Ojú ìwé 2
Ǹjẹ́ A Óò Ṣẹ́gun Àrùn AIDS? 3-9
Báwo ni ènìyàn ṣe ń kó àrùn AIDS? Ibo ló ti ń jà jù nísinsìnyí? Ǹjẹ́ a lè ṣẹ́gun rẹ̀? Àwọn àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ nínú ìwé ìròyìn yìí yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àti àwọn mìíràn.
Báwo Là Bá Ti Ṣe É Láìsí Àwọn Afárá? 10
A kì í kà wọ́n sí. Bẹ́ẹ̀ ìgbésí ayé ì bá yàtọ̀ ká ní kò sí wọn! Kí ni a mọ̀ nípa wọn? Èé ṣe tí wọ́n fi wà lóríṣiríṣi?
Ǹjẹ́ Ìwà Ìkà sí Àwọn Ẹranko Dára? 26
Ìjà ajá, ìjà adìyẹ, ìjà ẹṣin, ìjà màlúù—ìwà ìkà sí àwọn ẹranko ti jẹ́ eré ìdárayá fún àwọn ènìyàn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Kí ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
IWÁJÚ ÌWÉ: Chad Slattery/Tony Stone Images (Àwòrán kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú kókó ìjíròrò.)