Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 25. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Orúkọ wo ni a tún ń pe Òkun Gálílì, tí ó bá orúkọ ìlú kan tí ó wà ní etíkun ìwọ̀ oòrùn rẹ̀ mu? (Jòhánù 6:1; 21:1)
2. Ibo ni 200 lára àwọn 600 ọkùnrin jagunjagun Dáfídì ti dúró nígbà tí ó rẹ̀ wọ́n lákòókò tí wọ́n ń lé àwọn agbésúnmọ̀mí ará Ámálékì tí wọ́n kó àwọn aya Dáfídì méjì ní òǹdè? (1 Sámúẹ́lì 30:9, 10)
3. Àárín kí ni Ráhábù fi àwọn amí ọmọ Ísírẹ́lì méjì pa mọ́ sí? (Jóṣúà 2:6)
4. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé yóò ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè “ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà”? (Hébérù 12:28)
5. Kí ni Òfin Mósè ní kí ọ̀gá kan ṣe bí ẹrú rẹ̀ kò bá fẹ́ jáde lọ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira? (Ẹ́kísódù 21:6)
6. Ìlú ńlá wo ni a wá mọ̀ bí ìlú ọgbọ́n ní Édómù? (Jeremáyà 49:7)
7. Igi wo ni a fi ṣe àwọn ilẹ̀kùn Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì? (1 Àwọn Ọba 6:31-33)
8. Ohun méje wo ni Òwe 6:17-19 sọ pé Jèhófà kórìíra?
9. Èwo ló kẹ́yìn lára ẹyọ lẹ́tà álífábẹ́tì èdè Hébérù? (Sáàmù 119:169, àkọlé)
10. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ń fúnrúgbìn kín-ún, bí a bá fi wé àwọn tí ń fúnrúgbìn yanturu? (2 Kọ́ríńtì 9:6)
11. Nígbà tí Sátánì ń pe Jèhófà níjà pé kí ó fawọ́ ìbùkún rẹ̀ kúrò lórí Jóòbù, kí ni ó sọ pé Jóòbù yóò ṣe? (Jóòbù 1:11)
12. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí “orúkọ àwọn ẹni burúkú”? (Òwe 10:7)
13. Mélòó ni kò wá fìmoore hàn lára àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá tí Jésù wẹ̀ mọ́? (Lúùkù 17:17)
14. Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tí ògiri Jẹ́ríkò fi wó lulẹ̀? (Jóṣúà 6:5)
15. Kí ni a sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá rí ẹyẹ nínú ìtẹ́ rẹ̀? (Diutarónómì 22:6, 7)
16. Èé ṣe tí Jèhófà fi ṣe ojúrere àkànṣe sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Aísáyà 41:8)
17. Ọmọ aládé mélòó ló ń gba Ahasuwérúsì Ọba nímọ̀ràn, tí wọ́n sì fara mọ́ ẹjọ́ tí ó dá fún Fáṣítì Ayaba? (Ẹ́sítérì 1:14)
18. Ọrẹ ẹbọ tí olùjọsìn kan rú sí Jèhófà, tí kò sì ṣẹ́ èyíkéyìí lára rẹ̀ kù. (Léfítíkù 1:4)
19. Kí ni ohun méjì tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe kí a lè gbà á là? (Róòmù 10:9)
20. Ọdún bí mélòó ni Sólómọ́nì fi kọ́ tẹ́ńpìlì? (1 Àwọn Ọba 6:1, 38)
21. Ní ìgbà láéláé, kí ni a máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fún ọ̀tá tí a bá mú kí ó má bàa lágbára? (Onídàájọ́ 1:6)
22. Ibo ni Mósè kọ́kọ́ tọ́jú àwọn wàláà òkúta Òfin sí? (Diutarónómì 10:1-5)
23. Ìwé wo nínú Bíbélì ló sọ nípa ìgbòkègbodò Pétérù àti Pọ́ọ̀lù ní pàtàkì?
24. Kí ni orúkọ ìránṣẹ́bìnrin tí inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí ó gbọ́ ohùn Pétérù, tí kò ṣí ilẹ̀kùn fún un, àmọ́ tí ó sáré wọlé lọ sọ fún àwọn yòókù pé Pétérù wà ní ẹnu ọ̀nà? (Ìṣe 12:13, 14)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Òkun Tìbéríà
2. Àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Bésórì
3. Pòròpórò ọ̀gbọ̀
4. “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀”
5. “Fi òòlu lu etí rẹ̀”
6. Témánì
7. Igi olóròóró
8. “Ojú gíga fíofío, ahọ́n èké, àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀, ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú, ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ, àti ẹnikẹ́ni tí ń dá asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin”
9. Tọ́ọ̀
10. Wọn óò ká ní ìbámu pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fúnrúgbìn
11. Yóò bú Jèhófà ní ojú rẹ
12. Yóò jẹrà
13. Mẹ́sàn-án
14. Wọ́n kígbe
15. Wọ́n lè kó àwọn ọmọ, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyá lọ
16. Wọ́n jẹ́ “irú-ọmọ Ábúráhámù,” tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà
17. Méje
18. Ọrẹ ẹbọ sísun
19. Ó gbọ́dọ̀ polongo pé Jésù ni Olúwa ní gbangba, kí ó sì lo ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run gbé Jésù dìde kúrò nínú òkú
20. Ọdún méje
21. Wọ́n ń gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ rẹ̀
22. Àpótí tí ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe
23. Ìṣe
24. Ródà