Oníṣẹ́-Abẹ Àrùn Ọkàn-Àyà Gbóríyìn fún Jí!
Jí!, December 8, 1996, gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde lákànṣe lórí “Ìkọlù Àrùn Ọkàn-Àyà—Kì Ni A Lè Ṣe?” Ọ̀jọ̀gbọ́n Thomas Stegmann, ọ̀kan lára àwọn lóókọlóókọ oníṣẹ́-abẹ ìpààrọ̀ ọkàn-àyà ní Germany, tó tún jẹ́ olórí ẹ̀ka iṣẹ́ abẹ igbá-àyà òun òpójẹ̀ kan, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà, ó sì kọ̀wé sí àwọn òǹṣèwé báyìí pé:
“Tọkàn-ìfẹ́-tọkàn-ìfẹ́ ni mo ka ohun tí ẹ kọ lórí kókó ọ̀rọ̀ àrùn ọkàn-àyà àti, ní pàtàkì, ìkọlù àrùn ọkàn-àyà. Gẹ́gẹ́ bí ògbógi nínú ẹ̀ka yìí, mo rò pé ó pọn dandan pé kí n sọ fún yín pé àlàyé tí ẹ ṣe lórí ìkọlù àrùn ọkàn-àyà àti ìsọfúnni tí ẹ pèsè lórí kókó ọ̀rọ̀ náà dára gan-an—tí ó ń fi òye gidigidi hàn fún alárùn-ọkàn-àyà náà lọ́nà kan, àti, lọ́nà mìíràn, tí ó ń fi àlàyé pípéye nípa àwọn òtítọ́ ìṣègùn hàn. Àlàyé náà fúnni ní àkópọ̀ ìsọfúnni dáradára kan àti ìsọfúnni yíyèkooro. Síso tí ẹ so ìjẹ́pàtàkì àrà ọ̀tọ̀ mọ́ títètèmọ àwọn àmì àrùn ìkọlù àrùn ọkàn-àyà tún ṣe pàtàkì pẹ̀lú.
“Láìka ìsapá àjùmọ̀ṣe sáyẹ́ǹsì ìṣègùn àti àwùjọ lápapọ̀ sí, ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú òpójẹ̀—àti ní pàtàkì, ìkọlù àrùn ọkàn-àyà—ni ó wọ́pọ̀ jù lọ nínú ohun tí n pànìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn. Gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ abẹ tí ń ṣiṣẹ́ lórí onírúurú ìyípadà lílekoko nínú ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú òpójẹ̀ ọkàn-àyà (lí legbagidi, sísúnkì, òpójẹ̀ dídí ) lójoojúmọ́, tó sì ń lo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà láti ṣèwòsàn àwọn àrùn wọ̀nyí, mo mọ bí àlàyé dídájú tó sì fa kókó ọ̀rọ̀ yọ ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn ènìyàn—àti fún ẹni tí ó ṣeé ṣe kó ní àrùn náà pẹ̀lú.
“Ẹ jẹ́ kí n gbóríyìn fún yín tọ̀yàyàtọ̀yàyà lórí bí ẹ ṣe ṣàgbéyọ kókó yìí—pẹ̀lú ìrètí pé àpilẹ̀kọ yín yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.”
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti máa ka Jí! déédéé tàbí bí o bá fẹ́ kí ẹnì kan kàn sí ọ láti bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.