Wíwo Ayé
◼ Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, nǹkan bí ẹgbàá ọ̀kẹ́ lára àwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Ṣáínà ló pàdánù ilẹ̀ wọn nítorí báwọn èèyàn ṣe ń yára fi oko sílẹ̀ tí wọ́n sì ń gba ìgboro lọ.—ÌWÉ ÌRÒYÌN CHINA DAILY, ORÍLẸ̀-ÈDÈ ṢÁÍNÀ.
◼ Kárí ayé, lọ́dún 2005, ogun méjìdínlọ́gbọ̀n ló jà. Wọ́n sì ja àwọn ìjà mọ́kànlá míì tí wọ́n ti gbébọn.—ÌWÉ ÌRÒYÌN VITAL SIGNS 2006-2007, TI ILÉ IṢẸ́ WORLDWATCH INSTITUTE.
◼ Àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan láti ilé ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìyẹn Institute of Technology nílùú Tokyo ti ṣe ọkọ̀ òfuurufú fífúyẹ́ gẹngẹ kan tó fi díẹ̀ wúwo ju àpò símẹ́ǹtì lọ tó sì jẹ́ pé bátìrì ló ń lò. Èyí tí ọkọ̀ òfuurufú náà fi rìn jìnnà sókè tó mítà mẹ́sàn-án dín nírínwó, èyí tó tó nǹkan bí àjà ilé méjìdínláàádóje, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú àáyá mọ́kàndínlọ́gọ́ta.—ÌWÉ ÌRÒYÌN MAINICHI DAILY NEWS, ORÍLẸ̀-ÈDÈ JAPAN.
◼ Lára àwọn ọmọ ọdún méjìlá sí ọmọ ogún ọdún tí wọ́n ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lórílẹ̀-èdè Netherlands, tí wọ́n ṣèbẹ̀wò síbì kan tí wọ́n ti lè fi ẹ̀rọ tó ń ya fọ́tò polówó ara wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, “nǹkan bí ìdajì ọmọkùnrin àti ìdajì ó lé díẹ̀ lára àwọn ọmọbìnrin tó wà lára wọn sọ pé wọ́n ní káwọn bọ́ra síhòòhò tàbí káwọn ṣe bí aṣẹ́wó lóríṣiríṣi ọ̀nà níwájú ẹ̀rọ tó ń ya fọ́tò náà.”—RUTGERS NISSO GROEP, ORÍLẸ̀-ÈDÈ NETHERLANDS.
Ṣé Eré Kọ̀ǹpútà Lè Di Bárakú?
“Bí ọpọlọ àwọn èèyàn tó ń ṣe eré kọ̀ǹpútà láṣejù ṣe ń ṣiṣẹ́ jọ tàwọn ọ̀mùtí tàbí tàwọn amugbó.” Ọ̀gbẹ́ni Ralf Thalemann tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ló sọ̀rọ̀ yìí. Òun ni aṣáájú ẹgbẹ́ tó ń ṣèwádìí lórí àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń sọ di bárakú nílé ẹ̀kọ́ gíga Charité University Hospital, nílùú Berlin, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Wọ́n lérò pé bí ṣíṣe eré kọ̀ǹpútà láṣejù bá ti kó sí èèyàn lórí tán, ó lè mú kí èròjà dopamine tó ń tú dà sínú ọpọlọ ẹni tó bá ń ṣeré kọ̀ǹpútà náà máa pọ̀ sí i. Ìyẹn á wá mú kí eré náà túbọ̀ máa gbádùn mọ́ ọn títí tá á fi di “bárakú.” Lẹ́yìn táwọn kan ṣèwádìí, wọ́n tiẹ̀ dámọ̀ràn pé èyí lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan lára ẹni mẹ́wàá tó bá ń ṣeré kọ̀ǹpútà.
“Ẹ̀rù” Máa Ń Ba Àwọn Ọlọ́rọ̀ “Ọkàn Wọn Kì Í Sì Í Balẹ̀”
Ìwé ìròyìn ìlú Beijing náà, China Daily, sọ pé, “ẹ̀rù máa ń ba àwọn milọníà, ìyẹn àwọn tí wọ́n lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọkàn wọn kì í sì í balẹ̀.” Wọ́n ṣe ìwádìí kan ní East China àti South China. Ìwádìí náà dá lórí àwọn èèyàn tí ìpíndọ́gba ọrọ̀ wọ́n tó bílíọ̀nù méjì àti igba mílíọ̀nù yuan ti ilẹ̀ Ṣáínà (èyí tó jẹ́ bílíọ̀nù márùndínlógójì àti igba mílíọ̀nù náírà). Àwọn olùṣèwádìí tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọlọ́rọ̀ àti “ìhà tí wọ́n kọ sí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ìgbéyàwó, ìgbé ayé, iṣẹ́ àṣejẹ àti owó,” rí i pé “èyí tó pọ̀ jù lára àwọn milọníà náà ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó tí wọ́n sì tún kórìíra ẹ̀.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kópa nínú ìwádìí náà sọ pé bá a bá yọwọ́ pé ọrọ̀ máa ń to èèyàn síbi tó ga láwùjọ, tó sì máa ń mú kéèyàn ronú pé ọwọ́ òun ti tẹ ohun tóun ń wá, wọ́n ò ṣàìgbà pé “ohun tí ọrọ̀ ti ṣe fáwọn jù lọ ni pé ó máa ń mú inú bí àwọn.”
Iṣẹ́ Oko Máa Ń Mú Kára Alárùn Ọpọlọ Le
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ògbógi tó lé ní ọgọ́rùn-ún láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlá pàdé nílùú Stavanger, lórílẹ̀-èdè Norway, wọ́n fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Fífi Ewéko Ṣe Ìwòsàn, èyí tó jẹ́ ọgbọ́n ìṣègùn kan tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀gbìn, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìtọ́jú ara. Gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ oníròyìn lórílẹ̀-èdè Norway, ìyẹn NRK, ṣe sọ, kì í tún ṣohun tó pọn dandan mọ́ pé kí wọ́n gba àwọn tó ti lárùn ọpọlọ fún ọ̀pọ̀ ọdún sílé ìtọ́jú àwọn alárùn ọpọlọ bí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ oko. Iṣẹ́ tó ń fún “ọkàn àti ara lókun” ni. Ó lé ní ẹgbẹ̀ta [600] oko tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn lórílẹ̀-èdè Norway táwọn àgbẹ̀ ti fara mọ́ ètò Fífi Ewéko Ṣe Ìwòsàn yìí, ó sì máa ń mú kí owó díẹ̀díẹ̀ wọlé sápò wọn.
Lílò Kan Àwọn Ilé Gogoro Tó Wà Lórí Ṣọ́ọ̀ṣì
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Newsweek ṣe sọ: “Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì New England [lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà] ti rí ojútùú sí ètò ìṣúnná owó wọn tó ń dín kù sí i. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ilé gogoro tó lẹ́wà tí wọ́n máa ń kọ́ sórí ṣọ́ọ̀ṣì wọn háyà fáwọn iléeṣẹ́ tẹlifóònù alágbèéká tí wọ́n ń wábi tí wọ́n máa ri òpó wọn sí.” Ibi tí wọ́n lè ri òpò sí kó lè máa ta ìsọfúnni látagbà lọ sára tẹlifóònù alágbèéká ò tó nǹkan nítorí òfin tó de ibi táwọn èèyàn máa ń kọ́ ilé gbígbé sí, àwọn tó ń gbé nírú àwọn àdúgbò bẹ́ẹ̀ ò sì fẹ́ láti máa rí òpó èyíkéyìí ládùúgbò tí wọ́n ń gbé. Ìdí ẹ̀ nìyẹn táwọn ilé iṣẹ́ tẹlifóònù alágbèéká fi ń gbé ẹ̀rọ wọn pa mọ́ sínú àwọn ilé gogoro tó wà lórí ṣọ́ọ̀ṣì. Ààrẹ ilé iṣẹ́ kan tó ń ṣojú fáwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ń fi ilé gogoro háyà yìí sọ pé: “Ó ti di òpó mẹ́ta tó wà lórí ṣọ́ọ̀ṣì tá a fi bẹ̀rẹ̀ báyìí, owó tó sì ń wọlé sápò àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó fi wọ́n háyà lọ́dún jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn nítorí ilé gogoro tí wọ́n fi bu ẹwà kún ṣọ́ọ̀ṣì lásán o.”