Kí Lo Lè Ṣe Bí Ọmọ Rẹ Bá Ń ké Ṣáá?
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ KÁNÁDÀ
DÓKÍTÀ kín ohun tí ìyá ọmọ náà ṣàkíyèsí lẹ́yìn. Irú àìsàn kan báyìí tó máa ń mú kí ikùn roni ló ń yọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà náà, Globe and Mail, sọ pé “bá a bá kó ọmọ mẹ́rin jọ, ọ̀kan nínú wọn” máa ní irú àìsàn yìí. Ọ̀kan lára ohun tó ń fi hàn pé ọmọ kan ní àrùn yìí ni pé á máa ké fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ó kéré tán, nígbà mẹ́ta lọ́sẹ̀. Kí ni òbí kan tí irú àìsàn yìí ń da ọmọ rẹ̀ láàmú lè ṣe? Àwọn onímọ̀ nípa ìtọ́jú àrùn àwọn ọmọdé sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà tí àìsàn náà bá ti bẹ̀rẹ̀ báyìí, ńṣe làwọn òbí àtàwọn ọmọ wulẹ̀ ní láti ṣe sùúrù tá a fi lọ fúnra ẹ̀. Báwo ni wọ́n á wá ṣe dúró pẹ́ tó?
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ṣe ìwádìí kan lórílẹ̀-èdè Kánádà nínú èyí tí wọ́n ti kíyè sí àwọn abiyamọtí àìsàn yìí ń ṣe àwọn ọmọ wọn. Ìwádìí náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé nínú ọgọ́rùn-ún irú àwọn àìsàn bẹ́ẹ̀, márùndínláàádọ́rùn-ún ló ti wábi gbà nígbà táwọn ọmọ náà fi máa pé ọmọ oṣù mẹ́ta. Ìwádìí tó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Dókítà Tammy Clifford, olùdarí ìgbóguntàrùn ní Ilé Ìwòsàn Àwọn Ọmọ Wẹ́wẹ́ Tó Wà Lábẹ́ Àsíá Ilé Iṣẹ́ Ìwádìí ní Ìlà Oòrùn Ìlú Ontario, tún fi hàn pé àwọn ìyá tí àìsàn tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ń ṣe ọmọ wọn kì í tìtorí ẹ̀ ní ìṣòro tó jẹ mọ́ ọpọlọ. Dókítà Clifford sọ pé: “Bó bá fi máa pé oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìbímọ, wọ́n á ti dà bí àwọn Ìyá àbúrò tírú àìsàn bẹ́ẹ̀ ò ṣọmọ tiwọn. Ńṣe ló máa dà bí ẹni pé wọn ò tiẹ̀ rántí ẹ̀ mọ́, lẹ́yìn tí igbe kíké náà bá ti dúró.”
Ìwé ìròyìn Globe sọ pé ìwádìí tuntun tí Dókítà Clifford àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀ jáde yìí “ti jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i láfikún sí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tá a ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àìsàn tí ń mú inú roni nítorí pé ó ti fi hàn pé apá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ọmọ tí àìsàn náà ń ṣe pín sí, ìyẹn ni àwọn tí àìsàn náà á ṣe, tá sì fi sílẹ̀ láàárín nǹkan bí oṣù mẹ́ta; àwọn tó ń ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù láìdáwọ́dúró; àtàwọn kéréje kan tí àìsàn náà ò tètè ṣe, àfìgbà tó bá di ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bí wọn.” Wọ́n tún ti ṣe ìwádìí mìíràn láti kíyè sí bí àwọn ọmọ tí àìsàn náà ń ṣe ṣe ń dàgbà, ohun tí wọ́n kíyè sí nípa àwọn ọmọ tí àìsàn náà máa ń ṣe níwọ̀nba oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bí wọn kọyọyọ.
Wọ́n ti fìgbà kan gbà gbọ́ pé bí àìsàn tó máa ń ṣe àwọn ọmọ tí wọ́n ń gbò jìgìjìgì bá ń da ọmọ kan láàmú, a jẹ́ pé igbe àkéèdabọ̀ ló fà á. Ṣùgbọ́n, bí ìwé ìròyìn Globe ṣe sọ, “igbe kíké ò lè pa ọmọdé lára, àmọ́, gbígbo ọmọdé jìgìjìgì, àní fún àkókò kúkúrú pàápàá, lè ba ètò ìṣàn ara ọmọ náà jẹ́ títí gbére, tàbí kó tiẹ̀ kú.”
Òmíràn sì tún ni pé, kí ọmọdé máa ké, àní láìdábọ̀ pàápàá, ní oore tó ń ṣe. Ìwé ìròyìn Globe sọ pé: “Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tí wọ́n máa ń ké ṣáá máa ń rí àfiyèsí tó pọ̀ gan-an gbà látọ̀dọ̀ àwọn tó ń tọ́jú wọn. Wọ́n máa ń gbádùn ìfarakanra púpọ̀ sí i, àwọn èèyàn túbọ̀ máa ń rẹ́rìn-ín sí wọn, wọn kì í yé sọ̀rọ̀ sí wọn, ìgbà gbogbo ni wọ́n sì máa ń gbé wọn mọ́ra.”