ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 12/8 ojú ìwé 32
  • Ọkùnrin Aláìgbọlọ́rungbọ́ Rí Ìdáhùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọkùnrin Aláìgbọlọ́rungbọ́ Rí Ìdáhùn
  • Jí!—1999
Jí!—1999
g99 12/8 ojú ìwé 32

Ọkùnrin Aláìgbọlọ́rungbọ́ Rí Ìdáhùn

“PABANBARÌ ni àwọn àpilẹ̀kọ tó ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn yín, Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àwọn ìtẹ̀jáde yín tó dé gbẹ̀yìn kò ṣeé gbé jùúlẹ̀! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè ni wọ́n ń dáhùn, wọ́n sì ń fini lọ́kàn balẹ̀.”

Ọ̀kan lára àwọn òǹkàwé wa láti gúúsù Íńdíà ló sọ bẹ́ẹ̀. Inú ẹ̀sìn Híńdù ni wọ́n bí i sí, ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ sọ ọ́ di aláìgbọlọ́rungbọ́. Ó sọ pé: “Mi ò mọ ète ìgbésí ayé. Àbá èrò orí Darwin nípa ẹfolúṣọ̀n kò nítumọ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ìbéèrè kan fi ń dààmú mi, àwọn ìbéèrè bíi Ta ni Ọlọ́run? Kí ló dé táyé fi bà jẹ́ báyìí? Ibo là ń lọ lẹ́yìn ikú? Ṣé lóòótọ́ làwọn ẹ̀mí burúkú wà?”

Nígbà tí ọkùnrin òǹkàwé yìí rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ̀ nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, ó wá san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn méjèèjì, ó fi ẹ̀bùn àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn ránṣẹ́ sí arábìnrin rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún àwọn èèyàn tó bá bá pàdé ní àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí. Nítorí pé fọ́tò àti àwòrán ló ń yà, ó mọrírì àwọn àwòrán inú ìwé ìròyìn wọ̀nyí, “àwọn àwòrán tí ń sọ̀rọ̀.” Nípa kíka ìwé ìròyìn àtàtà wọ̀nyí, ìwọ náà lè di ọ̀kan lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé tó ti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọn, tí wọ́n sì ti rí ìfọ̀kànbalẹ̀.

Bí o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run àti ète rẹ̀ fún wa, inú wa yóò dùn láti sọ fún ẹ nípa bí o ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ tó gbajúmọ̀ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? gbà. Sáà ti kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí a kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, gbà.

Sọ èdè tí o fẹ́.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

IWÁJÚ ÌWÉ, ojú ìwé 2 sí 9 àti 32: Fọ́tò Einstein: U.S. National Archives; Model-T Ford: Látinú Collections of Henry Ford Museum & Greenfield Village; Ilọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé: Dorothea Lange, FSA Collection, Library of Congress; Nicholas Kejì àti ìdílé rẹ̀: Látinú ìwé náà, Liberty’s Victorious Conflict; Ilé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè: Fọ́tò U.S. National Archives; Churchill: The Trustees of the Imperial War Museum (MH 26392); Ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń jagun: Fọ́tò U.S. Navy; Àwọn bọ́ǹbù runlérùnnà: Fọ́tò USAF; Gandhi: Culver Pictures; Èèyàn tó wà lórí òṣùpá: Fọ́tò NASA; Bíba afẹ́fẹ́ jẹ́: Godo-Foto; Mao Tse-tung: Culver Pictures; Àwọn ọmọdé nílẹ̀ Áfíríkà: Fọ́tò FAO/F. Botts; Ère Lenin: Juraatis/Sipa Press; Ọkọ̀ agbéni-renú-òṣùpá: Fọ́tò NASA; Archduke Ferdinand: Látinú ìwé náà, The War of the Nations; Lenin: Musée d’Histoire Contemporaine-BDIC

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́