ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 5/8 ojú ìwé 31
  • Mi Ò Jẹ́ Mu Sìgá!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mi Ò Jẹ́ Mu Sìgá!
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Inú Rere Máa Ń Yí Ìwà Kíkorò Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Jí!—2004
g04 5/8 ojú ìwé 31

Mi Ò Jẹ́ Mu Sìgá!

ÀKÒRÍ ọ̀rọ̀ yẹn ni wọ́n ní kí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó kópa nínú ìdíje ìwé kíkọ tó wáyé jákèjádò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ ọ̀rọ̀ lé lórí. Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn ti Ìpínlẹ̀ Missouri (MSMA) ló ṣonígbọ̀wọ́ ìdíje náà. Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó kópa nínú ìdíje ìwé kíkọ náà, láti ilé ìwé méjìlélógójì, tó nǹkan bí ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta ó dín márùn-ún [675]. Breanna, ọmọ ọdún méjìlá, ló gbégbá orókè, wọ́n sì gbé ewì tó kọ jáde nínú ìwé ìròyìn àjọ MSMA náà, Missouri Medicine. Breanna tún láǹfààní láti ka ewì náà níwájú àwọn èèyàn tó wá síbi àpéjọ ọlọ́dọọdún tí àjọ MSMA ṣe. Kí Breanna tó ka ewì náà, ó kọ́kọ́ sọ fún gbogbo àwọn tó wà níkàlẹ̀ pé:

“Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú ìwé ìròyìn Jí! ni mo sì ti rí gbogbo òkodoro ọ̀rọ̀ tó wà nínú ewì tí mo kọ. Kódà, lára àkọlé tó wà lẹ́yìn ìtẹ̀jáde yìí ni mo ti fa ọ̀rọ̀ tí mo kọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlà tó wù mí jù lọ nínú ewì náà yọ. Àwòrán agbárí tí wọ́n gbé sìgá há lẹ́nu wà níbẹ̀, àkọlé náà sì kà pé: ‘Ikú Fún Títà.’ Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Jí! ti ń tẹ ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ tó ń sọ nípa ewu tó wà nínú sìgá mímu.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá họ́ọ̀ sìgá mímu tàbí tábà. Wọ́n gbà gbọ́ pé mímọ̀ọ́mọ̀ lo ohunkóhun tó bá lè kó ẹ̀gbin bá ara kò fọ̀wọ̀ hàn fún ẹ̀bùn ìwàláàyè kò sì ka Ẹlẹ́dàá kún ohunkóhun. (Ìṣe 17:24, 25) Nítorí náà, wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìṣílétí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.”—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Bíi táwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí yòókù, Breanna ń sapá láti fi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò. Dájúdájú, irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú inú Ẹlẹ́dàá wọn dùn.—Òwe 27:11.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Breanna (ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni báyìí) tó gbé ewì rẹ̀ dání

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́