Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
July 8, 2003
Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Ǹjẹ́ A Lè Rí Nǹkan Ṣe Sí I?
Ọmọ kékeré tí ikú yẹ̀ lórí rẹ̀ yìí ń sunkún lẹ́yìn ètò ìsìnkú àwọn ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́jọ tí ẹnì kan pa ní ìlú Ikeda, lórílẹ̀-èdè Japan. Káàkiri ayé ni àwọn ìwà ìkà tó burú jáì ti ń ṣẹlẹ̀. Kí lohun tó ń sún àwọn èèyàn láti máa hu irú àwọn ìwà tó burú bògìrì bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ òpin tiẹ̀ lè dé bá ìṣòro yìí?
3 Àwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Kí Ló Dé Tí Wọ́n Túbọ̀ Ń Peléke Sí I?
5 Kí Ló Dé Táwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Fi Wọ́pọ̀ Tó Báyìí?
10 Ǹjẹ́ Ohun Kan Wà Tó Lè Fòpin Sí Ìwà Ìkà Bíburú jáì?
12 Ǹjẹ́ O Mọ̀?
13 Àwọn Òwe Ẹ̀yà Akan Òwe Tó Ń Gbé Àṣà Ìbílẹ̀ Lárugẹ
30 Wíwo Ayé
32 Ǹjẹ́ Ọmọ Aráyé Ò Ní Pa Ilẹ̀ Ayé Wa Rírẹwà Yìí Run Báyìí?
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà Á Nígbà Tí Àjálù Bá Wáyé? 16
Àwọn àjálù òjijì lè mú kí àwọn ìbéèrè tó ṣòro gan-an láti dáhùn nígbèésí ayé bẹ̀rẹ̀ sí í jà gùdù lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí ọ̀nà tó yá kánkán tó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀ láti rí àwọn ìdáhùn ṣíṣekókó.
Bí A Ṣe Pa Òùngbẹ Tẹ̀mí Tó Ń Gbẹ Mí 24
Kà nípa obìnrin kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àmọ́ tí ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ ohun tó ń wá nípa tẹ̀mí—àyàfi ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, èyí tó wá yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
FỌ́TÒ AFP/Toshifumi Kitamura