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba àwọn àṣà ìhùwà wíwúlò jẹ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 15:33) Láti máa bá àwọn ènìyàn tí kò ka àwọn òfin Ọlọ́run sí kẹ́gbẹ́ yóò yọrí sí ìjábá níkẹyìn, nítorí pé Bíbélì wí pé: “Ẹni tí ó ń bá ọlọgbọ́n rìn yóò gbọ́n; ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ àwọn aṣiwèrè ni yóò ṣègbé.”—Òwe 13:20.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ ijó rave kò yàtọ̀ sí agbo oògùn líle, àwọn tó sì ń lọ síbẹ̀ lè rí àbájáde búburú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́pàá ló máa ń lọ kó àwọn ènìyàn lọ́pọ̀ ibi ijó rave, tí wọ́n sì ń fòpin sí ijó náà, bóyá nítorí pé wọ́n ń ṣètò ijó náà láìbófinmu tàbí nítorí àwọn oògùn líle tó wà níbẹ̀. Ìwọ yóò ha fẹ́ kí a kà ọ́ mọ́ àwọn tí kì í pa òfin mọ́ bí? (Róòmù 13:1, 2) Ká tilẹ̀ wá ní kò sí ọ̀ràn òfin rírú níbẹ̀, o ha lè wà níbi irú òde àríyá bẹ́ẹ̀, kí o sì wà ‘láìní èérí nínú ayé’ síbẹ̀? (Jákọ́bù 1:27) Níwọ̀n bí a ti dẹ́bi fún àríyá aláriwo, tàbí “àríyá oníwà ẹhànnà” (Byington), nínú Bíbélì, wíwà tí o bá wà níbi ijó rave kan ha lè mú kí o di ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gaara mú níwájú Ọlọ́run àti ènìyàn bí?—Gálátíà 5:21; Kọ́ríńtì Kejì 4:1, 2; Tímótì Kíní 1:18, 19.

Ní kedere, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ewu ijó rave. Ṣùgbọ́n má sọ̀rètí nù. Ọ̀pọ̀ eré ìtura tí o lè gbádùn ṣì wà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìdílé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣètò àwọn ìkórajọ gbígbámúṣé.b Pẹ̀lú ìwéwèé àti àbójútó tí a baralẹ̀ ṣe, gbogbo àwọn to lọ sí ibi wọ̀nyí máa ń kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀lára ìtura ti ẹ̀mí àti ti ara. Ní pàtàkì jù, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ń gbéni ró ń mú inú Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” tí ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ máa yọ̀, dùn.—Tímótì Kíní 1:11; Oníwàásù 8:15.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Oògùn líle PCP (phencyclidine) jẹ́ oògùn apàmọ̀lára kan tí a máa ń lò láìbófinmu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti ṣokùnfà ìfọkànyàwòrán tó ṣe kedere nínú ọpọlọ.

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1992, ojú ìwé 15 sí 20, àti Jí!, May 22, 1997, ojú ìwé 8 sí 10.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

Kí Ni Orin Techno?

Ní ṣókí, orin techno tọ́ka sí orin oníjó orí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́. Oríṣiríṣi ló ní nínú. Àwọn kan yóò júwe orin techno bí orin oníwọ̀n, nítorí pé ó sábà máa ń ní ìwọ̀n ìró tó wà láàárín 115 sí 160 láàárín ìṣẹ́jú kan.

Ìwé agbéròyìnjáde The European sọ pé: “Létí àwọn ọ̀gbẹ̀rì, orin techno ń dún bí ìró tí o máa ń gbọ́ nígbà tí olùtọ́jú eyín bá ń ṣètọ́jú eyín rẹ, pa pọ̀ mọ́ ìró tí o lè wòye pé a ń gbọ́ lóru ọjọ́ tí a pa Sódómù òun Gòmórà run.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìró ohùn orin techno tí ń dún déédéé ń wọ àwọn olùgbọ́ kan lọ́kàn. Christine, ọmọ ọdún 18, sọ pé: “Ní tèmi, orin yìí ń fúnni ní ìmọ̀lára òmìnira tí kò láàlà àti àìgbára-lẹ́nikẹ́ni.” Sonja ní irú ìmọ̀lára kan náà. Ó wí pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, n kò fẹ́ràn orin techno rárá. Ṣùgbọ́n bí o bá ti ń tẹ́tí sí i tó ni yóò máa wù ọ́ tó. Bí o bá yí i sókè dáadáa, yóò ṣòro fún ọ láti ṣàìfiyèsí ìró rẹ̀ tí ń lù kìkì. O máa bẹ̀rẹ̀ sí í mira láìròtẹ́lẹ̀. Bí o kò bá ṣọ́ra, ìró náà ni yóò máa darí gbogbo ara rẹ.” Shirley, ọmọ ọdún 19, rí ohun kan tó jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú orin techno. Ó wí pé: “Èyí ju orin lásán kan lọ. Ọ̀nà ìgbésí ayé kan pọ́nńbélé tí a ń fi hàn nínú ìwọṣọ àti èdè ni.”

Ìfẹ́ ọkàn àwọn Kristẹni ni láti “máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.” (Éfésù 5:10) Nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra nípa orin techno bí wọn yóò ṣe lò ó nípa oríṣi orin èyíkéyìí mìíràn. Bí o bá rí i pé orin techno ń fà ọ́ mọ́ra, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Báwo ni irú orin yìí ṣe ń nípa lórí mi? Ó ha ń mú mi láyọ̀, kí ó fi mí lọ́kàn balẹ̀, kí ó sì mú mi lálàáfíà bí? Tàbí ó ń dà mí lọ́kàn rú, bóyá tí ó ń mú mi ronú nípa ìbínú tàbí ìṣekúṣe bí? Fífà tí mo bá fà mọ́ irú orin yìí yóò ha mú mi fà mọ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tó rọ̀ mọ́ ọn bí? A óò ha dẹ mí wò láti lọ síbi ijó rave kan kí n lè gbọ́ irú orin yìí, tàbí kí n lè jó o bí?’

Ní gidi, kókó pàtàkì ibẹ̀ ni pé: Irú orin tó wù kí o yàn láàyò, má ṣe jẹ́ kí ó jẹ́ ìdènà láàárín ìwọ àti Bàbá rẹ ọ̀run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́