Wíwo Ayé
Wọn Ò Forúkọ Ẹ̀sìn Jesuit Sílẹ̀ ní Rọ́ṣíà
Iléeṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ní Rọ́ṣíà ti sọ pé àwọn ò fọwọ́ sí ìwé tí Ẹgbẹ́ Àwọn Ọmọ Jésù kọ, tí wọ́n fi ń béèrè pé kí wọ́n forúkọ ẹgbẹ́ àwọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètò ẹ̀sìn tó dá dúró, ìwé ìròyìn National Catholic Reporter ló gbé ìròyìn yìí jáde. Ọdún 1540 ni wọ́n dá Ẹgbẹ́ Àwọn Ọmọ Jésù, táwọn èèyàn mọ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit, sílẹ̀. Lábẹ́ òfin tuntun tó de ẹ̀sìn nílẹ̀ Rọ́ṣíà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀sìn ni ìjọba sọ pé kí wọ́n wá forúkọ sílẹ̀, kí ìjọba tó fún wọn láṣẹ lábẹ́ òfin. Àwọn ẹgbẹ́ tí ìjọba ò bá forúkọ wọn sílẹ̀ kò lè tẹ ìwé ẹ̀sìn jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè pín in kiri, wọn ò lè mú ọmọ ilẹ̀ òkèèrè wọ̀lú láti wá lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè kọ́ àwọn ibùdó ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. April 29, 1999, ni wọ́n forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè yẹn.
Gbígbẹ̀mí Ara Ẹni Ti Lékenkà ní Japan
Ìwé ìròyìn The Daily Yomiuri sọ pé ní Japan, iye àwọn èèyàn tó fọwọ́ ara wọn pa ara wọn lọ́dún 1998 pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Gẹ́gẹ́ bí Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ilẹ̀ Japan ti wí, 32,863 èèyàn ló pa ara wọn lọ́dún 1998—iye yìí jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta àwọn tí jàǹbá ọkọ̀ pa ní Japan. Ohun pàtàkì tó jẹ́ kó pọ̀ tó yẹn ni ìṣòro ìṣúnná owó tí àìríṣẹ́ṣe fà, èyí tó bá orílẹ̀-èdè náà fínra lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ náà dẹnu kọlẹ̀. Gbígbẹ̀mí ara ẹni ló wà nípò kẹfà lára ikú tó ń pa àwọn èèyàn ní Japan.
Afẹ́fẹ́ Panipani Gbòde Kan
Iléeṣẹ́ ìròyìn táa mọ̀ sí Reuters sọ pé: “Ohun ìrìnnà ló gbawájú lára àwọn ohun tó túbọ̀ ń tú nǹkan burúkú dà sáfẹ́fẹ́ ní Yúróòpù, iye àwọn èèyàn tí afẹ́fẹ́ burúkú yìí ń pa láwọn orílẹ̀-èdè kan pọ̀ ju iye tó ń kú nínú jàǹbá [ọkọ̀].” Ìwádìí kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe fi hàn pé ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún èèyàn ní Austria, ilẹ̀ Faransé, àti Switzerland ló ń kú láìtọ́jọ́ lọ́dọọdún nítorí àrùn tó jẹ mọ́ èémí tàbí ti ọkàn-àyà tí afẹ́fẹ́ burúkú ń fà. Ìròyìn ọ̀tọ̀ kan fi hàn pé, látinú nǹkan bí ìlú mẹ́rìndínlógójì ní Íńdíà, ó tó àádọ́fà èèyàn tó ń kú láìtọ́jọ́ lójoojúmọ́ nítorí mímí afẹ́fẹ́ burúkú símú.
Ìsọfúnni Inú Kọ̀ǹpútà Kì Í Pẹ́ Sọ Nù
Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa kọ̀ǹpútà fi ń sọ pé fífi ìsọfúnni pa mọ́ sínú kọ̀ǹpútà fini lọ́kàn balẹ̀ ju kíkọ ọ́ sórí bébà lọ. Àmọ́ o, àwọn amójútó ilé ìkàwé àtàwọn ibi ìkósọfúnnisí ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ o. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “À ń pàdánù ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni pàtàkì nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìtàn nítorí pé ó ń bà jẹ́ níbi táa kó o sí tàbí nítorí pé inú ẹ̀rọ táa kó o sí kò bóde mu mọ́.” Àwọn ibi tí a ń kó ìsọfúnni sí nínú kọ̀ǹpútà kò fẹ́ ooru, ọ̀rinrin, tàbí kí afẹ́fẹ́ tàbí agbára òòfà tó gba inú afẹ́fẹ́ wá máa wọlé. Ìwé ìròyìn náà sọ pé bí ìsọfúnni náà ṣe máa pẹ́ sí, tún sinmi lórí ipò tí kásẹ́ẹ̀tì táa ká ìsọfúnni náà sí wà, ó sì lè máà pẹ́ ju ọdún mẹ́wàá kó tó bẹ̀rẹ̀ sí bà jẹ́. Ìṣòro míì tó tún ń kojú àwọn tó ń tọ́jú ìsọfúnni inú kọ̀ǹpútà pa mọ́ ni bí ìmọ̀ nípa kọ̀ǹpútà ti ń fojoojúmọ́ yí padà. Àwọn ẹ̀yà inú ẹ̀rọ táa fi ń tọ́jú ìsọfúnni pa mọ́ máa ń yí padà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé kíákíá ni ẹ̀rọ wọ̀nyí máa ń di kọ̀ǹdẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Abby Smith, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ibi Ìkàwé àti Orísun Ìsọfúnni, sọ pé: “Àfàìmọ̀ kí ìsọfúnni wọ̀nyí má sọ nù gbé, àfi táa bá ń tọ́jú àwọn ẹ̀rọ àti kọ̀ǹpútà àtijọ́ tó ṣeé lò pẹ̀lú àwọn kásẹ́ẹ̀tì wọ̀nyí táa fi ìsọfúnni pa mọ́ sí.”
Iye Èèyàn Íńdíà Ti Lé ní Bílíọ̀nù Kan
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ń Bójú Tó Ìpíndọ́gba Iye Ènìyàn ti wí, àwọn èèyàn tó wà ní Íńdíà ti lé ní bílíọ̀nù kan ní August 1999. Ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn tó wà ní Íńdíà báyìí ló wà níbẹ̀ léyìí tí kò ju àádọ́ta ọdún sẹ́yìn. Báwọn èèyàn ibẹ̀ bá ń pọ̀ sí i ní ìpín kan àtààbọ̀ lórí ọgọ́rùn-ún lọ́dọọdún, bó ṣe rí báyìí, nígbà tó bá máa fi tó ogójì ọdún, iye èèyàn tó wà ní Íńdíà á ti pọ̀ ju ti China lọ, á wá di orílẹ̀-èdè téèyàn ti pọ̀ jù lọ lágbàáyé. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Inú Íńdíà àti China ni èyí tó lé ní ìdá mẹ́ta gbogbo èèyàn tó wà láyé ń gbé báyìí.” Ní ohun tó dín sí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, ni ìwọ̀n gígùn ẹ̀mí àwọn ará Íńdíà ti ròkè, láti ọdún mọ́kàndínlógójì dé ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta.
Iye Ìgbéyàwó Ń Lọọlẹ̀ ní Amẹ́ríkà
Ìwé ìròyìn The Washington Post gbé ìròyìn kan síbi tó ń kó ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìròyìn ọ̀hún dá lé ìwádìí kan tí Yunifásítì Rutgers ṣe, tí wọ́n pè ní Ìwádìí Lórí Ètò Ìgbéyàwó Lórílẹ̀-Èdè Wa, èyí tó fi hàn pé iye àwọn tó ń ṣègbéyàwó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti lọọlẹ̀ pátápátá, kò lọọlẹ̀ tó báyìí rí nínú ìtàn. Ìwádìí náà tún fi hàn pé kété lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn òbí méjèèjì tó lọmọ ló ń tọ́ ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí wọ́n bí lórílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ lónìí iye yẹn ti lọọlẹ̀, ó ti di ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún. Ìròyìn náà sọ pé: “Ìpíndọ́gba iye ọ̀dọ́bìnrin tó sọ pé ‘ìgbésí ayé tó bójú mu’ ni bíbímọ láìsí nílé ọkọ ti pọ̀ sí i látorí ìpín mẹ́tàlélọ́gbọ̀n dórí ìpín mẹ́tàléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ogún ọdún sẹ́yìn.” Abájọ tí ìròyìn náà fi sọ pé: “Ètò ìgbéyàwó ti wọ wàhálà ńlá”!
Ẹ̀kọ́ Ti Kàgbákò ní Áfíríkà
Iléeṣẹ́ ìròyìn tí wọ́n ń pè ní All Africa News Agency sọ pé, lágbègbè aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà, ó lé ní ogójì mílíọ̀nù àwọn ọmọ tó ti tó iléèwé lọ tí kì í lọ iléèwé. Onírúurú ìṣòro ló ti dojú kọ ètò ẹ̀kọ́ lágbègbè yẹn. Fún àpẹẹrẹ, nítorí ìṣòro ìṣúnná owó, ọ̀pọ̀ iléèwé ni kò lómi rárá, tó sì jẹ́ pé ilé ìgbẹ́ mélòó kan ni wọ́n ní, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ níkankan rárá. Ìwé ò tó, aláàbọ̀ ẹ̀kọ́ ló sì pọ̀ jù lára àwọn tíṣà. Láfikún sí ìṣòro ìṣúnná owó, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin ló ń gboyún, ìdí sì rèé tí ọ̀pọ̀ nínú wọn fi ń fi iléèwé sílẹ̀. Àrùn éèdì pẹ̀lú ti ṣàkóbá fún iye àwọn tó ń lọ iléèwé. Iléeṣẹ́ Africa News sọ pé: “Àwọn ọmọ pínníṣín tó ti bẹ̀rẹ̀ ìbálòpọ̀ takọtabo láàárọ̀ ọjọ́ wọn ti mú kí iye àwọn ọ̀dọ́langba tí àrùn éèdì ń ràn pọ̀ sí i.” Nígbà míì, àwọn ọmọbìnrin tí kò tíì kó àrùn éèdì ni wọ́n máa ń sọ pé kó dúró sílé kó máa tọ́jú àwọn ìbátan tó ti kó àrùn náà. Dókítà Edward Fiske, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀, tó tún ń ṣiṣẹ́ fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀, sọ pé: “Láìlọ iléèwé, ọjọ́ iwájú ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà kò lè lójú.”
Òkú Àtọdúnmọ́dún Ní Ìka Ẹsẹ̀ Tó Jẹ́ Àtọwọ́dá
Ìwé ìròyìn The Sunday Times ti London sọ pé: “Ìka ẹsẹ̀ tó jẹ́ àtọwọ́dá ń bẹ lára òkú kan táwọn ará Íjíbítì ìgbàanì kùn lọ́ṣẹ, ó sì jọ pé onítọ̀hún lo ọmọ ìkasẹ̀ yẹn nígbà tó wà láyé, kó tó di pé wọ́n sin ín ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn.” Dókítà Nicholas Reeves, sọ pé aṣọ ọ̀gbọ̀ ni wọ́n fi ṣe ọmọ ìkasẹ̀ àtọwọ́dá náà, ohun tó sì wà nínú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ni àtè láti ara ẹranko àti sìmẹ́ǹtì, ó sì jẹ́ “àgbà iṣẹ́, tó rí rèǹtè-rente, iṣẹ́ tó fi làákàyè hàn, tó dúró sán-ún, ó sì dájú pé wọ́n dìídì ṣe é fún ẹsẹ̀ yẹn ni.” Wọ́n fi kinní kan tó jọ awọ ara bo ọmọ ìkasẹ̀ náà, ó sì tún ní èékánná tó ṣe rẹ́gí. Ọ̀wọ́ ihò mẹ́jọ ni wọ́n dá lu sára ọmọ ìkasẹ̀ náà láti fi so ó mọ́ ẹsẹ̀. Wọ́n to ihò náà ní ìlà ibi tí okùn sálúbàtà yóò gbà, tó fi jẹ́ pé téèyàn bá lo ọmọ ìkasẹ̀ náà, tó sì wá wọ sálúbàtà tí wọ́n de okùn rẹ̀ lọ́nà tó fi rí bíi lẹ́tà Y, ńṣe ni okùn bàtà náà á bo àwọn ihò ara ọmọ ìkasẹ̀ náà.
Rírí Ẹ̀fọ́rí He Lẹ́yìn Lílo Oògùn Ara Ríro!
Àwọn tó bá ń lo oògùn ẹ̀fọ́rí lẹ́ẹ̀mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́sẹ̀ lè ní ẹ̀fọ́rí tí àṣìlò oògùn ń fà. A gbọ́ pé irú ẹ̀fọ́rí yìí máa ń dààmú nǹkan bí èèyàn kan nínú àádọ́ta èèyàn, wọ́n sì sọ pé àwọn oògùn wẹ́ẹ́wẹ̀ẹ̀wẹ́ bí aspirin, àtàwọn oògùn ara ríro míì ló ń fà á. Lẹ́yìn tóògùn wọ̀nyí bá pàrora tán, wọ́n tún lè fa ẹ̀fọ́rí tí aláìsàn náà lè fi èèṣì kà sí ẹ̀fọ́rí gidi tàbí túúlu. Onítọ̀hún á wá túbọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kó oògùn ara ríro mì, ẹ̀fọ́rí gidi á wá padà dé. Dókítà Tim Steiner, tó ń ṣiṣẹ́ ní Imperial College, ní London, ṣàlàyé pé “tẹ́nì kan bá wà tó ń kígbe ẹ̀fọ́rí ṣáá lójoojúmọ́, ẹ jẹ́ ká gbà pé ẹ̀fọ́rí tí àṣìlò oògùn ń fà ló ń dà á láàmú.” Ó tún sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí táa ti ṣàwárí ìṣòro yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ dókítà ìdílé ni kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀fọ́rí yìí, fún ìdí yìí, ṣe ni wọ́n á tún sọ pé kéèyàn lọ máa lo oògùn ara ríro tó tún lágbára sí i, nígbà tó jẹ́ pé ohun téèyàn ì bá ṣe ni pé kó ṣíwọ́ lílo oògùn wọ̀nyẹn, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Sunday Telegraph ti London ti wí.
Ìtọ́jú Ahọ́n
Ìròyìn kan látinú ìwé ìròyìn Prince George Citizen sọ pé, kòkòrò bakitéríà tó ń sá pa mọ́ sábẹ́ ahọ́n rẹ lè máa run imí ọjọ́, òórùn burúkú sì lèyí jẹ́. Ìròyìn náà tẹ̀ síwájú pé: “Àyíká tó gbẹ fúrúfúrú, tí kò ní afẹ́fẹ́ ọ́síjìn ni bakitéríà ń fẹ́, ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ní àwọn ibi kọ́lọ́fín àtàwọn ibi tó jin kòtò, níbi tí afẹ́fẹ́ táa ń fi ránṣẹ́ sínú ẹ̀dọ̀fóró kì í dé.” Fífọyín àti fífomi yọnu dáa, ṣùgbọ́n nǹkan bí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn bakitéríà wọ̀nyí ni fífọyín lè mú kúrò. Allan Grove, tó jẹ́ dókítà eyín, gbà gbọ́ pé híha ahọ́n, tó jẹ́ àṣà àwọn ará Yúróòpù ìgbàanì, ni “ohun pàtàkì kan ṣoṣo tóo lè ṣe kí òórùn burúkú má bàa máa tẹnu rẹ jáde.” Ìwé ìròyìn Citizen sọ pé lílo ohun pẹlẹbẹ táa fi ike ṣe “dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ju fífi búrọ́ọ̀ṣì eyín fọ ahọ́n, kó máa pọ́n ṣẹ̀ẹ̀ bí osùn.”
Ojú Tuntun Ti Bẹ̀rẹ̀ sí Wo Àgbáálá Ayé
Awò awọ̀nà-jíjìn kan, tórúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Gemini North, tó wà lórí òkè Mauna Kea, ní Hawaii, la ojú rẹ̀ wẹ̀ẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wo àgbáálá ayé ní June 1999. Ìwé ìròyìn Independent ti London, sọ pé dígí rẹ̀ tó fi ń fa ìmọ́lẹ̀ mọ́ra, fẹ̀ ju mítà mẹ́jọ lọ, yóò sì jẹ́ káwọn onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà rí àwọn nǹkan tíntìntín tó wà ní ìsálú ọ̀run. Awò Gemini North yìí, àti òmíì tí wọ́n ń pè ní Hubble, tó wà lójúde òfuurufú, mú kó ṣeé ṣe fáwọn onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà láti rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ “wẹ̀yìn wò.” Àǹfààní tí Hubble ní ni pé ojúde òfuurufú ló wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ilẹ̀ ni Gemini wà ní tiẹ̀, ó ní àwọn ẹ̀rọ tó ń lo kọ̀ǹpútà, tó ń mú àwọn nǹkan wíríwírí inú afẹ́fẹ́ tó lè dí i lójú kúrò, ìdí nìyí tí àwòrán tó ń gbé jáde fi ṣe kedere bíi ti Hubble—ìyẹn tí tiẹ̀ ò bá ṣe kedere ju ti Hubble lọ pàápàá.