ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/08 ojú ìwé 30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Ti Fọwọ́ sí Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-Èdè Turkey
  • Íńtánẹ́ẹ̀tì Ń Sọ Àwọn Èèyàn Di Aláìnítìjú
  • Àkẹ̀kù Tí Ń Ba Ẹ̀rí Jẹ́
  • Ó Ṣe Jẹ́ Pé Lópin Ọ̀sẹ̀ Lojú Ọjọ́ Máa Ń Burú Jù?
  • Kí Ni Ìsokọ́ra Alátagbà Internet?
    Jí!—1997
  • Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Èé Ṣe Tí O Ní Láti Ṣọ́ra?
    Jí!—1997
  • Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ṣé Bẹ́ẹ̀ Ni Ewu Pọ̀ Tó Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 4/08 ojú ìwé 30

Wíwo Ayé

◼ Láti ọdún mẹ́fà sẹ́yìn, “nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn . . . ni wọ́n ti pa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.”—ÌWÉ ÌRÒYÌN THE NEW YORK TIMES, ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ.

◼ Àwọn tó ń bójú tó ìkànnì gbogbo gbòò kan ti mú orúkọ àti àkọsílẹ̀ míì tó jẹ́ ti ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29,000] lára àwọn oníbàárà wọn kúrò lórí ìkànnì wọn torí pé wọ́n ti fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń ṣèṣekúṣe. Amòfin Àgbà ti ìpínlẹ̀ Connecticut, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Richard Blumenthal, ké gbàjarè pé àkókò ti tó báyìí láti wá nǹkan ṣe sí “ọ̀ràn àwọn oníṣekúṣe tí wọ́n ń pọ̀ sí i bí ewé rúmọ̀ níbi [ìkànnì] náà.”—ÌRÒYÌN LÁTI REUTERS NEWS SERVICE, ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ.

◼ “Ó dà bíi pé ọ̀dá orúkọ ti dá wọn lórílẹ̀-èdè Ṣáínà báyìí o. . . . Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe jákèjádò orílẹ̀-èdè náà lọ́dún 2006 fi hàn [pé] nǹkan bí ìdá márùndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún . . . lára bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ṣáínà ni wọ́n ń pín ọgọ́rùn-ún orúkọ ìdílé lò láàárín ara wọn.”—ÌWÉ ÌRÒYÌN CHINA DAILY, ORÍLẸ̀-ÈDÈ SÁÍNÀ.

◼ Ní gbogbo ìgbà táwọn alálùpùpù bá rìnrìn-àjò kìlómítà kan, “ìgbà méjìlélọ́gbọ̀n ni ewu ikú máa ń wu wọ́n” ju tàwọn tó bá wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ.—UC BERKELEY WELLNESS LETTER, ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Wọ́n Ti Fọwọ́ sí Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-Èdè Turkey

Ní July 31, 2007, orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀wé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tí ìjọba fọwọ́ sí lórílẹ̀-èdè Turkey. Èyí á fún wọn láǹfààní láti lè ra ilé tàbí ilẹ̀, wọ́n lè kọ́ àwọn ibi ìjọsìn, kí wọ́n háyà àwọn ibi ìpàdé, kí wọ́n gba ọrẹ, kí wọ́n sì pẹjọ́ bó bá pọn dandan pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

Íńtánẹ́ẹ̀tì Ń Sọ Àwọn Èèyàn Di Aláìnítìjú

Nínú àtẹ̀jáde kan, ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì ilẹ̀ Jámánì kan, tí wọ́n dá sílẹ̀ káwọn lọ́kọláya lè máa fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹra wọn níṣu, sọ pé àwọn ti ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún lé mẹ́wàá [310,000] oníbàárà báyìí, àwọn oníbàárà tuntun tí wọ́n sì ń rí lójoojúmọ́ jẹ́ ẹgbẹ̀rún [1,000] kan. Ohun tó jẹ́ ìwúrí àwọn onígbọ̀wọ́ ìkànnì náà ni pé nínú gbogbo àwọn tó ń fọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ ọkọ tàbí aya wọn níṣu lórí ìkànnì náà, “kò sí ọ̀kan ṣoṣo péré tó mọra wọn.” Ọ̀kan lára àwọn olùdarí ìkànnì náà sọ pé: “Nítorí pé kò sí ẹlòmíì tó mọ àwọn tó ń bára wọn ṣàdéhùn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kì í jẹ́ kójú tì wọ́n” ó sì máa ń mú kó “túbọ̀ rọrùn fún wọn láti bára wọn ṣàdéhùn láìwẹ̀yìn wò.” Òmíràn lára àwọn olùdarí ìkànnì náà wá fọwọ́ sọ̀yà pé Íńtánẹ́ẹ̀tì á túbọ̀ jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ọkọ tàbí aya máa dalẹ̀ ara wọn.

Àkẹ̀kù Tí Ń Ba Ẹ̀rí Jẹ́

Báwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ń ṣàlàyé apá mẹ́ta tó kẹ́yìn nínú “béèyàn ṣe ti ara ẹranko jáde,” wọ́n á ní lẹ́yìn Homo habilis ó para dà di Homo erectus kó tó wá di “ẹ̀dá adáríhurun” ìyẹn, Homo sapiens. Àmọ́, níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn síra lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí àkẹ̀kù méjì kan. Wọ́n sì sọ pé àwọn àkẹ̀kù méjèèjì náà, ìyẹn Homo habilis àti Homo erectus, tí wọ́n rò pé ẹ̀dá èèyàn tara wọn ṣẹ̀ wá, jọ wà nígbà kan náà ni. Meave Leakey tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìròyìn lórí ìwádìí nípa àkẹ̀kù yìí wá sọ pé: “Wíwà tí wọ́n jọ wà nígbà kan náà yìí mú kó dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe pé kí ‘Homo habilis’ para dà di ‘Homo erectus.’

Ó Ṣe Jẹ́ Pé Lópin Ọ̀sẹ̀ Lojú Ọjọ́ Máa Ń Burú Jù?

Ọ̀pọ̀ ará Jámánì ti bẹ̀rẹ̀ sí fura pé ojú ọjọ́ máa ń dáa láàárín ọ̀sẹ̀ ju òpin ọ̀sẹ̀ lọ. Ìwé ìròyìn Der Spiegel sọ pé ó ṣeé ṣe kí kúlẹ̀kúlẹ̀ ìwádìí tí wọ́n fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣe nípa bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí lápá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Jámánì já sí bí wọ́n ṣe rò ó sí. Ọjọ́ Wednesday ló máa ń móoru jù lọ, ọjọ́ Saturday ló sì máa ń tutù jù lọ. Láwọn ọjọ́ Saturday, òjò máa ń fi bí ìlọ́po méje rọ̀ ju ti àárín ọ̀sẹ̀ lọ, ó sì máa ń ṣe lemọ́lemọ́ nígbà mẹ́wàá ju ti ọjọ́ Monday tó sábà máa ń gbẹ fúrúfúrú. Oòrùn máa ń fi ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ràn lọ́jọ́ Tuesday ju ọjọ́ Saturday lọ. Àwọn olùṣèwádìí lérò pé ooru ara àwọn èèyàn, èyí tó ti dà mọ́ afẹ́fẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀ máa ń gbára jọ lópin ọ̀sẹ̀, á dà pọ̀ mọ́ ooru tó wá látara oòrùn láti yọ́ ìkùukùu, èyí tó máa wá jẹ́ kí òjò rọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́