“Ojúlówó Ìwé Ìròyìn”
Ǹjẹ́ o ti ka ìwé ìròyìn Jí! rí? Kí ni o lè sọ nípa ìjójúlówó ẹ̀dà tí ó wà lọ́wọ́ rẹ yìí? Àwọn àpilẹ̀kọ inú rẹ ha ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ha ṣèwádìí dáradára lórí wọn, wọ́n ha sì ní àwòrán tí ó wuni bí?
Akọ̀ròyìn aládàáni kan láti Nàìjíríà, Áfíríkà, kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo máa ń ka Jí! déédéé. Ojúlówó ìwé ìròyìn ni Jí! jẹ́. Ó jẹ́ orísun èrò ìdánúṣe fún mi. Àwọn èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ ń jojú ní gbèsè, wọ́n sì ń ru ọkàn òǹkàwé tí kò ní ẹ̀tanú sókè láti ṣí i kà. Ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ń jẹ́rìí sí ìgbékalẹ̀ àrà ọ̀tọ̀; ojú ìwé kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ọ̀nà ìkọ̀ròyìn títayọ. Ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan, tí ó ní àwọn àpilẹ̀kọ tí a kọ dáradára, tí ó sì bágbà mu, jẹ́ ìpèsè ìsọfúnni tí ó níye lórí tí kò sì ṣe é díye lé.”
A rọ̀ ọ́ láti ka àwọn àpilẹ̀kọ tí ó wà nínú ẹ̀dà Jí! yìí. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ ní ojú ìwé 5.