Ìrànwọ́ Fún Ìgbéyàwó Kan Tó Ń tú Ká Lọ
Obìnrin kan kọ̀wé láti Erékùṣù Àríwá ti New Zealand nípa ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ jókòó láti kẹ́kọ̀ọ́ ìtẹ̀jáde náà, mo lérò pé ìgbéyàwó mi ti dé orí kókó tí mo lè ‘mú kí ó ṣàṣeyọrí tàbí kí n fòpin sí i.’”
Ó ṣàlàyé ìgbésí ayé rẹ̀ àtẹ̀yìnwá. “Ìyá mi ti fojú winá ìgbéyàwó méjì tó kún fún ìfìyàjẹni. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a sábà máa ń kọ́ wa pé àwọn ọkùnrin kò wúlò, gbogbo èrò wọn kò sì kọjá kí wọ́n máa jẹ àwọn obìnrin níyà. Nítorí náà, mo dàgbà di ìpáǹle obìnrin, olóríkunkun kan, tí kì í jáwọ́ lára àríyànjiyàn kankan.”
Obìnrin náà rí i pé ó yẹ kí òun yí padà. “Mo wá mọ̀ pé nítorí pé n kì í tẹrí ba fún ọkọ mi, àti nítorí pé mo ń gbéra ga, mo ń sọ àǹfààní ayọ̀ ìdílé nù.” Nítorí náà, ó ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣàlàyé pé: “Ní báyìí, èmi àti ọkọ mi ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà gẹ́gẹ́ bí ìdílé, mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà ti mo fi lè jẹ́ Kristẹni aya síbẹ̀. Ibi tí a ti dé báyìí ń fún wa láyọ̀, ṣùgbọ́n a ṣì lè tẹ̀ síwájú.
“A kò fìgbà kankan ní ìfẹ́ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tó ti ìsinsìnyí rí nínú ilé wa.”
Bí o bá fẹ́ gba ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ìwé pẹlebẹ olójú ìwé 32 náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, nínú èyí tí ẹ̀kọ́ 8 ti sọ̀rọ̀ nípa “Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí” gbà, kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5. Bí o bá fẹ́ kí ẹnì kan bá ọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ ninú ilé rẹ̀ pẹ̀lú, jọ̀wọ́ mẹ́nu ba ìyẹn.