Wíwo Ayé
Ọdún 2000 àti Kristi
Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin sọ pé: “Ìwádìí fi hàn pé kò tó ọ̀kan nínú ará Britain mẹ́fà tí ó sọ pé ọdún 2000 ní í ṣe pẹ̀lú Kristi.” Ìwádìí Èrò Aráàlú kan “fi bí àìmọ̀kan àwọn aráàlú nípa Ẹgbẹ̀rúndún náà ṣe lékenkà tó hàn, tí ìpín mẹ́tàdínlógójì lára àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sì sọ pé, àwọn kò mọ ìdí tí a fi ń rántí rẹ̀ . . . , ìpín méjìdínlógún lára wọn sọ pé, àṣeyẹ náà sàmì sí ọ̀rúndún tuntun, ìpín mẹ́tàdínlógún lára wọn sì sọ pé wọ́n sàmì sí ọdún 2000.” Ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ló rí ìsopọ̀ láàárín ọdún 2000 àti ìbí Kristi. Ọ̀jọ̀gbọ́n Anthony King ti Yunifásítì Essex sọ pé, fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ẹgbẹ̀rúndún náà túmọ̀ sí “kìkì àkókò àǹfààní láti jó, kí wọ́n mu ọtí òyìnbó, kí wọ́n sì wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn títí di ọ̀gànjọ́ òru tàbí kí wọ́n rìnrìn àjò lọ sí òkè òkun.” Bíṣọ́ọ̀bù Áńgílíkà náà, Gavin Reid, ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà báyìí pé: “A ń gbé láàárín ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí kò rántí àwọn àṣà àti ohun tẹ̀mí rẹ̀ mọ́.”
Ìkìlọ̀ Lórí “Àwọn Kòkòrò Àrùn tí Kò Gbóògùn”
Ìwé ìròyìn Star ti Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Bí ‘àwọn kòkòrò àrùn tí kò gbóògùn’ kò ṣe jẹ́ kóògùn agbógunti kòkòrò àrùn tí ó lágbára jù ṣiṣẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ìkìlọ̀ fún gbogbo ènìyàn, kì í ṣe fún àwọn oníṣègùn nìkan ṣùgbọ́n fún àwọn tí ń lò ó pẹ̀lú.” Onímọ̀ nípa ìyípadà tí àrùn inú ara ń fà náà, Mike Dove, kìlọ̀ pé “àwọn àrùn kan tí a ti fìgbà kan rí tọ́jú tàbí tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kúrò tán pátápátá tún ti ń di nǹkan mìíràn, wọ́n sì ti ń padà wá báyìí.” Àlòjù oògùn agbógunti kòkòrò àrùn ti yọrí sí àwọn oríṣi ikọ́ ẹ̀gbẹ (TB) tuntun, ibà, àìsàn táífọ́ọ̀dù, àtọ̀sí, àrùn lọ́rùnlọ́rùn, àti òtútù àyà tí ó túbọ̀ ń ṣòro láti tọ́jú, tí àwọn oògùn òde-òní kò sì ràn wọ́n. Ikọ́ ẹ̀gbẹ nìkan ń pa àwọn ènìyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta lọ́dún kan. Àwọn olùgbàtọ́jú lè ṣèrànwọ́ nípa rírántí nǹkan wọ̀nyí: Lákọ̀ọ́kọ́, gbìyànjú irú ìgbésẹ̀ bíi mímu omi tí ó pọ̀, fífún ara rẹ ní ìsinmi tí ó yẹ, kí o sì máa fi omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ tí a fi iyọ̀ sí yọnu bí ọ̀fun bá ń dùn ọ́. Má ṣe fagbára mú dókítà rẹ láti fún ọ ní oògùn agbógunti kòkòrò àrùn—jẹ́ kí ó pinnu bí o bá nílò wọn ní ti gidi. Bí wọ́n bá kó wọn fún ọ, rí i dájú pé o lo gbogbo rẹ̀ tán kódà bí ó bá tilẹ̀ dà bí pé ara rẹ́ ti ń yá. Rántí pé, oògùn agbógunti kòkòrò àrùn kò lè wo òtútù àti ọ̀fìnkìn sàn, nítorí pé fáírọ́ọ̀sì ni ó máa ń fà á kì í ṣe bakitéríà. Dove sọ pé: “Olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti gbógun ti ìṣòro tí ń fa ìdààmú kárí ayé yìí tí ó sì lè ṣe jàǹbá fún ìlera ara.”
Ìbàjẹ́ Ńlá tí Ìsoríkọ́ Ń Ṣe
Ìwé ìròyìn O Globo ti Brazil sọ pé: “Ìsoríkọ́—tí ó burú ju àrùn tí a lè fojú rí ni olórí okùnfà pípabiṣẹ́jẹ àti àìlèṣiṣẹ́ dáradára mọ́ lágbàáyé.” Ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe fi hàn pé ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] ènìyàn ni àrùn ọpọlọ pa ní ọdún 1997. Ní àfikún sí i, àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ọpọlọ, bí kí ìmọ̀lára ẹni yí padà, ti ní ìyọrísí búburú lórí ìgbòkègbodò àwọn amọṣẹ́dunjú tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́jọ ènìyàn kárí ayé—iye tí ó pọ̀ ju mílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gọ́fà òṣìṣẹ́ tó ní ìfàsẹ́yìn nítorí ìṣòro ọ̀rọ̀ gbígbọ́ tàbí àwọn mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí jàǹbá ṣe lẹ́nu iṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Guy Goodwyn ti Yunifásítì Oxford ṣe, ìṣòro ìsoríkọ́ yóò pọ̀ sí i ní ọjọ́ iwájú, ti yóò sì jẹ́ ìnira gan-an fún àwùjọ ènìyàn nítorí àdánù àìlèṣe-ǹkan-jáde àti ìnáwó tó ń peléke sí i lórí ìtọ́jú. Ní United States nìkan, iye tí a ń pàdánù lórí ìsoríkọ́ lọ́dún ti tó bílíọ̀nù mẹ́tàléláàádọ́ta dọ́là báyìí.
Ó Dùn-ún Kà Lórí Bébà
Ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé dpa-Basisdienst ti Germany ròyìn pé: “Kò sí ìkọ̀wé ojú kọ̀ǹpútà kan tí ó ṣeé kà dáadáa bí èyí tí a tẹ̀ sórí bébà.” Kíkà láti inú bébà dípò ojú kọ̀ǹpútà kì í jẹ́ kí a ṣe àṣìṣe púpọ̀, ó sì ń mú kí a yára kàwé. Àwọn ìdánrawò fi hàn pé kíkàwé lójú kọ̀ǹpútà fi ìpíndọ́gba mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún pẹ́ ju kíkàwé lórí bébà lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń sunwọ̀n sí i nígbà tí a bá lo ojú kọ̀ǹpútà tó dára gan-an, tí ń mú kí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí i, tó sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gàdàgbà-gàdàgbà, tí kì í tún ṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ jù, síbẹ̀ a kò lè fi wé bí ó ṣe ń rí tí a bá ń kàwé lórí bébà. Afìṣemọ̀rònú, Martina Ziefle láti Aachen, Germany, sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ń kàwé lójú kọ̀ǹpútà wulẹ̀ ń tẹjú mọ́ orísun ìmọ́lẹ̀ tí ń bù yẹ̀rì, tó ń ṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, tó sì tàn yòò. Àwọn ọ̀rọ̀ náà kì í hàn kedere, ojú rẹ̀ kì í sì í mọ́lẹ̀ dáadáa.” Ìparí ọ̀rọ̀ ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé dpa ni pé: “Nígbà tí o bá fẹ́ ra ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, o ní láti fún bí ojú kọ̀ǹpútà náà ṣe dára sí láfiyèsí gan-an.”
Àmì Àwọn Àkókò
Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Àṣà àtijọ́ kan tí ó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ní Kánádà yóò wá sópin láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá [ní Newfoundland] bá bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìbọn ìléwọ́ kiri fún ìgbà àkọ́kọ́.” Ẹgbẹ́ Ọlọ́pàá ti Ọba Newfoundland, tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1729, ni “agbo ọmọ ogun ọlọ́pàá tí ó yíde kẹ́yìn láìsí ìbọn kan lárọ̀ọ́wọ́tó wọn ní Àríwá Amẹ́ríkà.” Òfin tuntun fi òpin sí èyí tí ó wà tẹ́lẹ̀. Ó béèrè pé kí àwọn ọlọ́pàá máa gba àṣẹ lọ́wọ́ ọ̀gá kan kí wọ́n tó dìhámọ́ra. Bí a bá gba ọlọ́pàá kan láyè, yóò kó ohun ìjà rẹ̀ sínú àpótí kan tí a tì pa nínú búùtù ọkọ̀ tí ó fi ń ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn náà, bí ó bá nílò rẹ̀ ní pàjáwìrì, yóò dá ọkọ̀ rẹ̀ dúró, yóò ṣí búùtù rẹ̀, yóò wá ṣí àpótí náà, yóò sì kó ọta sínú ohun ìjà rẹ̀. Olórí ìjọba náà, Brian Tobin, sọ pé: “Ó ṣàjèjì, ó sì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ bọ́gbọ́n mu ní tòótọ́ láti sọ pé amọṣédunjú kan, agbo ọmọ ogun ọlọ́pàá tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ kò ní àǹfààní láti lo ohun ìjà wọn ní ọdún 1998.” Àpáta náà, orúkọ ọ̀wọ́n tí a mọ Newfoundland mọ́, ṣì ń yangàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí ìwà ọ̀daràn ti lọọlẹ̀ jù ní orílẹ̀-èdè náà, ó sì jẹ́ ibi tí a kò ti yìnbọn pa òṣìṣẹ́ kan lẹ́nu iṣẹ́ rí.
Ẹ̀san Gbígbà Ni Iṣẹ́ Wọn
Ní ṣíṣe ìlérí “àṣírí pípamọ́ dáadáa” àti agbára láti ṣiṣẹ́ ní ibikíbi ni Japan, ilé iṣẹ́ kan ni Tokyo kéde pé: “A óò yanjú ìkùnsínú kan lórúkọ rẹ.” Ọkùnrin tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà sọ pé, ọgbọ́n èrò orí náà ni “láti fi irú ìyà kan náà ti ẹnì kan kọ́kọ́ fi jẹ oníbàárà wa jẹ òun náà.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Asahi Evening News ti sọ, ilé iṣẹ́ náà yóò “gbẹ̀san lọ́nà tí ó bófin mu,” bíi rírí i dájú pé “ẹnì kan pàdánù iṣẹ́ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀,” títú àwọn àjọṣepọ̀ ká, àti “rírí i dájú pé a gba ipò lọ́wọ́ alájọṣiṣẹ́ ẹni tàbí kí a dójú ti ọ̀gá kan tí ń fi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni.” Nínú àwọn ènìyàn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ to àádọ́ta tí ń tẹ ilé iṣẹ́ náà láago lóòjọ́, nǹkan bí ogún nínú wọn ní ń fẹ́ kí a bá àwọn pànìyàn; ṣùgbọ́n àkópọ̀ òfin ilé iṣẹ́ náà kì í ṣe láti fipá ṣe nǹkan tàbí láti tẹ òfin lójú, “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń kù díẹ̀ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.” Wọ́n máa ń gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ sẹ́nu iṣẹ́ náà, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn sì ń ṣiṣẹ́ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ ní àwọn ibi iṣẹ́ mìíràn. Àwọn kan wà nínú wọn tí àwọn fúnra wọn ti jìyà tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti gbẹ̀san. Ọkùnrin tí ó ni ilé iṣẹ́ náà kìlọ̀ pé: “O kò mọ̀ bóyá ohun kan tí o ṣe nígbà kan rí ti mú kí àwọn kan di kùnrùngbùn sí ọ. Ṣọ́ra.”
Àwọn Akàn Orí Ilẹ̀ àti Àyíká Wọn
Àwọn èèrà, ikán, àti ekòló ń rún àwọn ewé àti pàǹtírí sínú igbó, ṣùgbọ́n kí ní ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn igbó kìjikìji ti ilẹ̀ olóoru tí omi máa ń kún ní gbogbo ìgbà? Àwọn akàn orí ilẹ̀ ni ó máa ń ṣe iṣẹ́ náà. Ó ya onímọ̀ ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti ibùgbé wọn kan láti Yunifásítì Michigan, United States of America lẹ́nu láti rí i pé àgbègbè kan tí ó gbòòrò ní Etíkun Pàsífíìkì ti Costa Rica kò ní ewé kankan lórí ilẹ̀ bíkòṣe àwọn ihò ńláńlá tí ó pọ̀. Láàárín òru, ó rí i bí àwọn akàn orí ilẹ̀—tí ó tó ìpín ọ̀kẹ́ mẹ́ta lórí hẹ́kítà kọ̀ọ̀kan—ṣe ń tú jáde láti kó ẹrù àwọn ewé jíjẹrà, èso, àti àwọn hóró, tí wọ́n ń gbé lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn ihò onímítà kọ̀ọ̀kan tí wọ́n gbẹ́. Àwọn akàn tí wọ́n gùn ní ogún sẹ̀ǹtímítà yìí, tí wọ́n ti ní ìjàgbọ̀n fún mímí tí wọ́n sì ń lọ sínú omi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti lọ pamọ, máa ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti fún àwọn gbòǹgbò igi tí ó jìn sí ìsàlẹ̀ lọ́ràá. Ìwé ìròyìn The Times ti London ròyìn pé, gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú igbó náà ni a lè mọ̀ nípasẹ̀ ohun tí àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí ń ṣe.
Nínú Gbalasa Òfuurufú Lọ́hùn-ún
Ìwé ìròyìn Astronomy sọ pé: “Ìhùmọ̀ afìsọfúnni-ránṣẹ́ láti ojúde òfuurufú, Voyager 1, ti wọnú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tí ì rìn jìnnà jù nínú èyí tí ènìyàn ṣe. Èyí tí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni Pioneer 10, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ máa doríkọ ọ̀nà òdìkejì pẹ̀lú ìrìn tó falẹ̀ gan-an.” Báwo ni Voyager 1 ṣe rìn jìnnà tó? Ó rìn jìnnà tó nǹkan bí bílíọ̀nù mẹ́wàá ààbọ̀ kìlómítà ní February 17, 1998. Ọkọ̀ àgbéresánmà náà gbéra ní September 5, 1977; ó kọjá Júpítà ní March 5, 1979; ó sì fò kọjá Sátọ̀n ni November 12, 1980. Ó wá ń dá ìsọfúnni padà gba inú ẹ̀fúùfù oòrùn àti ibi àgbègbè agbára òòfà inú gbalasa òfuurufú. Ilé iṣẹ́ Ìfòlófuurufú àti Ìṣàkóso Gbalasa Òfuurufú ti Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn irin iṣẹ́ rẹ̀ lè jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ti ọkọ̀ àgbéresánmà èyíkéyìí tí ó lè mọ ààlà tí ó wà láàárín òpin agbára òòfà inú Oòrùn àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn àlàfo tó wà láàárín àwọn ìràwọ̀.”
Àwọn Ọmọ Tí A Kò Fi Orúkọ Wọn Sílẹ̀
Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Ó lè jẹ́ ìdámẹ́ta nínú gbogbo àwọn ọmọ ni a kò fi ọjọ́ ìbí wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, tí a wá fi wọ́n sípò ìgbàgbé lábẹ́ òfin tó lè túmọ̀ sí pípàdánù àǹfààní ẹ̀kọ́ ìwé àti ètò ìlera.” Fífi ọjọ́ ìbí sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba lọ sílẹ̀ gan-an ní gúúsù Sàhárà Áfíríkà àti ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà, bí Cambodia, Íńdíà, Myanmar, àti Vietnam. Carol Bellamy tí ó jẹ́ olùdarí àgbà ti Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé, ilé iṣẹ́ tó bójútó ètò náà jákèjádò ayé, sọ pé: “Àìní ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí kí a máà bí ènìyàn rárá.” Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni ó béèrè fún fífi ọjọ́ ìbí sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba kí ọmọ kan tó lè rí ìtọ́jú gbà ní ilé ìwòsàn tàbí kí ó tó lè forúkọ sílẹ̀ ní ilé iwé, ó sì ṣeé ṣe kí a fagbára mú àwọn ọmọ tí kò bá ní ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí láti darapọ̀ mọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ to ń ṣiṣẹ́ gbowó tàbí kí á kó wọn nífà nípa lílò wọ́n fún iṣẹ́ aṣẹ́wó. Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Ipò òṣì nìkan kọ́ ló ń pinnu iye ìforúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, ìròyìn tí a rí fi hàn pé, iye ìforúkọsílẹ̀ ga ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní Látìn Amẹ́ríkà, àáríngbùngbùn Éṣíà àti Àríwá Áfíríkà.”