Ojú ìwé 2
Ayé Kan Tí Kò Ti Ní Sí Ìwà Ọ̀daràn—Ìgbà Wo Ni? 3-9
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lónìí ni ó dá lójú pé ó ṣeé ṣe kí ayé kan tí ìwà ọ̀daràn kò ní sí dé. Báwo ni o ṣe lè wà láàyè láti fojú rẹ rí i?
Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́ 12
Bàbá ọ̀dọ́mọdé Horst àti arábìnrin rẹ̀ kú sí ẹ̀wọ̀n ní ilẹ̀ Germany nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Báwo ló ṣe nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀?
Àwọn Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Yin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà 18
Ka ohun tí ìròyìn inú àwọn ìwé agbéròyìnjáde sọ nípa ìyàsímímọ́ àwọn ilé lílò ti ẹ̀ka Rọ́ṣíà ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tó kọjá.