Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà
Lẹ́yìn tí obìnrin kan ti yẹ ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, tá a tẹ̀ jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí wò, ó kọ lẹ́tà nípa ìwé tí wọ́n yàwòrán àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn sí yìí pé: “Ohun èlò àgbàyanu tí mo nílò gan-an nìyí. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ bí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ilẹ̀, àwọn èèyàn àti ipò àwọn nǹkan ṣe rí gan-an ni.”
Ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 36, tí wọ́n yàwòrán rírẹwà sí yìí, á ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti fojú inú yàwòrán àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì. Obìnrin náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Rírí tí mo rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín gíga ibi tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì sí àtàwọn ilẹ̀ tó yí i ká ràn mí lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa ìjọsìn Jèhófà ‘tá a gbé ga.’ Ìrànlọ́wọ́ ńlá gbáà ló jẹ́ láti rí ibi táwọn ìlú ààbò àtàwọn ibòmíì tí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti Gíríìkì mẹ́nu kàn wà. Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí lo ìwé fífanimọ́ra yìí láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì nínú Bíbélì.”
Ní ìparí lẹ́tà rẹ̀, obìnrin náà sọ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni mà á máa lo ẹ̀bùn rírẹwà yìí.”
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé tá a pè ní Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.