Jí! Ran Olùkọ́ Kan Lọ́wọ́ ní Moscow
Olùkọ́ kan kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pé òun ń wéwèé láti máa lo àwọn àpilẹ̀kọ inú Jí! tí òun bá ń kọ́ àwọn ọmọ ní kíláàsì. Ó ṣàlàyé pé:
“Mo ronú pé Jí! ń ràn mí lọ́wọ́ láti rí agbára àtigbéǹkanṣe nínú ìgbésí ayé, ó ń dá okun mi padà, ó sì ń yọ mí nínú àwọn èrò amúnisoríkọ́. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àwọn àpilẹ̀kọ àgbàyanu nípa ìjàkadì tí ènìyàn ń bá àwọn kòkòrò àrùn jà [ìtẹ̀jáde ti February 22, 1996]. Ó dá mi lójú pé àwọn ìwé ìròyìn yín ń ṣàǹfààní fún gbogbo ìdílé tó bá ní wọn.” Ó fi kún un pé: “Mo fẹ́ láti máa rí Jí! gbà . . . Láìsí àní-àní, ìwé ìròyìn yín lè ràn mí lọ́wọ́.”
Irú lẹ́tà kan náà, tí a rí gbà láti Stavropol, ìlú ńlá kan tí àwọn ènìyàn ibẹ̀ lé ní ìdá mẹ́rin mílíọ̀nù, tí ó wà níbi tí ó lé ní 1,000 kìlómítà sí ìlà oòrùn gúúsù Moscow, kà pé: “Mo fẹ́ láti kọ̀wé béèrè fún Jí! Àìpẹ́ yìí ni mo gba ìwé ìròyìn yìí méjì. Àwọn àpilẹ̀kọ inú wọn fi òye nípa àwọn ìṣòro tí àwọn ènìyàn dojú kọ hàn. Àwọn kan nínú wọn ṣàpèjúwe àwọn ohun tó jẹ́ tuntun sí mi. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo rí irú àpèjúwe bíbọ́gbọ́nmu bẹ́ẹ̀ nípa àwọn nǹkan.”
Bí inú rẹ yóò bá dùn sí gbígba ẹ̀dà Jí! mìíràn tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti bá ọ jíròrò nínú Bíbélì, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ lára àwọn tí ó wà ni ojú ìwé 5.