Àwọn Aṣàbójútó Ilé Iná Atọ́nà Ọkọ̀ Òkun—Iṣẹ́ Kan Tí Ń Kásẹ̀ Nílẹ̀
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ
LÉRALÉRA ni àwọn aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun ti sọ pé: “Kò sí iṣẹ́ mìíràn tí mo tún fẹ́ ṣe.” Ọkùnrin kan tí ó fi ipò alábòójútó tí ó wà ní ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe ike ní Toronto, Kánádà, sílẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun kan tí ó ti wà fún ọdún 106 sọ pé, iṣẹ́ náà mú kí òun nímọ̀lára bíi pé “ọjọ́ orí òun fi ọdún 10 dín sí i.”
Lájorí iṣẹ́ aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun jẹ́ láti rí pé iná tí ó tàn rekete wà fún àwọn atukọ̀ òkun. A tún béèrè pé kí ó máa fun àwọn fèrè aṣèkìlọ̀ tí a ń lò nígbà tí kùrukùru bá wà, kí ó sì máa ṣàtúnṣe wọn, kí ó sì máa fi rédíò ìbánisọ̀rọ̀ pèsè ìsọfúnni nípa ipò ojú ọjọ́ fún àwọn apẹja àti àwọn ọkọ̀ òkun tí ń kọjá.
Nígbà kan rí, àwọn aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun ní láti rí i sí i pé epo ń wà nínú àgbá epo, kí àtùpà wà ní títàn, kí èéfín má sì dọ̀tí ìgò àtùpà náà. Ó wọ́pọ̀ kí àwọn aṣàbójútó fi ọwọ́ yí iná aṣèkìlọ̀ káàkiri ní gbogbo òru láti ṣamọ̀nà àwọn ọkọ̀ òkun láìséwu nígbà tí àwọn iná atọ́nà kò bá ṣeé tètè tún ṣe tàbí kí wọ́n fi òòlù lu agogo aṣèkìlọ̀ tí a ń lò nígbà tí kùrukùru bá wà ní gbogbo òru nígbà tí fèrè aṣèkìlọ̀ tí a ń lò nígbà tí kùrukùru bá wà kò bá ṣiṣẹ́!
Líla Ìjì Òkun Náà Já
Àwọn ìjì lílekoko jẹ́ lájorí àníyàn kan. Ní ìgbà kan, ẹnì kan tí ń bójú tó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun rí ohun tí ó gbà gbọ́ pé ó jẹ́ “kùrukùru funfun kíkàmàmà” kan, àmọ́ tí ó wá jẹ́ ìgbì omi lílágbára kan ṣoṣo! Ìgbì omi náà ga tó òkè onímítà 15.2, ó sì ga tó ibùgbé aṣàbójútó náà. Ìgbì omi yìí ṣèbàjẹ́ tí ó pọ̀ tó èyí tí ìjì ńlá ń ṣe.
Ní ìgbà mìíràn, ní gbogbo òru, ìjì atẹ́gùn líle kan rọ́ omi lu ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun tó wà ní Èbúté Pubnico, Nova Scotia. Ńṣe ni aṣàbójútó náà àti ìdílé rẹ̀ dúró, wọ́n sì ń retí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Nígbà tí ó fi máa di òwúrọ̀, ìjì náà ti dẹwọ́. Àmọ́ nígbà tí aṣàbójútó náà jáde síta, ó yà á lẹ́nu láti rí i pé ilẹ̀ ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun náà ti pòórá. Ilé náà ti dá wà láàárín omi!
Ìnìkanwà àti Àṣetúnṣe Iṣẹ́ Kan Náà
Nígbà tí a bi aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun kan léèrè nípa ìnìkanwà, ó rẹ́rìn-ín sínú, ó sì wí pé: “Àwọn ènìyàn ń sọ fún wa pé, ‘Ẹ gbọ́ ná, báwo ni ẹ ṣe lè fara dà ìnìkanwà náà?’ A óò sì fèsì ní bíbéèrè pé, ‘Ẹ dúró ná, báwo ni ẹ̀yin ṣe ń fara da gbígbé àárín ìlú ńlá pẹ̀lú gbogbo ariwo àti pákáǹleke yẹn?’”
Ní àwọn ìgbà tó ti kọjá, a ṣe àkójọ àwọn ìwé kéékèèké lárọ̀ọ́wọ́tó sí àwọn ibùdó atọ́nà ọkọ̀ òkun tí ó wà ní ibi àdádó jíjìnnà gan-an ní United States. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó fi di ọdún 1885, a ti ní àwọn ibi-ìkówèésí 420. Dájúdájú, àwọn aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun wá di ẹni tí ó máa ń kàwé dáadáa.
Iṣẹ́ Àkọ́mọ̀ọ́ṣe Tí Ń Kásẹ̀ Nílẹ̀
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti fi àwọn ilé gogoro tí a fi irin kọ́, tí ó ní àwọn iná alágbára tí ń bù yẹ̀rì, tí ènìyàn kì í bójú tó rọ́pò àwọn ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun tí a mọ, tí ènìyàn ń bójú tó. Àwọn awakọ̀ òkun kì í tún fojú wá iná aṣèkìlọ̀ tí ń ṣe bàìbàì tàbí ọwọ́ iná tí kùrukùru kò jẹ́ kí ó mọ́lẹ̀ dáradára. Lónìí, àwọn iná tungsten halogen alágbára àti fèrè aṣèkìlọ̀ tí a ń lò nígbà tí kùrukùru bá wà, tí ń dún ketekete, tí a ń gbọ́ níbi gbogbo ń ta awakọ̀ òkun lólobó nípa ewu ojú òkun.
Àwọn ọkọ̀ òkun tí a ṣètò ìgbékalẹ̀ tí ń gba àwọn àmì ìkìlọ̀ láti àwọn ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun sí nínú ti ń mọ ibi tí wọ́n bá wà bí ó ti wù kí kùrukùru ṣe dí tó. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ń jẹ́ kí arìnrìn-àjò ojú òkun lè gba ojú òkun láti èbúté kan dé òmíràn, kí ó sì ní ìdánilójú pé òun lè yẹra fún àwọn òkìtì yanrìn, àpáta líléwu lábẹ́ omi, àti àwọn àpáta líléwu ní etíkun.
Gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní, àwọn aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun ti ń yára kógbá sílé. Aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun kan tí ó lérò pé tòun ti tán pátápátá rántí tìbànújẹ́tìbànújẹ́ nígbà tí ó ń fi erékùṣù tí ó ti jẹ́ ilé rẹ̀ fún ọdún 25 sílẹ̀ pé: “A gbádùn ayé wa níhìn-ín. A kò fẹ́ láti fi ibí sílẹ̀ rárá.”
Síbẹ̀, àwọn iná ayíbírí, àwọn iná kéékèèké, iná pàjáwìrì, àwọn ìró aṣèkìlọ̀, àti àwọn iná aṣèkìlọ̀ nílò àtúnṣe, àwọn ibùdó atọ́nà ọkọ̀ òkun sì nílò ìtọ́jú. Àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń rìnrìn àjò ni wọ́n máa ń tún àwọn ilé gogoro oníná atọ́nà ọkọ̀ òkun ṣe báyìí.
Àwọn tí wọ́n mọyì ọ̀pọ̀ ọdún tí àwọn aṣàbójútó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun fi ṣiṣẹ́ ṣàjọpín èrò ọkùnrin kan ní Augusta, Maine, tí ó kédàárò pé: “Dájúdájú, kò lè rí bákan náà mọ́, tí o bá wo ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun, tí o sì mọ̀ pé kọ̀ǹpútà ló ń tan àwọn iná náà, tí o mọ̀ pé kò sí àwọn ènìyàn níbẹ̀.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Ilé Iná Atọ́nà Ọkọ̀ Òkun Àkọ́kọ́
Wọ́n parí kíkọ́ ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun àkọ́kọ́ tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú ìtàn nígbà ìṣàkósò Ptolemy Kejì ti Íjíbítì. Nǹkan bí ọdún 300 ṣááju Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ́ ọ, ó sì wà ní Erékùṣù Pharos, lẹ́bàá àbáwọlé ibi tí a ń pè ní èbúté ti Alẹkisáńdíríà nísinsìnyí. Ó gba 20 ọdún tí wọ́n fi kọ́ ọ ní iye tí ó jẹ́ 2.5 mílíọ̀nù dọ́là.
Àwọn àkọsílẹ̀ ìwé ìtàn fi hàn pé ó ga ju 90 mítà lọ. Iyàrá òkè rẹ̀ ní àwọn fèrèsé tí ó dojú kọ agbami òkun, tí àwọn iná tí a fi igi tàbí bóyá àwọn ògùṣọ̀, tí Josephus sọ pé a lè rí láti ibi tí ó jìnnà ju 50 kìlómítà lọ, dá, ń jó lẹ́yìn rẹ̀.
A ka ilé olókùúta títóbi náà sí ọ̀kan lára àwọn Ohun Ìyanu Méje Tí Ó Wà ní Ayé. Iná rẹ̀ tí ń jó wòwò ṣiṣẹ́ bí iná aṣèkìlọ̀ fún 1,600 ọdún, tí ó ṣeé ṣe pé ìsẹ̀lẹ̀ kan ló bà á jẹ́.
Bí ọ̀rúndún ti ń gorí ọ̀rúndún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun ní oríṣiríṣi ìwọ̀n ìtóbi àti ìrísí ni a kọ́ sí àwọn ibùdókọ̀ jákèjádò ayé. Àwọn ògbólógbòó ilé iná atọ́nà ọkọ̀ òkun tí a mọ̀ ń wà nìṣó lónìí bí ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí àti ibi tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ nífẹ̀ẹ́ sí ní àwọn ọgbà ìtura àpapọ̀ orílẹ̀-èdè, ìpínlẹ̀, orílẹ̀-èdè, àti ìlú ńlá, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn sì ń lọ wò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ilé Iná Atọ́nà Ọkọ̀ Òkun ti Cape Spear, Newfoundland, Kánádà