Wíwo Ayé
◼ Ọdún tó kọjá ni “ọdún tí ooru mú jù lọ ní Àríwá Ìlàjì Ayé,” tá a bá sì wò ó jákèjádò ayé, “ẹ̀ẹ̀kan péré ni ooru tíì mú ju bó ṣe mú lọ́dún tó kọjá lọ.” “Àárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá la ti rí ọdún mẹ́jọ [tó wà lákọọ́lẹ̀] pé ooru tíì mú jù lọ.”—ÌRÒYÌN ILÉ IṢẸ́ AGBÓHÙNSÁFẸ́FẸ́ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ.
◼ Àsìkò tí ìjì líle jà létí òkun Àtìláńtíìkì lọ́dún 2005 ló tíì jẹ́ àsìkò “tọ́wọ́ dí jù lọ . . . èèyàn sì lè sọ pé òun ni ìjì líle tó tí ì ṣe ọṣẹ́ jù lọ,” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀. Lára ìjì líle mẹ́rìnlá tó wà lákọọ́lẹ̀, méje nínú wọn lè yára jà kọjá kìlómítà mẹ́tàdínláàádọ́sàn-án [177], ìyẹn àádọ́fà [110] máìlì ní wákàtí kan ṣoṣo.—ILÉ IṢẸ́ TÓ Ń BÓJÚ TÓ ÒKUN ÀTI OJÚ ÒFUURUFÚ NÍLẸ̀ AMẸ́RÍKÀ.
◼ “Lọ́dún 1850, ó ju àádọ́jọ [150] òkìtì yìnyín tó wà ní ọgbà òkìtì yìnyín tó ń jẹ́ Glacier National Park ní ìpínlẹ̀ Montana [lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà]. Àmọ́ báyìí, mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n péré ló kù.”—ÌWÉ ÌRÒYÌN THE WALL STREET JOURNAL, ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ.
◼ “Òtítọ́ pọ́ńbélé tó wà nínú ọ̀rọ̀ ṣíṣe àyípadà sí bí ayé ṣe ń móoru ni pé kò sí orílẹ̀-èdè kan táá fẹ́ ṣe ìyípadà táá mú kí ìṣòro náà yanjú tó bá di pé ìyípadà náà á ṣàkóbá fún ọrọ̀ ajé wọn.”—TONY BLAIR, OLÓRÍ ÌJỌBA ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ.
Àbí Àwọn Kátólíìkì Náà Fẹ́ Máa Wàásù Láti “Ilé dé Ilé”?
Gẹ́gẹ́ bí bíṣọ́ọ̀bù àgbà ti ìlú São Paulo, ìyẹn Cláudio Hummes, ṣe sọ, iye àwọn ará Brazil tó jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì ti dín kù. Ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, tá a bá fi gbogbo wọn dá ọgọ́rùn-ún, mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] nínú wọn ló jẹ́ Kátólíìkì, àmọ́ báyìí iye yẹn ti di mẹ́tàdínláàádọ́rin [67]. Bíṣọ́ọ̀bù náà di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ ọ̀hún ru ṣọ́ọ̀ṣì torí “bí wọn kì í ṣeé lè wàásù lọ́nà tó múná dóko fáwọn ọmọ ìjọ tó ṣèrìbọmi, èyí tó jẹ́ pé onírúurú nǹkan ló fà á.” Hummes sọ pé: “Ó yẹ ká máa wá àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ láti ilé dé ilé, ká wá wọn lọ sáwọn ilé ìwé àti sáwọn ilé iṣẹ́ míì, kì í kàn ṣe ká jókòó sínú ṣọ́ọ̀ṣì nìkan.” Ìwé ìròyìn orí íńtánẹ́ẹ̀tì, Folha Online, sọ pé àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ti kọ́ ní iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló yẹ kó ṣiṣẹ́ yìí. Ọ̀kan lára olórí ìṣòro tó ń kojú ìjọ Kátólíìkì lórílẹ̀-èdè Brazil àti láwọn orílẹ̀-èdè yòókù tó wà ní ìhà Gúúsù Amẹ́ríkà ni pé àwọn àlùfáà ò pọ̀ tó.
Òfin Ti Fọwọ́ sí Ẹ̀sìn Wa Nílẹ̀ Jámánì
Nínú ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Leipzig lórílẹ̀-èdè Jámánì, ìyẹn Federal Administrative Court, ṣe ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kejì ọdún 2006, ilé ẹjọ́ náà pàṣẹ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Berlin gbọ́dọ̀ ka àjọ Religious Association of Jehovah’s Witnesses in Germany kún àwọn ẹ̀sìn tó lórúkọ lábẹ́ òfin. Ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún rèé tí ọ̀ràn yìí ti ń ti ilé ẹjọ́ kan dé òmíràn nílẹ̀ Jámánì, tó fi mọ́ ilé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀, ìyẹn Federal Constitutional Court, tó sì ti wá kángun síbi tó dáa báyìí. Níwọ̀n bí òfin ti fọwọ́ sí Religious Association of Jehovah’s Witnesses in Germany gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ tó wà fún àǹfààní aráàlú, wọn ò ní máa gbà owó orí tó yẹ kí wọ́n máa gbà lọ́wọ́ àwọn iléeṣẹ́ lọ́wọ́ wọn, wọ́n á sì máa gbádùn àwọn àǹfààní mìíràn táwọn ẹ̀sìn ńláńlá tó wà lórílẹ̀-èdè náà ń gbádùn.
Eré Ìdárayá Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì Ti Jàrábà Àwọn Ọ̀dọ́ Ilẹ̀ Ṣáínà
“Eré ìdárayá orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti jàrábà àwọn ọ̀dọ́ nílẹ̀ Ṣáínà o, ṣe làwọn tó ń di bárakú fún nínú wọn sì ń pọ̀ sí i,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn orílẹ̀-èdè Hong Kong náà, South China Morning Post ṣe sọ. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nínú ọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́ míì tí wọ́n wà láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìlà Oòrùn Ayé nìyẹn, ìyẹn àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hong Kong, Japan àti Kòríà. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Nílé lóko lojú ti wà lára àwọn ọmọdé báyìí torí pé àwọn òbí ń fẹ́ káwọn ọmọ rúnpá-rúnsẹ̀ sí i kí wọ́n lè wọ yunifásítì. Àmọ́, jíjókòó táwọn èwe fẹ́ láti máa jókòó sídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì kò jẹ́ kí èròǹgbà ọ̀hún jọ.” Wọ́n fojú bù ú pé ó tó mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn ọmọdé nílẹ̀ Ṣáínà tó nílò ìrànlọ́wọ́ láti borí ohun tó ti jàrábà wọn yìí.