Ìrètí Ọmọbìnrin Ará Rọ́ṣíà Kan
ỌMỌBÌNRIN ọlọ́dún 15 kan ní Ukhta, Rọ́ṣíà, ìlú ńlá tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ lé ní 100,000, tó jìn ju 1,200 kìlómítà lọ sí ìhà ìlà oòrùn àríwá Moscow, fí ìdàníyàn àtọkànwá hàn fún ipò sísànjù lórí ilẹ̀ ayé. Ó ṣàlàyé èyí ninú lẹ́tà yí tí ó kọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pé:
“Ọ̀rẹ́ mi sọ fún mi pé ìwé náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, ṣàpèjúwe ìgbésí ayé Jésù Kristi. Mo ní ọkàn ìfẹ́ sí àwọn ìwé yín, àwọn ìwé ìròyìn yín, àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ yín. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ní ọkàn ìfẹ́ yìí. Ó bẹ̀rẹ̀ nílé iṣẹ́ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ nígbà tí mo lọ san owó ìlò rédíò àti tẹlifóònù. Mo rí ìwé ìléwọ́ kan nílẹ̀ níbẹ̀. Mo mú un, mo gbọn ìdọ̀tí ara rẹ̀ nù, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé ìléwọ́ náà tí ó ní àkọlé náà, Why Is Life So Full of Problems?
“Mo kà nípa àwọn wàhálà àti ìjìyà tí ń dojú kọ àwọn ènìyàn, àwòrán ẹ̀yìn ìwé ìléwọ́ náà sì ṣàpèjúwe ìgbésí ayé tuntun kan tí a ṣèlérí nínú Párádísè. Mo ń retí pé yóò dé lọ́jọ́ kan. Ní gidi, mo fẹ́ láti rí i kí gbogbo ènìyàn láyọ̀, kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn, kí wọ́n sì ní ìlera, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ láti tún rí àwọn ìbátan tí wọ́n ti kú. . . . Èmi yóò fẹ́ láti mọ ohun tí mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè ní ìrètí láti wà láàyè nínú Párádísè ilẹ̀ ayé náà. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ fi ìsọfúnni tàbí àwọn ìwé ránṣẹ́ sí mi. N óò san owó wọn àti owó ìfiwọ́nránṣẹ́.”
Ìwọ pẹ̀lú lè rí àwọn ìwé tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jèrè ìrètí fífẹsẹ̀múlẹ̀ tí a gbé karí Bíbélì nípa ìwàláàyè nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, gbà tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti bá ọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.