Wíwo Ayé
Àwọn Asọmọdọ̀pọ̀ Tí Kò Nírètí
“Àwọn asọmọdọ̀pọ̀” ni ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá láti ṣàpèjúwe àwọn ènìyàn tí a bí láàárín ìgbà tí ogun àgbáyé kejì parí àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960. Láàárín àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà lára àwọn tí wọ́n ṣẹ́gun nínú ogun náà ròyìn pé iye àwọn aráàlú pọ̀ sí i gan-an. Ìwé agbéròyìnjáde The European sọ pé, ìwádìí kan tí a ṣe ní orílẹ̀-èdè 16 fi hàn pé àwọn asọmọdọ̀pọ̀, tí wọn kò bìkítà, tí wọ́n sì lẹ́mìí pé nǹkan yóò dára nípa ọjọ́ ọ̀la nígbà kan rí, ti wá ń “nímọ̀lára àìláàbò nípa ara wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ka ọjọ́ ogbó wọn sí ohun tí ó dà bí ìfòyà.” Kí ló wá fa àìsírètí náà? Ìròyìn náà sọ pé: “Wọ́n ń kojú ayé kan tí wọ́n rò pé ó ti ń ṣàṣejù nínú ìwà tèmi ṣáá, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti àìlèkóra-ẹni-níjàánu àti àìsí ìwà ọmọlúwàbí.”
Àwọn Àkóràn Àrùn Mẹ́dọ̀wú Ìpele C Tí Ó Fara Sin
Ìròyìn kan tí àwùjọ àwọn dókítà kan láti ilẹ̀ Faransé ṣe sọ pé: “Àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C fara hàn bí ohun tí àwọn ará ìlú ń ṣàníyàn lè lórí gan-an ní ilẹ̀ Faransé.” Àwọn dókítà náà tọ́ka pé lẹ́yìn tí a bá ti ṣàwárí pé àrùn ti di mọ́líkì sínú ẹ̀dọ̀ aláìsàn láti nǹkan bí ọdún 10 sí 30 ọdún ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ̀ nípa èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn àkóràn àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C. Àkóràn fáírọ́ọ̀sì àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C lè ṣekú pani, a sì sábà máa ń kó o láti inú ìfàjẹ̀sínilára àti gígún abẹ́rẹ́ oògùn líle sínú ara. Ìròyìn náà kìlọ̀ pé, a nílò àwọn ìlànà ṣíṣàyẹ̀wò kínníkínní dáadáa sí i ní kíákíá, níwọ̀n bí àwọn tí ó mọ̀ pé àwọn ní àrùn náà tẹ́lẹ̀ kí a tó ṣàwárí rẹ̀ lára wọn kò ti tó ìdámẹ́rin. Gẹ́gẹ́ bí ìwé àtìgbàdégbà Hepatology ti sọ, a fojú díwọ̀n rẹ̀ pé 500,000 sí 650,000 àwọn ará Faransé ni wọ́n ti ní àrùn náà ní báyìí.
Ìfọ́mọlọ́mú Ń Dín Àìsàn Kù
Ìwé ìròyìn Parents sọ pé: “Àwọn ọmọ-ọwọ́ tí a fi ọmú bọ́ kò lè tètè ní àrùn etí àti ìgbẹ́ gbuuru, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a fi àwọn ọmọ-ọwọ́ tí ó lé ní 1,700, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín oṣù 2 sí 7 ṣe ti fi hàn. Àwọn olùwádìí ní Àwọn Ibùdó fún Ìkáwọ́ àti Ìṣèdíwọ́ fún Àrùn ṣàwárí pé ó ṣeé ṣe kí ọmọ-ọwọ́ kan tí wọ́n ń fi oúnjẹ inú agolo nìkan bọ́ ní ọ̀kan lára àwọn òkùnrùn wọ̀nyí ní ìlọ́po méjì ti ọmọ-ọwọ́ tí wọ́n ń fi ọmú nìkan bọ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà ti gbà gbọ́ tipẹ́tipẹ́ pé wàrà ọmú ń dáàbò bo ọmọ-ọwọ́ lọ́wọ́ àkóràn nítorí ó ń tàtaré àwọn agbógunti àrùn ara ìyá, ìwádìí náà fi hàn pé àwọn àǹfààní rẹ̀ pọ̀. Laurence Grummer-Strawn, ẹni tí ó kọ ìwádìí náà jáde, sọ pé: “Ó dára láti sọ pé bí ọmọ jòjòló kan bá ṣe mu wàrà ọmú tó láàárín oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ni nǹkan yóò ṣe dára fún un tó.”
Ara Lílu Ń Fa Ìṣòro
Ara lílu lè jẹ́ àṣà tí àwọn ènìyàn ń kó lọ́pọ̀lọpọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àmọ́ ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé, “ètè, ẹ̀rẹ̀kẹ́, àti ahọ́n tí a lu ń fa àwọn ewu tí ìṣòro tí wọ́n ń fà kì í ṣe àkóràn nìkan.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣègùn eyín ní Ẹ̀ka Ìṣègùn Eyín ní Yunifásítì West Virginia, ní Morgantown ti sọ, “ìrora, ara wíwú, àkóràn, itọ́ dídà jù, àti pípa erìgì lára wọ́pọ̀ nínú àwọn aláìsàn tí a lu ẹ̀ya ẹnu wọn. . . . Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi ń há ẹ̀yà ẹnu tí a lu túbọ̀ ń fa ìṣòro tí ó pọ̀.” Ohun ọ̀ṣọ́ náà lè gé eyín tàbí kí ó kán an, ó lè fa àbùkù nínú ọ̀rọ̀ sísọ, ó lè dá àpá sí ẹran ara, àti—bí a bá gbé e mì—ó lè dí ọ̀nà èémí.
Ẹ Jọ̀wọ́, A Kò Fẹ́ Ìbáradíje
Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin sọ pé, Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé (WCC), tí 330 ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀, ti “pè fún fífòpin sí ìgbìdánwò ‘oníbàáradíje’ tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ń ṣe láti fi gba àwọn mẹ́ńbà tuntun lọ́wọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn.” Ìgbìmọ̀ WCC “ṣe lámèyítọ́ lílo ‘ìrànlọ́wọ́ ìfẹ́dàáfẹ́re’ . . . láti fi fa ojú àwọn òtòṣì, àwọn tí wọ́n nìkan wà àti àwọn tí a fipá ta nù, mọ́ra ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ní pàtàkì kí wọ́n lè yí ìsìn wọn padà.” Wọ́n pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ‘ẹ̀rí Ìhìn Rere náà tí a tẹ́wọ́ gbà àti ìyíninísìnpadà tí a kò tẹ́wọ́ gbà.’ Ìyíninísìnpadà tí a kò tẹ́wọ́ gbà ní àwọn ohun wọ̀nyí nínú, “ìṣelámèyítọ́ olójúsàájú” nípa ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn, fífi ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn ìgbàgbọ́ ẹni hàn bí èyí tí ó jẹ́ òtítọ́, fífún àwọn mìíràn ní àǹfààní ẹ̀kọ́ tàbí ìrànlọ́wọ́ ìfẹ́dàáfẹ́re láti sún wọn yí ìsìn wọn padà, kíkàn án nípá tàbí lílo ìfìtínà ti ìrònú òun ìhùwà láti rọ àwọn ẹlòmíràn láti yí ìsìn wọn padà, àti lílo ipò àìfararọ tí àwọn ènìyàn wà tàbí “ẹ̀tàn tí ó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn láti lè ‘yí’ wọn ‘lọ́kàn padà.’”
Ìsọgbódaṣálẹ̀ ní Ítálì
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ Ítálì mọ́ aṣálẹ̀, ó ti gbé Ìgbìmọ̀ Ìjọba Àpapọ̀ kan kalẹ̀ fún Ìgbéjàko Aṣálẹ̀. Fún kí ni? Àìlẹ́tùlójú ilẹ̀ ti ń tàn kálẹ̀ lọ síhà àríwá ní Ítálì. Ìwé agbéròyìnjáde La Stampa sọ pé: “Bí a kò bá lo ìlànà tí ó gbàrònú kan nípa àyíká láti dín àwọn gáàsì tí ń fa ìmáyégbóná kù, kí a sì yí àwọn ọ̀nà kan tí a ń gbà ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ń ṣèpalára padà, láàárín ẹ̀wádún mélòó kan, ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn àgbègbè [Ítálì] lè di ilẹ̀ tí a pa run.” Wọ́n ké gbàjarè náà níbi ìpàdé àpérò Àjọ Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí ó dá lórí ìsọgbódaṣálẹ̀, tí wọ́n ṣe ní Róòmù. Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn àgbègbè tí wọ́n wà nínú ewu kò mọ sí àwọn àgbègbè ìhà gúúsù Ítálì náà, Sicily, Sardinia, Calabria, Apulia, àti Basilicata, nìkan mọ́, àmọ́ pé ó tún ti kan àwọn àgbègbè kan tí wọ́n sábà máa ń mú irè jáde ní àríwá, ọ̀rá ilẹ̀ wọn sì ti ń dín kù.
Ṣíṣètọ́jú Àrùn Ìgbẹ́ Gbuuru Ọmọdé
Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Journal ti Caracas sọ pé: “Àwọn olùwádìí ará Venezuela ti ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára kan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ mú ìgbẹ́ gbuuru lílégbákan kúrò pátápátá. Wọ́n ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára náà . . . láti dáàbò boni lọ́wọ́ ìgbẹ́ gbuuru tí fáírọ́ọ̀sì rotavirus ń fà, tí ń pa nǹkan bí 873,000 ọmọdé tí wọn kò tíì pé ọdún márùn-ún lọ́dọọdún ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Kódà ní United States, àrùn náà ṣì ń gbé ohun tí ó lé ní 100,000 ọmọ jòjòló àti àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi lọ sí ilé ìwòsàn lọ́dọọdún. Ìwádìí náà, tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde The New England Journal of Medicine, ròyìn pé gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà dáàbò boni ní ìwọ̀n ìpín 88 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́wọ́ fáírọ́ọ̀sì náà, ó sì fi ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún dín iye àwọn tí a ń gbà sí ilé ìwòsàn nítorí ìgbẹ́ gbuuru lílégbákan kù. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìfàsẹ́yìn kan wà. Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Journal sọ pé: “Ìtọ́jú náà lè ti gbówó lórí jù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà”—àwọn orílẹ̀-èdè “níbi tí wọ́n ti ń ná iye tí kò tó 20 dọ́là fún títọ́jú ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún.” Títí di ìgbà tí a óò lè pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára náà tí kò ní gbówó lórí, a gbọ́dọ̀ máa ṣètọ́jú ìpàdánù omi ara tí ìgbẹ́ gbuuru ń fà nípa dídá omi tí a pàdánù padà sára, ìlànà tí a ti ń lò fún 20 ọdún, tí ó sì gbéṣẹ́.
A Rí Rìṣíìtì Tẹ́ńpìlì
Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé, ohun “tí ó jọ rìsíìtì tí wọ́n já fúnni fún ìdáwó ṣékélì onífàdákà mẹ́ta fún Tẹ́ńpìlì Yahweh” ti “wà ní ọjà àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé. Èyí ni àfikún ibi tí a ti mẹ́nu kan Tẹ́ńpìlì Ọba Sólómọ́nì yàtọ̀ sí inú Bíbélì, tí ó pẹ́ jù lọ, tí a tíì ṣàwárí. A ti rí [àwọn ọ̀rọ̀ náà] BYT YHWH, ‘ilé Olúwa [Yahweh],’ . . . lódindi nínú àkọlé kan ṣoṣo yàtọ̀ sí inú Bíbélì,” àti nítorí tí a kò mọ àyíká ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáradára, awuyewuye ti wà nípa ìtumọ̀ rẹ̀. Àpáàdì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí, tí a kọ nǹkan sí lára náà, tí ó gùn ní sẹ̀ǹtímítà 10.9 lóròó àti sẹ̀ǹtímítà 8.6 níbùú, tí ó sì ní ìlà márùn-ún àti ọ̀rọ̀ 13, hàn ketekete, ó sì rọrùn láti kà. Níwọ̀n bí ó ti wà láti ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, ó kéré tán, ó fi ọ̀rúndún kan ju àkọlé kejì lọ, àwọn ògbógi sì ti kéde pé ó ṣeé gbà gbọ́.
Awuyewuye Nípa Ayaba Ṣébà
Ní Etiópíà, wọ́n ń pè é ní Makeda. Ní Yemen, orúkọ rẹ̀ ni Bilqis. A mọ̀ ọ́n dáradára sí ayaba Ṣébà, tí a mẹ́nu kan nínú Bíbélì àti Kùránì. Orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ń sọ pé tòun ni, wọ́n sì nírètí pé àwọn óò rí ibojì rẹ̀ níbẹ̀ láìpẹ́, wọ́n sì ń fún àwọn awalẹ̀pìtàn níṣìírí láti máa túbọ̀ walẹ̀ láti rí ẹ̀rí kó jọ. Bí wọ́n bá lè rí ẹ̀rí nípa ayaba Ṣébà, ibi tí wọ́n ti rí i yóò di ibi fífanimọ́ra kíkàmàmà fún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́, yóò sì tún fìdí ẹ̀rí ìsopọ̀ pẹ̀lú ọ̀làjú ìgbàanì tí orílẹ̀-èdè náà sọ pé òun ní múlẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal sọ pé: “Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ọ̀pọ̀ àkọlé tí ó wá láti ilẹ̀ ọba Ṣébà ìgbàanì lórí àwọn ògbólógbòó òkúta ní Etiópíà àti Yemen. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé èyíkéyìí lára wọn kò mẹ́nu kan Makeda tàbí Bilqis.” Ó fi kún un pé: “Bíbélì kò fi bẹ́ẹ̀ ṣèrànwọ́. Ó ṣàkọsílẹ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ gbogbo wúrà àti àwọn nǹkan amóúnjẹ-tasánsán tí Ṣébà kó wá fún Sólómọ́nì, àmọ́ kò sọ ibi tí ó ti wá.”
Àwọn Àkájọ Ìwé Tí Wọ́n Kó Pamọ́
Àwọn ará Samáríà, tí iye wọn ti dín kù sí 600 péré, gbọ́dọ̀ wá mílíọ̀nù kan dọ́là jáde láti fi gba àwọn ìwé mímọ́ wọn padà. Wọ́n jí àwọn àkájọ ìwé méjèèjì náà, tí a gbọ́ pé ọ̀kan ti pẹ́ tó 700 ọdún tí èkejì sì ti pẹ́ tó 400 ọdún, kó ní sínágọ́gù àwọn ará Samáríà kan ní ìlú ńlá West Bank ní Nablus ní ohun tí ó ti lé ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn. Àwọn olè náà yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kó àwọn àkájọ ìwé náà jáde ní orílẹ̀-èdè náà, àìpẹ́ yìí sì ni a wá rí wọn ní Amman, Jọ́dánì, níbi tí àwọn àgbààgbà Samáríà ti wá wò wọ́n. A gbà gbọ́ pé ẹnì kan tí ó mọ ibi tí wọ́n kó wọn sí dáradára ló lọ jí wọn kó. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Samáríà ní ń gbé orí òkè ńlá náà tí ó ga ju Nablus lọ, tí ó jẹ́ ibi mímọ́jùlọ wọn. Wọ́n gbà gbọ́ pé ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Ábúráhámù láti fi ọmọ rẹ̀ Ísákì rúbọ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure: Shlomo Moussaieff