Ojú ìwé 2
Ìháragàgà Fún Ìsọfúnni Báwo Ló Ṣe Kàn Ọ́? 3-12
Ìsọfúnni ń ya lù wá lójoojúmọ́—nípasẹ̀ tẹlifíṣọ̀n, ìsokọ́ra alátagbà Internet, ìwé agbéròyìnjáde, rédíò, ìwé ìròyìn, ẹrù ìwé tí a kò fúnra ẹni béèrè fún. Àwọn tó wà lọ́wọ́ ti pọ̀ jù. Bí wọ́n ti pọ̀ tó ń fa ìdàrúdàpọ̀. Kí ni o lè ṣe nípa rẹ̀?
Bí Àwọn Ará Inca Ṣe Pàdánù Ilẹ̀ Ọba Wọn Oníwúrà 13
Àgbàyanu ọ̀làjú kan wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà nígbà tí àwọn ajagunṣẹ́gun ará Sípéènì fi débẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1532. Báwo ló ṣe fọ́ yángá?
Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Kan Ṣàtúnṣe Àìtọ́ Kan 19
Àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fojú winá àìsí ìdájọ́ òdodo púpọ̀ jù. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀.