ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/22 ojú ìwé 24
  • Ìpadàṣọ̀kan Aláìlẹ́gbẹ́ Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpadàṣọ̀kan Aláìlẹ́gbẹ́ Kan
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésí Ayé Mi Yí Padà Nígbà Tí Mo Mọ Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ohun Tó Ń fa Ìbànújẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Ìpàdé Tí Ń Runi Sókè sí Ìfẹ́ àti sí Iṣẹ́ Àtàtà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ó Wọ̀ Ọ́ Lọ́kàn
    Jí!—1998
  • Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí “Àwọn Ẹni Mímọ́”?
    Jí!—2011
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/22 ojú ìwé 24

Ìpadàṣọ̀kan Aláìlẹ́gbẹ́ Kan

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ BRITAIN

ỌMỌ ọdún méjì péré ni Bruce nígbà tí Marie, ìyá rẹ̀, rí i kẹ́yìn ní 1945. Lẹ́yìn tí Marie ṣèkọ̀sílẹ̀, bàbá Bruce gba ẹ̀tọ́ àbójútó rẹ̀ lábẹ́ òfin. Ní títẹ ìmọ̀lára rẹ̀ lọ́nà àdánidá rì, Marie pinnu pé yóò ṣe ọmọkùnrin òun láǹfààní jù bí bàbá rẹ̀ àti ìyàwó tuntun tí bàbá rẹ̀ fẹ́ bá tọ́ ọ dàgbà láìsí fàákájáa ti ìmọ̀lára kankan láti ọ̀dọ̀ òun. Ní àbárèbábọ̀, òun àti Bruce kò kàn sí ara wọn rárá.

Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Marie lọ́kọ mìíràn, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn, ṣùgbọ́n ó ṣì ń ronú nípa Bruce. Ibo ló wà? Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sí i?

Nígbà tí bàbá Bruce kú ní 1976, Marie lọ síbi ìsìnkú rẹ̀. Bruce, ọ̀dọ́kùnrin rírẹwà kan tó ti lé lọ́mọ 30 ọdún nígbà náà, àti ìyàwó tuntun tí bàbá rẹ̀ fẹ́, wà níbẹ̀. Nítorí pé Marie ṣì gbà gbọ́ pé Bruce lérò pé ìyàwó bàbá rẹ̀ náà ló bí i, ó rò pé kò ní jẹ́ ìwà inú rere láti jẹ́ kí ó mọ òun ní irú àkókò yẹn. Marie ì bá ti ṣe ohun tó yàtọ̀ ká ní ó mọ̀ pé bàbá Bruce ti kọ̀ ọ́ ní kété tó ti tún gbéyàwó, tó sì jẹ́ pé ìyá bàbá rẹ̀ ló tọ́ ọ dàgbà.

Ní nǹkan bí àkókò yìí ni Marie bá Sue, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pàdé, tí ó sì gbà láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé. Ó ṣe kòńgẹ́ pé nígbà kan náà ni Alan, ọkọ Sue, bẹ̀rẹ̀ sí í bá Bruce àti ìyàwó rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí àìlera, Marie dá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dúró, ó sì kó lọ.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún kàn sí Marie ní 1995. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì yára tẹ̀ síwájú. Bí ó ti ń sún mọ́ ìgbà tí yóò ṣe ìrìbọmi, Marie finú han Kristẹni alàgbà kan nípa Bruce. Alàgbà náà ṣe ìwádìí, ó sì rí i pé, ní àfikún sí pé Bruce àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Bruce tún jẹ́ alàgbà kan ní ìlú ìbílẹ̀ ti Marie gan-an!

Ó kó ojora bá àwọn alàgbà tó kù nínú ìjọ tí Bruce wà. Bí wọ́n bá sọ fún Bruce pé ìyá rẹ̀ yóò ṣèrìbọmi ní ọjọ́ àpéjọ àkànṣe tí ń bọ̀, báwo ni yóò ṣe hùwà padà? Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ mọ̀ pé ìyá náà wà tẹ́lẹ̀? Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbàrà tí Bruce mọ̀ nípa ọ̀ràn náà, òun àti ìdílé rẹ̀ yára lọ pàdé Marie. Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Bruce sọ bí ó ti ń gbá ìyá rẹ̀ mọ́ra ni pé: “Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn kò já mọ́ nǹkan; ọjọ́ iwájú ló ṣe pàtàkì nínú òtítọ́!”

Ní March 1996, Marie, tó jẹ́ ọmọ ọdún 78 nígbà náà ṣèrìbọmi ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní East Pennine, England—Bruce ló rì í bọmi. Ẹ wo bí Bruce ti láyọ̀ tó láti jèrè ìyá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arábìnrin tẹ̀mí kan!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Bruce, àti ìyá rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́