ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 7/8 ojú ìwé 30-31
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Awalẹ̀pìtàn Ń Yọ́ Yìnyín Dídì
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Atatẹ́tẹ́
  • Ooru Gbígbóná Bì Lu Orílẹ̀-Èdè Faransé
  • Àárẹ̀ Ọkàn Ń Ṣàwọn Ọkùnrin
  • Báwo Làwọn Àlùfáà Kátólíìkì Ṣe Mọ Bíbélì Tó?
  • Àwọn Ìṣòro Tí Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Máa Ń Fà
  • “Òkun Òkú Ti Ń Gbẹ O”
  • Ṣíṣàwárí Àwọn Nǹkan Tó Ń Fa Ìsoríkọ́
    Jí!—2001
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
    Jí!—2017
  • Kí Ló Burú Nínú Tẹ́tẹ́ Títa?
    Jí!—2002
  • Báa Ṣe Lè Dá Àwọn Àmì Ìsoríkọ́ Mọ̀
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 7/8 ojú ìwé 30-31

Wíwo Ayé

Àwọn Awalẹ̀pìtàn Ń Yọ́ Yìnyín Dídì

Ìwé ìròyìn èdè Jámánì náà, Der Spiegel, sọ pé yíyọ́ yìnyín dídì èyí tó ń mú kí àwọn nǹkan tó ti fara sin sínú yìnyín látọjọ́ pípẹ́ máa fara hàn ń fa àwọn òpìtàn mọ́ra gan-an ni. Lọ́dún 1999, nígbà tí wọ́n yọ́ irú yìnyín dídì kan bẹ́ẹ̀ lórí Àwọn Òkè Olókùúta ti Orílẹ̀-èdè Kánádà, wọ́n rí ọkùnrin ará Íńdíà kan tó ti kú láti àádọ́ta lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún [550] sẹ́yìn. Àmọ́, níbi àgbájọ àwọn òkè ńlá Alps ni wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn nǹkan tó fara sin sínú yìnyín. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni wọ́n rí òkú ọkùnrin kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ó já ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ àtọmọ àlè tíyẹn bí fún un sílẹ̀ lọ́dún 1949. Ńṣe ló há sáàárín yìnyín dídì, wọ́n sì bá òrùka ìgbéyàwó méjì nínú àpò rẹ̀. Bí Harald Stadler, ọ̀gá àwọn awalẹ̀pìtàn tó ń yọ́ yìnyín dídì ní Yunifásítì Innsbruck, ní orílẹ̀-èdè Austria, ṣe sọ, ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ń yán hànhàn fún ni bí wọ́n á ṣe rí àwọn nǹkan tó bá jẹ mọ́ ọ̀gágun Hannibal, gbajúmọ̀ olórí ogún àwọn ara ìlú Kátéèjì ìgbàanì tó kó erin mẹ́tàdínlógójì gba ibi àwọn òkè ńlá Alps kọjá. Ó sọ pé: “Bá a bá rí eegun erin kan ṣoṣo lásán, a jẹ́ pé ọwọ́ ba ohun tá à ń wá nìyẹn.”

Àwọn Ọ̀dọ́ Atatẹ́tẹ́

Nígbà tí ìwé ìròyìn National Post, ti ìlú Toronto ń ṣe àgbéjáde ìròyìn nípa ohun tí Ibùdó Fáwọn Ọ̀dọ́ Atatẹ́tẹ́ Lágbàáyé ní Yunifásítì McGill sọ, ó ṣàlàyé pé: “Ó ju ìdajì lọ lára àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá sí mẹ́tàdínlógún lórílẹ̀-èdè Kánádà tí wọ́n kà sí atatẹ́tẹ́-gbafẹ́, bá a bá sì fi gbogbo wọn dá ọgọ́rùn-ún, ó ṣeé ṣe kí ìdá mẹ́wàá sí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára wọn dojú kọ ìṣòro ńlá nídìí tẹ́tẹ́ títa, wọ́n sì tún ka ìdá mẹ́rin sí mẹ́fà sí àwọn tí ‘tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún.’” Fífún tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ kan ní tíkẹ́ẹ̀tì tí wọ́n á fi ta tẹ́tẹ́ lọ́tìrì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tàbí títa tí wọ́n ń ta tẹ́tẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti kékeré pínníṣín, ló máa ń mú kí ọkàn wọn fà sí i. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé, àbájáde èyí ni pé púpọ̀ sí i lára àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà ti ń lọ́wọ́ sí tẹ́tẹ́ títa báyìí ju bí wọ́n ti ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà mìíràn tó lè di bárakú lọ, irú bíi sìgá mímu tàbí ìjoògùnyó. Àwọn olùkọ́ nírètí pé sísọ àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti dẹ́kun tẹ́tẹ́ títa di apá kan abala ẹ̀kọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lórílẹ̀-èdè Kánádà, lohun gbígbéṣẹ́ tí wọ́n lè ṣe láti borí ìṣòro náà.

Ooru Gbígbóná Bì Lu Orílẹ̀-Èdè Faransé

Ooru tó kọjá sísọ mú ní ilẹ̀ Faransé ní ọjọ́ méjìlá àkọ́kọ́ nínú oṣù August, lọ́dún 2003. Látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í díwọ̀n bójú ọjọ́ ṣe gbóná sí lọ́dún 1873 ní ìlú Paris, kò tíì sí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kankan tó gbóná tó báyẹn rí. Ìwé ìròyìn Terre sauvage, tó ń sọ nípa ìṣẹ̀dá, ròyìn pé: “Bí ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ [ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ojú ọjọ́ nílẹ̀ Faransé] ti sọ, bí ooru yìí ṣe gbóná janjan tó àti bó ṣe wà pẹ́ tó, ré kọjá ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí tó tí ì wáyé rí ní Paris.” Lóṣù méjì péré, èyí tó yọ́ lára yìnyín dídì tó wà níbi òkè Pyrenees, níbi bodè tó wà níhà gúúsù ilẹ̀ Faransé, tó nǹkan bí àádọ́ta mítà [èyí ga tó ilé alájà mẹ́rìnlá]. Onímọ̀ nípa yìnyín dídì, Pierre René sọ pé: “Láàárín àádọ́jọ ọdún, òkìtì yìnyín Pyrenees tó gba ilẹ̀ tó fẹ̀ tó kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n kìlómítà níbùú lóòró yìí ti yọ́ débi pé ibi tó gbà báyìí ò fẹ̀ ju kìlómítà márùn-ún níbùú lóòró lọ.” Ṣé ẹ̀rí lèyí jẹ́ pé ayé ń móoru? Èrò àwọn ògbógi ò tí ì ṣọ̀kan lórí ọ̀ràn náà. Àmọ́ ṣá o, èrò àwọn kan tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ ni pé ó ṣeé ṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ ooru gbígbóná máa wáyé lemọ́lemọ́ sí i láwọn ọdún ẹ̀yìnwá ọ̀la, ohun ìjayà sì nìyẹn jẹ́ látàrí ooru gbígbóná janjan tó wáyé nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tó kọjá. Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] èèyàn tí ooru náà pa nílẹ̀ Faransé.

Àárẹ̀ Ọkàn Ń Ṣàwọn Ọkùnrin

Ìwé ìròyìn The Star, ti ìlú Johannesburg, sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó ń bani nínú jẹ́ jù lọ nípa àárẹ̀ ọkàn ni èrò èké tí ò tíì kásẹ̀ ńlẹ̀ náà pé ‘àìsàn àwọn obìnrin’ ni, kì í sábà ṣe àwọn ‘ọkùnrin gidi’ tí wọ́n bá tó gbangba sùn lọ́yẹ́. Àwọn ògbóǹtagí sọ pé ńṣe ni àárẹ̀ ọkàn fara pamọ́ sáwọn ọkùnrin lára nítorí pé wọn kì í lọ sọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ nípa ìlera tó àwọn obìnrin, ìdí nìyí tí wọn kì í fi í ní àǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro wọn,” ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé “wọn kì í lè ṣàlàyé púpọ̀ nípa másùnmáwo.” Nítorí náà, àmì àrùn tó wọ́pọ̀ lára àwọn obìnrin tó bá ní àárẹ̀ ọkàn làwọn dókítà mọ̀ jù lọ. Ìwé ìròyìn JAMA ṣàlàyé pé: “Àmì tí wọ́n máa ń rí lára àwọn obìnrin tó bá ní àárẹ̀ ọkàn yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí wọ́n máa ń rí lára àwọn ọkùnrin.” Kí ni díẹ̀ lára àwọn àmì tí wọ́n máa ń rí lára àwọn ọkùnrin tó bá ní àárẹ̀ ọkàn? Ìbínú, àárẹ̀, ìkanra, jàgídíjàgan, àìlèṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, àti kí aláàárẹ̀ ọkàn náà máa fẹ́ láti yẹra fáwọn ẹbí àtọ̀rẹ́. Ẹ̀dà ìwé Reader’s Digest tí wọ́n ń tẹ̀ jáde ní Gúúsù Áfíríkà fi kún un pé: “Kì í ṣe ìgbà gbogbo ni ìbínú àti àárẹ̀ ọkàn jọ ń rìn pọ̀, pàápàá nínú ọ̀ràn tàwọn ọkùnrin.”

Báwo Làwọn Àlùfáà Kátólíìkì Ṣe Mọ Bíbélì Tó?

“Báwo làwọn àlùfáà ṣe mọ Bíbélì tó?” Andrea Fontana, tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ àlùfáà àti olùdarí Ọ́fíìsì Bíṣọ́ọ̀bù Tó Ń Rí sí Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Turin, ló béèrè ìbéèrè náà. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwé ìròyìn Kátólíìkì ti orílẹ̀-èdè Ítálì náà, Avvenire, gbé jáde, Fontana sọ pé ìbéèrè náà sọ sí òun lọ́kàn nígbà tí “ọmọ ìjọ kan tọ [òun] wá tó sì béèrè bóyá ṣọ́ọ̀ṣì náà ní ètò kankan fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ní ṣọ́ọ̀ṣì tí ọmọ ìjọ yìí ń lọ, “wọn ò mẹ́nu kan Ìwé Mímọ́ rí.” Ní ìdáhùn sí ìbéèrè ọmọ ìjọ náà, Fontana kọ̀wé pé: “Ní tòótọ́, báwọn [àlùfáà] bá ti jáde nílé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà tí wọ́n lọ, ó bani nínú jẹ́ pé díẹ̀ nínú wọn ló máa ń bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. . . . Nígbà tí ìwàásù ọjọọjọ́ Sunday bá ń lọ lọ́wọ́ nìkan làwọn onígbàgbọ́ sábà máa ń gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ tí wọ́n sì máa ń sún mọ́ ọn.” Ọmọ ìjọ náà sọ pé “òun fúnra òun sún mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kóun tó mọ púpọ̀ sí i.”

Àwọn Ìṣòro Tí Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Máa Ń Fà

Àwọn èèyàn tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ti ń pọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà báyìí o. Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fojú bù ú pé iye àwọn àgbàlagbà tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti pọ̀ sí i látorí ìpín méjìlá ààbọ̀ lórí ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ lọ́dún 1991 dorí ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 2003. Pípọ̀ tàwọn tó ń sanra jọ̀kọ̀tọ̀ tó ń pọ̀ sí i yìí ti nípa lórí okòwò mélòó kan. “Bí ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, tí wọ́n kìlọ̀ fún lóṣù May [2003] pé àwọn èèyàn tó ń gbé ti wúwo ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí wọ́n sì sọ́ fún un pé kó mọ iye àwọn tá á máa gbé, kó lè dín ìwọ̀n ìwúwo náà kù, ilé iṣẹ́ tó ń ta èlò ìsìnkú náà ti ń pa irinṣẹ́ dá, ó sì ń ṣe pósí tó túbọ̀ fẹ̀ sí i nítorí àwọn ara Amẹ́ríkà tí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀,” bí ìwé ìròyìn The New York Times ṣe sọ. Pósí tí wọ́n ń ṣe kì í ju sẹ̀ǹtímítà mọ́kànlélọ́gọ́ta lọ ní gígùn, ṣùgbọ́n àwọn pósí tó fẹ́ tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́rìnlélọ́gọ́fà tí wọ́n sì ṣe ara ẹ̀ ringindin ti wà báyìí. Wọ́n ti fi kún fífẹ̀ “àwọn ilé orí ibojì, sàréè, àti ọkọ̀ ìgbókùú, kódà, wọ́n tún ti fi kún fífẹ̀ ṣọ́bìrì tó wà lára ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ́lẹ̀ ní itẹ́ òkú.” Olùdarí àgbà fáwùjọ tó ń gbẹnu sọ fáwọn tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀, Allen Steadham, sọ pé: “Àwọn èèyàn ń tóbi fọ̀ngbàdì fọ̀ngbàdì, wọn á sì rí bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀ bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀ bí wọ́n bá kú, àwọn ilé iṣẹ́ sì ń ro tiwọn mọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe jáde.”

“Òkun Òkú Ti Ń Gbẹ O”

Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ àjọ akọ̀ròyìn Associated Press sọ pé: “Òkun Òkú ti ń gbẹ, àfi báwọn onímọ̀ ẹ̀rọ bá lọ́wọ́ sọ́ràn náà ni ò fi ní gbẹ tán ráúráú.” Òkun Òkú, tí wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀ nítorí pé ìyọ tó pọ̀ nínú ẹ̀ ò jẹ́ káwọn ẹ̀dá omi lè gbé níbẹ̀, wà ní ibi tó rẹlẹ̀ jù lọ lágbàáyé, ó fi irínwó mítà wà ní ìsàlẹ̀ ìtẹ́jú òkun. “Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, bí oòrùn ṣe ń fa omi inú òkun náà gbẹ, ni omi mìíràn ń ṣàn wọ ibẹ̀ látinú Odò Jọ́dánì, tó jẹ́ ibi kan ṣoṣo tómi ń bá wọnú ẹ̀, ìyẹn ni ò jẹ́ kó tíì gbẹ tán. Àmọ́ ṣá o, láwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Jọ́dánì ti ń lo omi tó ń wá látinú Odò Jọ́dánì láti bomi rin àwọn ilẹ̀ gbígbòòrò tí wọ́n fi ń dáko nítòsí odò pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ tó la àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì láàárín, ìyẹn sì ń pa Òkun Òkú lára, nítorí omi mìíràn ò rọ́pò èyí tí oòrùn bá ti fà nínú rẹ̀ mọ́.” Ìwádìí kan ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ pé, bí wọn ò bá wá nǹkan ṣe sí i, omi tó wà nínú rẹ̀ á túbọ̀ máa fi nǹkan bíi mítà kan dín kù lọ́dún, ìpalára ńlá lèyí á sì ṣe fún ilẹ̀ tó yí i ká, àwọn ẹranko inú ìgbẹ́ àtàwọn nǹkan ọ̀gbìn. Ní báyìí, ọ̀dá kan tó fi ọdún márùn-ún dá ti ń pa kún àjálù tó bá Òkun Òkú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́