Ìpàtẹ Ọjà Ìsìn Kan
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Ítálì
FEBRUARY 1995 ni òkìkí bẹ̀rẹ̀ sí í kàn nípa ohun tí àwọn ènìyàn rò pé ó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu òde òní kan: Àwọn ènìyàn rò pé àwọn rí ère Madonna ní Civitavecchia bí ó ṣe ń sun ẹ̀jẹ̀. Láti ìgbà náà wá, àwọn Kátólíìkì láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé ti ń rin ìrìn àjò mímọ́ lọ síbẹ̀, láti fojú ara wọn rí ère náà.
Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica ṣe wí, ọ̀pọ̀ Kátólíìkì ni “ipò àyíká ìpàtẹ ọjà” tí ibi ìbẹ̀wò ìrìn àjò afẹ́ náà ní bí nínú. Kódà, ìdààmú bá àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn mélòó kan pàápàá nítorí àwọn àwùjọ ènìyàn tí ń tú yááyáá lọ láti bọ̀wọ̀ oníjọsìn fún ère náà. Bí àpẹẹrẹ, Luigi Pizzolato, olùkọ́ kan ní Yunifásítì Kátólíìkì ti Milan, ṣàríwísí ìjọ náà fún níní ẹ̀mí ìtẹ́lọ́rùn nípa ìgbàgbọ́ “tí ìmọ̀lára ń ru sókè” kan. Ó sọ pé èso tí ohun tí a fi ẹnu lásán pè ní iṣẹ́ ìyanu yìí ń so ni “ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti sọ dìbàjẹ́.” Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn mìíràn, Carlo Molari, rán wa létí pé “nínú Májẹ̀mú Tuntun, ẹnì kan tí ń jẹ́ Símónì Magus lo agbára àrà ọ̀tọ̀ fún ìlépa ara rẹ̀—láti fi pa owó, bí a ó ṣe pè é lónìí.”—Ìṣe 8:9-24.
Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti kíyè sára nítorí àwọn tí yóò fúnni ní “àwọn àmì ńláǹlà àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu.” (Mátíù 24:3, 24) Kódà, nígbà tó bá jọ pé irú àwọn àmì bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ìgbàgbọ́ Kristẹni kan kò ṣeé gbé karí àwọn ohun tí a lérò pé ó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu. (Hébérù 11:1, 6) Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nípa níní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lílo ìmọ̀ràn rẹ̀. (Jòhánù 17:3; Róòmù 10:10, 17; 2 Tímótì 3:16) Ǹjẹ́ o fẹ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀? O kò ṣe jẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá tún kàn sí ọ?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
AGF/La Verde