ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 4/8 ojú ìwé 32
  • Àṣé Ẹnì Kan Ń wò Wọ́n

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àṣé Ẹnì Kan Ń wò Wọ́n
  • Jí!—2002
Jí!—2002
g02 4/8 ojú ìwé 32

Àṣé Ẹnì Kan Ń wò Wọ́n

ÀWỌN ọ̀dọ́langba méjì kan yà láti jẹun àárọ̀ ní ilé àrójẹ kan nílùú kékeré kan ní Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, kí wọ́n tó jẹun, wọ́n tẹrí ba wọ́n sì gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.

Nígbà tó yá, obìnrin kan tó ti ń kíyè sí wọn wá síbi tábìlì tí wọ́n ti ń jẹun ó sì mú ìwé tí wọ́n kọ iye owó táwọn ọmọ náà máa san fún oúnjẹ tí wọ́n rà sí. Obìnrin náà wá sọ fún wọn pé: “Nínú ayé tá a ti ń gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà láabi táwọn ọ̀dọ́ ń hù, ó yà mí lẹ́nu láti rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì yìí tí wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n fẹ́ jẹun. Mo máa sanwó oúnjẹ yín.”

Ọ̀rọ̀ náà ya àwọn ọmọ méjì yìí lẹ́nu púpọ̀, àmọ́ wọ́n ṣojú fúrú wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ obìnrin náà. Wọ́n wá rò ó lẹ́yìn náà pé ó yẹ káwọn jẹ́ kí obìnrin náà mọ̀ pé kì í kàn án ṣe Ọlọ́run èyíkéyìí làwọn ń gbàdúrà sí. Ni ọ̀kan lára wọn bá lọ bá obìnrin náà, ó sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó wá sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn.

Àṣà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìdílé wọn. Àwọn òbí àwọn ọmọdékùnrin wọ̀nyí ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tí ìdílé náà ti kà ni Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Orí mọ́kàndínlógún ni ìwé yìí ní. Ọ̀kan lára wọn dá lórí ọ̀rọ̀ àdúrà, àkọlé rẹ̀ ni “Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọ́run.”

O lè rí ẹ̀dà kan gbà lára ìwé olójú ewé 192 tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí tó o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́