Ìparadà—Ǹjẹ́ Rírí Ni Ẹ̀rí fún Wíwà?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA ÀÁRÍNGBÙNGBÙN ÁFÍRÍKÀ
ADÁHUNṢE náà kú. Ṣùgbọ́n lójú ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn tó pé jọ síwájú ilé rẹ̀, ó wulẹ̀ para dà lásán ni. Nítorí pé ní kété tí ó kú gan-an, wọ́n rí òjòlá ńlá kan tó wọ́ jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀! Lójú àwọn kan, èyí wulẹ̀ ṣe kòńgẹ́ ni. Ṣùgbọ́n lójú àwọn mìíràn, ó jẹ́ ẹ̀rí tí ó mú kí ó dá wọn lójú pé adáhunṣe náà ti yí pa dà di òjòlá—ó ti para dà!
Níbi púpọ̀ ní Áfíríkà, èrò pé ẹnì kan lè yí padà tàbí pé a lè yí ẹnì kan padà di ẹranko wọ́pọ̀ gan-an. Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn oṣó lágbára láti para dà di àmọ̀tẹ́kùn tàbí òjòlá. Bákan náà ni èrò pé oṣó lè pa ẹnì kan dà di ẹranko tún wọ́pọ̀. Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn àjẹ́ lè rán ẹ̀mí ènìyàn jáde lọ bí ẹyẹ tàbí ẹranko mìíràn láti lọ ṣe ìjàǹbá. Ní àáríngbùngbùn Áfíríkà, àwọn ènìyàn kan kò jẹ́ pa erin tàbí ejò, nítorí ìbẹ̀rù pé ẹbí wọn kan tó ti kú lè ti di ọ̀kan nínú irú àwọn ẹranko wọ̀nyí.
Nígbà tí irú ìgbàgbọ́ wọ̀nyí lè ṣàjèjì sí àwọn kan tí ń kàwé yìí, ọ̀pọ̀ ará Áfíríkà gbà pé àwọn tó fojú rí irú ìyírapadà bẹ́ẹ̀ ti jẹ́rìí gbè é. Wọ́n sọ pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtàn tí àwọn ènìyàn olóye ń sọ ní àsọtúnsọ kò lè jẹ́ èèṣì lásán.
Òtítọ́ ni pé a tún lè rí irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ jákèjádò ayé. Bí àpẹẹrẹ, ní Japan, àwọn ènìyàn gbà gbọ́ pé wọ́n lè di kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, ajá, àti gara. Bákan náà ni àwọn àlọ́ àpagbè ilẹ̀ Yúróòpù ní ìtàn àwọn ènìyàn tí wọ́n pa lára dà di ìkookò panipani lóru. Ní àwọn apá ibòmíràn láyé, a ń gbọ́ oríṣiríṣi ìtàn nípa àwọn ẹkùn, akọ ẹlẹ́dẹ̀, ọ̀nì, àti ológbò pàápàá tí ó lè ṣe ènìyàn kó tún ṣe ẹranko.
Ǹjẹ́ Ìwé Mímọ́ Tì Í Lẹ́yìn?
Àwọn kan tilẹ̀ sọ pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ti ìgbàgbọ́ nínú ìparadà tó ju ti agbára ẹ̀dá lọ lẹ́yìn. Wọ́n sábà máa ń tọ́ka sí àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì mẹ́rin bí ẹ̀rí. Nínú ti àkọ́kọ́, Jésù lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde lára àwọn ọkùnrin méjì, lẹ́yìn tí ó lé wọn jáde tán, àwọn ẹ̀mí èṣù náà wọ inú agbo ẹlẹ́dẹ̀ kan. (Mátíù 8:28-33) Nínú àkọsílẹ̀ kejì, tí ó wà nínú Númérì 22:26-35, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù bá a sọ̀rọ̀. Nínú ìkẹta, bóyá tí ó jẹ́ èyí tí a mọ̀ dunjú jù, ejò kan bá Éfà sọ̀rọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.
Bí ó ti wù kí ó rí, àyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ní fínnífínní fi hàn pé dájúdájú, wọn kì í ṣe àwọn àpẹẹrẹ ìparadà. Ẹ jẹ́ kí a mú ti àwọn ẹlẹ́dẹ̀ tí ẹ̀mí èṣù bà lé náà bí àpẹẹrẹ. Bíbélì kò sọ pé àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ àwọn ènìyàn tó para dà di ẹranko. Ó tì o, àkọsílẹ̀ náà sọ pé, kí ẹ̀mí èṣù tó bà lé wọn, “ọ̀wọ́ ọ̀pọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ kan ń jẹ̀ nínú pápá ìjẹko.” (Mátíù 8:30) Àwọn ẹ̀mí búburú ti Sátánì ló wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, kì í ṣe ẹ̀mí àwọn ènìyàn.
Nípa ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù àti ejò ti Édẹ́nì ńkọ́? Nínú ti àkọ́kọ́, Bíbélì sọ ní pàtó pé “Jèhófà la ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà” tí ó fi lè sọ̀rọ̀. (Númérì 22:28) Kì í ṣe ènìyàn kan tó para dà. Ní ti ejò ti Édẹ́nì pàápàá, Bíbélì fi ẹ̀dá ẹ̀mí búburú tí ń jẹ́ Sátánì Èṣù hàn kedere bí “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.” (Ìṣípayá 12:9) Sátánì ló tipasẹ̀ ejò náà sọ̀rọ̀, tí ó sì “sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:3) Dájúdájú, ẹranko ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù, ẹranko sì ni ejò náà—kí wọn tó sọ̀rọ̀, nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀, àti lẹ́yìn tí wọ́n sọ̀rọ̀ tán.
Àkọsílẹ̀ kẹrin tí wọ́n tún máa ń tọ́ka sí ni ti agbéraga ọba Bábílónì náà, Nebukadinésárì. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run rẹ Nebukadinésárì sílẹ̀. “A . . . ṣe ọkàn-àyà” rẹ̀ “bí ti ẹranko, ibùgbé rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́. Wọ́n fún un ní ewéko jẹ gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ìrì ọ̀run sì rin ín, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé.” (Dáníẹ́lì 5:21) Láàárín ọdún méje tí orí Nebukadinésárì fi dà rú, ó rí bí ẹranko, ó sì ń hùwà bí ẹranko. Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì 4:33 ṣe wí, “irun rẹ̀ . . . gùn bí ti ìyẹ́ idì àti èékánná rẹ̀ bí èékánná ẹyẹ.” Síbẹ̀síbẹ̀, ọba náà kò hùyẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì hu èékánná ẹyẹ nígbà kankan. Ó jẹ́ ènìyàn síbẹ̀!
Èrò nípa ìparadà tó kọjá agbára ẹ̀dá lòdì sí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ní tààrà. Ìdí ni pé, Bíbélì fi hàn pé ènìyàn kò ní ọkàn kan tó dá wà, tó lè wọnú ẹranko kan lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ènìyàn fúnra rẹ̀ jẹ́ “alààyè ọkàn”! (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ìparadà kò tún bá ìṣètò nǹkan lọ́nà ti ẹ̀dá tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe mu. A ṣẹ̀dá àwọn ẹranko láti máa bímọ “ní irú tiwọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:24, 25) Nítorí àwọn ààlà apilẹ̀ àbùdá tí Ọlọ́run ti pa, kò ṣeé ṣe fún onírúurú, tàbí ìṣọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn ẹranko, láti bá ara wọn dà pọ̀, kí wọ́n sì bímọ. Ìyàtọ̀ tí ó wá pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ wà láàárín àwọn ẹranko àti ènìyàn tí a dá ‘ní àwòrán Ọlọ́run.’ (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Dájúdájú, Ọlọ́run kò ní pẹ̀gàn àwọn òfin tí òun fúnra rẹ̀ ṣe nípa fífún ènìyàn ní agbára láti pa ara wọn dà di àwọn ẹranko aláìnírònú.
Òtítọ́ ni pé a lè rí ìparadà nínú ìṣẹ̀dá. Àwọn mùkúlú ń para dà di labalábá, àwọn légbélègbé sì ń para dà di àkèré. Bí ó ti wù kí ó rí, àkíyèsí tí a fara balẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn àpẹẹrẹ ìparadà wọ̀nyí kò kan ìyípadà “irú,” wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìdàgbàsókè “irú” kan náà ni. Nígbà tí wọ́n bá ti dé ìpele àgbà, wọn yóò máa bímọ “ní irú tiwọn.”
Rírí Kì Í Fìgbà Gbogbo Jẹ́ Ẹ̀rí fún Wíwà
Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè ṣàlàyé ọ̀ràn ti àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn fojú rí ìparadà tó kọjá agbára ẹ̀dá? Ó ṣe kedere pé èyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ mìíràn ní ti “ìṣiṣẹ́ Sátánì pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo fún àwọn tí ń ṣègbé,” ni.—2 Tẹsalóníkà 2:9, 10.
Bí àṣà tí gbogbo abúmọ́ni ń dá, àwọn ẹ̀mí èṣù ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn gbà gbọ́ pé àwọn ní agbára ju bí wọ́n ṣe ní in ní tòótọ́ lọ. Wọ́n ń ṣe àwọn “iṣẹ́ àmì” tí wọ́n fi ń yíni lérò padà, tí ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà tí àwọn olè àti àwọn gbájú-ẹ̀ ń ṣe.
Ó múni rántí àwọn oníjìbìtì atakáàdì tí ń sábà lọ sí ọ̀pọ̀ ọjà ilẹ̀ Áfíríkà. Láìtijú, wọ́n ń tan àwọn ìyàwó ilé mélòó kan láti fi owó òógùn ojú wọn ṣòfò nídìí ẹ̀tàn ayò káàdì. Wọn yóò fi káàdì mẹ́ta—pupa méjì àti dúdú kan—han obìnrin kan, wọn yóò sì sọ fún un pé ó lè sọ owó rẹ̀ di ìlọ́po méjì nípa wíwulẹ̀ mú káàdì dúdú náà jáde. Yóò lọ́ra láti ta á—títí di ìgbà tí ó bá rí ẹlòmíràn tó jọ pé ó jẹ ayò tí kò nira yìí. Kò ní mọ̀ pé alájọṣe àwọn oníjìbìtì náà ni ẹni tí wọ́n sọ pé ó jẹ náà. Òun náà á kówó kalẹ̀, yóò fojú mú káàdì dúdú náà bí wọ́n ti ń dojú wọn bolẹ̀ tí wọ́n sì ń yọ̀ wọ́n. Ṣùgbọ́n ìtìjú àti ìbànújẹ́ ń bá a bí ó ti ń já sí pé káàdì pupa ló mú. Ó ti ná owó oúnjẹ ìdílé rẹ̀—ó ti kó sí pàkúté ìwọra tirẹ̀ àti ti oníjìbìtì gbígbọ́nféfé kan! Ẹ̀pa ò bóró mọ́, ó ti wá mọ̀ pé rírí kì í ṣe ẹ̀rí fún wíwà.
Lọ́nà kan náà, inú Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ máa ń dùn láti máa tan àwọn ènìyàn jẹ láti rò pé ẹ̀dá ènìyàn lè para dà di ẹranko. Ògbógi ni Sátánì nídìí ẹ̀tàn. Ó ṣe tán, òun ló pa irọ́ àkọ́kọ́, tó sọ fún Éfà pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. . . . Ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5) Irọ́ yìí ti ṣokùnfà onírúurú ẹ̀kọ́ tí ń sé àwọn ènìyàn mọ́ inú ìbẹ̀rù, lára wọn ni àìleèkú ọkàn, iná ọ̀run àpáàdì, àti ìparadà. Nípa bẹ́ẹ̀, ní Áfíríkà, àwọn ènìyàn ṣe tán láti san arabaríbí owó láti “jẹ àjẹsára” nítorí wọ́n rò pé èyí lè dáàbò bò wọ́n, kí wọ́n má ṣeé yí padà di ẹranko. Ní ti gidi, “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù” ti di irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nígbèkùn, ó sì ń dí wọn lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—1 Tímótì 4:1; Jákọ́bù 4:7.
Ìparadà Tòótọ́
Bóyá o ti fìgbà gbogbo gbà gbọ́ pé ìparadà wà, kódà tí o ti ń bẹ̀rù rẹ̀ pàápàá. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kọbi ara sí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nínú Róòmù 12:2. Níbẹ̀, nínú àkọsílẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, a lo oríṣi ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, me·ta·mor·phoʹo. A kà pé: “Ẹ para dà [me·ta·mor·phouʹsthe] nípa yíyí èrò inú yín padà.” Èyí tọ́ka sí ìparadà kan tí ó lè ṣẹlẹ̀—yíyí àkópọ̀ ìwà ẹni padà pátápátá!
Àwọn tí ń fẹ́ láti wu Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀, nítorí Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.”—Kólósè 3:9, 10.
Báwo ni o ṣe lè para dà? Nípa gbígba ìmọ̀ pípéye láti inú Bíbélì. Ìmọ̀ yẹn lè mú kí o jáwọ́ lára àwọn èrò àti àbá tí o ti ń gbé gẹ̀gẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí Jésù ti wí, “ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Dájúdájú, o lè gba ìdáǹdè lọ́wọ́ àwọn irọ́ àti ìbẹ̀rù nípa ìparadà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ohun tí a “rí” kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ohun gidi
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]
Oníṣègùn ìbílẹ̀: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Africana Museum, Johannesburg