Kí Ló Fà Á Tí Mo FI Máa Ń Dákú?
Dókítà fẹ́ láti mọ bí ojú mi ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa sí. Nítorí náà, ó ní láti fi irin iṣẹ́ kan báyìí kan ẹyinjú mi. Èmi fúnra mi ti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bó bá ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí pé bó ṣe máa ń ṣe mi nígbà gbogbo nìyẹn. Bó ṣe ṣe mí náà nìyẹn nígbà tí nọ́ọ̀sì fi abẹ́rẹ́ fa ẹ̀jẹ̀ lára mi. Ó sì tún máa ń ṣe mí bẹ́ẹ̀ bí mo bá fara pa. Ńṣe ni mo máa ń dákú.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan láti orílẹ̀-èdè Kánádà ṣe fi hàn, bá a bá kó ọgọ́rùn-ún èèyàn bí irú tèmi jọ, nǹkan bíi mẹ́ta lára wa sábà máa ń dákú bí wọ́n bá fi nǹkan kan ẹyinjú wa, bí wọ́n bá fi abẹ́rẹ́ fa ẹ̀jẹ̀ lára wa tàbí bá a bá fara pa. Bó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn, ó ṣeé ṣe kó o ti rí i pé pàbó ni gbogbo ọgbọ́n tó ò ń dá kó o má bàa máa dákú ń já sí. O tiẹ̀ lè ti gbìyànjú láti máa gba ilé ìwẹ̀ lọ kó o má bàa máa dákú ní gbangba. Ìyẹn ò fi bẹ́ẹ̀ dáa tó ṣá o. Nítorí pé o lè dákú lójijì kó o sì ṣe ara ẹ léṣe. Lẹ́yìn tí mo ti dákú dájí báyìí lọ́pọ̀ ìgbà, mo pinnu pé màá fẹ́ mọ ohun tó ń fà á.
Lẹ́yìn témi àti dókítà kan tó láàánú lójú ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, témi náà sì ti ṣèwádìí nínú àwọn ìwé mélòó kan, mo rí i pé àìtó ẹ̀jẹ̀ tó ń lọ sínú ọpọlọ ló máa ń mú kéèyàn dákú. Wọ́n ní ohun kan wà tó máa ń pín ẹ̀jẹ̀ tó ń lọ káàkiri inú ara bó ṣe yẹ, àmọ́ bó bá di pé ohun tó ń pín ẹ̀jẹ̀ tó ń lọ káàkiri inú ara bó ṣe yẹ yìí ò bá ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, ó di dandan kéèyàn dákú, bíi nígbà tẹ́ni tó wà lórí ìjókòó tẹ́lẹ̀ bá dédé dìde dúró.
Láwọn ìgbà kan, bíi nígbà tó o bá rí ẹ̀jẹ̀ tàbí tí wọ́n bá fi nǹkan kan ẹyinjú rẹ, ohun tó máa ń darí bó o ṣe ń mí sókè sódò, bóúnjẹ ṣe ń dà lára ẹ, bí àyà ẹ ṣe ń lù kìkì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ á mú kó máa ṣe ẹ́ bíi pé orí ìdùbúlẹ̀ lo wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe lo jókòó tàbí kó jẹ́ pé orí ìdúró lo wà. Ohun tó o máa kọ́kọ́ kíyè sí ni pé àníyàn tó wà lọ́kàn ẹ á mú kí àyà ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í lù kìkì. Lẹ́yìn náà, ìlùkìkì náà á bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, òpó tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ lọ sí ẹsẹ̀ rẹ á fẹ̀ sí i. Nítorí èyí, ẹ̀jẹ̀ tó ń kọjá lọ sí ẹsẹ̀ rẹ á pọ̀ sí i, èyí tó ń kọjá lọ sí orí ẹ á sì dín kù. Afẹ́fẹ́ ọ́síjìn, ìyẹn afẹ́fẹ́ tó ń gbẹ́mìí ró ò ní tó mọ́ nínú ọpọlọ, wàá sì dákú. Kí lo lè ṣe tírú èyí ò fi ní ṣẹlẹ̀ mọ́?
Bí nọ́ọ̀sì bá ń fa ẹ̀jẹ̀ rẹ, o lè gbójú kúrò níbẹ̀ tàbí kó o rí i pé o wà lórí ìdùbúlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, kó tó di pé ẹ̀jẹ̀ tó ń lọ sínú ọpọlọ ẹ ò tó mọ́, ó ní bí ara ṣe máa sọ fún ẹ, tíwọ náà á sì mọ̀. Torí náà, àkókò sábà máa ń wà tó láti wá nǹkan ṣe sí i kó o tó dákú. Ọ̀pọ̀ dókítà máa ń dá a lábàá pé kéèyàn dùbúlẹ̀, kó sì fi ẹsẹ̀ méjèèjì ti àga tàbí ara ògiri. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ò ní rogún sí ẹsẹ̀ rẹ, ọ̀ràn àìtó ẹ̀jẹ̀ nínú ọpọlọ tó máa mú kó o dákú ò ní wáyé. Ó sì ṣeé ṣe kára ẹ ti le láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ péré.
Bí ìsọfúnni yìí bá ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ti ṣe ràn mí lọ́wọ́, wàá lè máa mọ̀ bó bá ti ń di pé ẹ̀jẹ̀ tó ń lọ sínú ọpọlọ ẹ ò tó nǹkan mọ́. Wàá sì lè yára ṣe ohun tó yẹ kó o ṣe kó o má bàa dákú.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
Ó máa dáa kó o máa wà ní ìdùbúlẹ̀ bó o bá ń gba ìtọ́jú ìṣègùn