Àgbàyanu Igi Dóńgóyárò
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ
“ILÉ egbòogi abúlé”—ohun tí àwọn ènìyàn ń pe igi dóńgóyárò ní Íńdíà nìyẹn. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn ènìyàn tí ń gbé orílẹ̀-èdè yẹn ti ń lo igi dóńgóyárò láti ṣèwòsàn ìrora, ibà, àti àwọn àrùn àkóràn. Nítorí pé ọ̀pọ̀ Híńdù gbà gbọ́ pé igi dóńgóyárò lè fọ ẹ̀jẹ̀ àwọn mọ́, wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ ọdún kọ̀ọ̀kan nípa jíjẹ ewé dóńgóyárò mélòó kan. Àwọn ènìyàn tún ń fi ẹ̀ka igi dóńgóyárò ṣe pákò, tí wọ́n fi ń fọ eyín wọn, wọ́n ń fún oje ewé dóńgóyárò sí àwọn àrùn awọ ara, wọ́n sì ń fi dóńgóyárò ṣe tíì tí wọ́n ń mu gẹ́gẹ́ bíi tọ́níìkì.
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń fi ọkàn ìfẹ́ púpọ̀ sí i hàn nínú igi dóńgóyárò. Bí ó ti wù kí ó rí, ìròyìn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tí wọ́n pè ní Neem—A Tree for Solving Global Problems kìlọ̀ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe fẹ́rẹ̀ẹ́ máà lópin, kò sí ohun tí ó dájú ṣáká nípa igi dóńgóyárò. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n nítara ọkàn jù lọ nípa igi náà àti ìwúlò rẹ̀ gbà pé àwọn ẹ̀rí tó wà níbi tí a dé yìí láti fi ti ìfojúsọ́nà wọn lẹ́yìn kò ì dáni lójú.” Síbẹ̀síbẹ̀, ìròyìn náà tún sọ pé: “Ìwádìí tí a fi ẹ̀wádún méjì ṣe ti fi àbájáde tó fọkàn balẹ̀ hàn ní oríṣiríṣi ọ̀nà pé irú ọ̀wọ́ tí a kò mọ̀ dáradára yìí lè ṣàǹfààní púpọ̀púpọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ àti èyí tí ó lọ́rọ̀. Kódà, àwọn kan nínú àwọn olùwádìí tó ní ìṣọ́ra jù lọ ń sọ pé, ‘igi dóńgóyárò tó pè ní àràmàǹdà igi.’”
Ipa Tó Ń Kó Gẹ́gẹ́ Bí Igi
Igi dóńgóyárò, tí a máa ń rí ní àwọn àgbègbè ilẹ̀ olóoru, jẹ́ mẹ́ńbà ọ̀wọ́ igi ọ̀ganwó. Ó máa ń ga tó 30 mítà, ìwọ̀n òbírípo rẹ̀ sì lè lé ní mítà 2.5. Níwọ̀n bí kò ti wọ́pọ̀ pé kí ewé rẹ̀ tán lórí rẹ̀, ó máa ń ní ìji jálẹ̀jálẹ̀ ọdún. Ó ń yára dàgbà, kò béèrè àbójútó púpọ̀, ó sì ń gbilẹ̀ dáadáa nínú ilẹ̀ tí kò lọ́ràá.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí ni wọ́n mú un wọ Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà láti pèsè ìji, kí ó sì dáwọ́ bí Aṣálẹ̀ Sàhárà ṣe ń gbòòrò lọ sí ìhà gúúsù dúró. Àwọn aṣọ́gbó tún ti gbin igi náà ní Fiji, Mauritius, Saudi Arabia, Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà àti Gúúsù Amẹ́ríkà, àti àwọn erékùṣù Caribbean. Ní United States, àwọn ilẹ̀ ọ̀gbìn àfidánrawò wà ní àwọn àgbègbè ìhà gúúsù ti Arizona, California, àti Florida.
Láfikún sí pé ó ń pèsè ìji jálẹ̀jálẹ̀ ọdún ní àwọn ibi tí ipò ojú ọjọ́ ń móoru, a tún lè fi igi dóńgóyárò dáná. Síwájú sí i, igi rẹ̀ tí ikán kò lè mu wúlò gan-an láti fi kọ́lé àti láti fi gbẹ́ ọnà. Nítorí náà, bí a bá gbé e karí ìwúlò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi kan nìkan, igi dóńgóyárò wúlò púpọ̀. Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rẹ̀ lásán nìyẹn.
Àwọn Kòkòrò Kórìíra Rẹ̀
Nítorí pé àwọn ará Íńdíà ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé ewé igi dóńgóyárò ń lé àwọn kòkòrò tí ń yọni lẹ́nu sá, wọ́n máa ń fi ewé rẹ̀ sínú bẹ́ẹ̀dì, ìwé, àpótí ìkóǹkansí, kọ́bọ́ọ̀dù, àti iyàrá ìkéèlòsí. Ní 1959, onímọ̀ nípa kòkòrò kan tó jẹ́ ará Germany, àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, dáwọ́ lé ìwádìí nípa igi dóńgóyárò lẹ́yìn tí wọ́n rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ eṣú tó ṣèyọnu nílẹ̀ Sudan láàárín àkókò tí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù eṣú jẹ ewé gbogbo igi láìfẹnukan ewé igi dóńgóyárò.
Láti ìgbà náà wá, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ̀ pé ìtòpelemọ kẹ́míkà dídíjú ti igi dóńgóyárò gbéṣẹ́ lòdì sí iye tó lé ní 200 irú ọ̀wọ́ kòkòrò títí kan onírúurú kòkòrò mite, nematodes, fungi, bakitéríà, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ fáírọ́ọ̀sì pàápàá. Nínú ìfidánrawò kan, àwọn olùwádìí kó ewé ẹ̀wà sóyà àti kòkòrò iná sínú ohun ìkóǹkansí kan. Wọ́n fún àwọn kẹ́míkà tí wọ́n yọ lára igi dóńgóyárò sára ìdajì ewé kọ̀ọ̀kan. Àwọn kòkòrò iná náà jẹ apá ibi tí wọn kò fún kẹ́míkà náà sí lára ewé náà, ṣùgbọ́n, wọn kò jẹ apá ibi tí kẹ́míkà náà wà. Ní gidi, ebi ló pa wọ́n kú, dípò kí wọ́n fẹnu kan kékeré díẹ̀ lára ewé tó ní kẹ́míkà náà lára.
Irú ìfidánrawò bẹ́ẹ̀ dámọ̀ràn pé ó ṣeé ṣe láti mú ohun tí kò gbówó lórí, tí kò ní májèlé fún ènìyàn, tó sì rọrùn láti ṣe jáde, bí àfirọ́pò àwọn oògùn apakòkòrò àgbélẹ̀rọ. Bí àpẹẹrẹ, ní Nicaragua, àwọn àgbẹ̀ ń po hóró èso dóńgóyárò tí wọ́n ti gún sómi—80 gíráàmù hóró èso náà nínú lítà omi kan. Wọ́n ń rẹ hóró èso náà sómi fún wákàtí 12, wọ́n ń sẹ́ hóró èso náà kúrò nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fún omi náà sára irúgbìn.
Àwọn ohun tí a mú jáde láti ara igi dóńgóyárò kì í pa ọ̀pọ̀ jù lọ kòkòrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Fífún àwọn ohun tí a fi èròjà igi dóńgóyárò ṣe sára kòkòrò ń pa ọ̀nà ìgbésí ayé kòkòrò dà, tó fi jẹ́ pé níkẹyìn, kò ní lè jẹun, tàbí bímọ, tàbí yí pa dà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ohun tí a mú jáde láti ara igi dóńgóyárò ń gbógun ti àwọn kòkòrò, kò jọ pé wọ́n léwu fún àwọn ẹyẹ, àwọn ẹranko ẹlẹ́jẹ̀ lílọ́wọ́ọ́wọ́, tàbí ẹ̀dá ènìyàn.
“Ilé Oògùn Abúlé”
Lẹ́yìn náà, ó tún ń ṣe àwọn àǹfààní mìíràn fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn hóró èso àti ewé rẹ̀ ní àwọn èròjà tó hàn pé wọ́n ń gbógun ti ìdíbàjẹ́, fáírọ́ọ̀sì, àti àwọn fungi. Àwọn àmì kan wà tó tọ́ka sí i pé igi dóńgóyárò lè bá ara wíwú, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti ọgbẹ́ inú jà. A ti gbọ́ pé àwọn egbòogi tí a mú èròjà wọn láti ara igi dóńgóyárò lè bá àrùn àtọ̀gbẹ àti ibà jà. Àwọn àǹfààní mìíràn tí ó ṣeé ṣe kí a rí ni ìwọ̀nyí:
Àwọn egbòogi tí ń lé kòkòrò sá. Èròjà kan tí a fi dóńgóyárò ṣe, tí a ń pè ní salannin, má ń lé àwọn kòkòrò tí ń jẹni sá. Egbòogi kan tí ń lé eṣinṣin àti ẹ̀fọn sá, tí a fi òróró dóńgóyárò ṣe, ti wà lórí àtẹ báyìí.
Ìtọ́jú eyín. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Íńdíà máa ń já ẹ̀ka igi dóńgóyárò láràárọ̀, wọ́n ń jẹ àgógó rẹ̀ kúnná, wọ́n wá ń fi fọ eyín àti erìgì wọn. Ìwádìí ti fi hàn pé èyí ṣàǹfààní, nítorí pé àwọn èròjà inú èèpo rẹ̀ ń gbógun ti ìdíbàjẹ́ gan-an.
Àwọn èròjà ìfètò-sọ́mọ-bíbí. Òróró dóńgóyárò jẹ́ ohun tí ó lágbára tí ń pa àtọ̀, ó sì ti hàn pé ó gbéṣẹ́ láti dín ìbímọ kù nínú àwọn ẹranko tí a fi ń ṣe ìwádìí. Ìdánrawò tí a fi àwọn ọ̀bọ ṣe tún fi hàn pé àwọn èròjà dóńgóyárò tún lè mú kí ó ṣeé ṣe láti ṣe egbòogi oníhóró tí àwọn ọkùnrin lè tẹnu jẹ fún ìfètò-sọ́mọ-bíbí.
Ní kedere, igi dóńgóyárò kì í ṣe igi kan lásán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tí ì mọ gbogbo nǹkan nípa igi dóńgóyárò, ó fúnni ní ìdí láti retí àwọn nǹkan ńláńlá—mímú kíkápá àwọn kòkòrò aṣèbàjẹ́ sunwọ̀n sí i, gbígbé ìlera lárugẹ, ṣíṣèrànwọ́ láti sọ aṣálẹ̀ di igbó, àti, bóyá, kíkápá àpọ̀jù iye ènìyàn. Abájọ tí àwọn ènìyàn fi pe àràmàǹdà igi dóńgóyárò ní “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ìran ènìyàn”!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Igi dóńgóyárò, ewé dóńgóyárò ló wà nínú àwòrán inú àkámọ́