ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/08 ojú ìwé 12-13
  • Ìgbà Wo Ló Tọ́ Kéèyàn Gbèjà Ara Ẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ló Tọ́ Kéèyàn Gbèjà Ara Ẹ̀?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Kórìíra Ìwà Ipá
  • Bí Wọ́n Bá Gbéjà Kò Ẹ́
  • Ààbò Tó Dára Jù Lọ
  • Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ipá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Irú Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Ipá?
    Jí!—2002
  • Ìwà Ipá
    Jí!—2015
  • Ìdí Tí Wọn Fi Ń hùwà ipá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 7/08 ojú ìwé 12-13

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ìgbà Wo Ló Tọ́ Kéèyàn Gbèjà Ara Ẹ̀?

ARIWO kan mú kó o ta jí láàárín òru. Ò ń gbúròó ẹsẹ̀. Ẹnì kan ti jálẹ̀kùn wọlé. Làyà ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí lù kìkì, ìbẹ̀rù ò sì jẹ́ kó o mohun tó ò bá ṣe.

Kò séèyàn tírú ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí. Ìwà ìkà àti ìwà ọ̀daràn ò wulẹ̀ mọ sáwọn orílẹ̀-èdè kan tàbí àwọn ìlú ńlá nìkan, ibi gbogbo ni wọ́n ti ń kó adìyẹ alẹ́. Ìbẹ̀rù táwọn èèyàn ń ní torí ìwà ọ̀daràn tó gbayé kan ti mú kí wọ́n máa ra ohun ìjà lóríṣiríṣi láti fi dáàbò bo ara wọn, kí wọ́n sì máa kọ́ oríṣiríṣi ọgbọ́n ìjàkadì téèyàn lè fi gbèjà ara ẹ̀. Àwọn ìjọba kan tiẹ̀ ti ṣàwọn òfin tó fún àwọn aráàlú lẹ́tọ̀ọ́ láti lo àwọn nǹkan tó lè ṣekú pa ẹlòmíì láti fi gbèjà ara wọn. Àmọ́, kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ṣó tọ́ kéèyàn lo ọgbọ́n ìjàkadì láti fi gbèjà ara ẹ̀ tàbí kó fi gbèjà àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀?

Ọlọ́run Kórìíra Ìwà Ipá

Bíbélì dẹ́bi fún ìwà ipá àtàwọn oníwà ipá. Dáfídì, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù, sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Dájúdájú, ọkàn rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Ọlọ́run kéde ìdájọ́ sórí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nígbà àtijọ́, tó fi mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀, torí wọ́n hùwà ipá, wọ́n sì tàjẹ̀ sílẹ̀. (Jóẹ́lì 3:19; Náhúmù 3:1; Míkà 6:12,13) Kódà, nínú òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹnikẹ́ni téèyàn bá kú mọ́ lọ́wọ́, torí pé kò ka nǹkan sí, ti dáràn tó burú jáì.—Diutarónómì 22:8.

Bíbélì gba olúkúlùkù wà níyànjú pé ká máa wá àlááfíà lójoojúmọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí ìjà máa wáyé. Ibi ọ̀rọ̀ kòbákùngbé ni ìjà àjàkú akátá ti sábà máa ń bẹ̀rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú, níbi tí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ kò bá sì sí, asọ̀ a dá.” (Òwe 26:20) Sùúrù sábà máa ń bomi paná ìbínú, kì í sì í jẹ́ kí ìjà wáyé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.

Bí Wọ́n Bá Gbéjà Kò Ẹ́

Téèyàn bá jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn ọ̀daràn ò ní gbéjà kò ó. Àwọn ọ̀daràn ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa hùwà ìkà sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 4:8; Jóòbù 1:14, 15, 17) Báwọn adigunjalè bá gbéjà ko ẹnì kan, kí ló yẹ kó ṣe? Jésù fún wa nítọ̀ọ́ni pé: “Má ṣe dúró tiiri lòdì sí ẹni burúkú.” (Mátíù 5:39) Ó tún sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ lọ, má ṣe dù ú ní ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pàápàá.” (Lúùkù 6:29) Jésù ò fọwọ́ sí lílo nǹkan ìjà torí àtigbèjà ohun ìní tara. Ẹni tó bá gbọ́n ò ní kọ̀ láti fún àwọn adigunjalè lóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ bí wọ́n bá gbéjà kò ó. Kò sí àní-àní pé gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ lẹ̀mí wa fi ṣeyebíye ju ohun ìní èyíkéyìí lọ!

Àmọ́ ṣá o, bí ọ̀daràn yẹn bá fẹ́ gbẹ̀mí wa ńkọ́? Òfin kan tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe. Bí wọ́n bá mú olè lọ́sàn-án gangan, tí wọ́n sì pa á, ẹni tó pa á máa jẹ̀bi ìpànìyàn. Èyí jẹ́ nítorí pé, ẹjọ́ ikú kọ́ ni wọ́n máa ń dá fún olè, ńṣe ló yẹ kí wọ́n mú olè náà, kí wọ́n sì fà á lé àwọn adájọ́ lọ́wọ́. Àmọ́, bí wọ́n bá lu ọ̀daràn kan pa lóru, wọn ò ní dẹ́bi fún onílé yẹn torí pé kò lè rọrùn fún un láti rí ohun tí ọ̀daràn yẹn ń ṣe débi tó fi máa mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Onílé yẹn lè ronú lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu pé ìdílé òun wa nínú ewu, kó sì wá ọ̀nà láti dáàbò bò wọ́n.—Ẹ́kísódù 22:2, 3.

Bíbélì tipa báyìí jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè gbèjà ara rẹ̀ tàbí ìdílé rẹ̀ bí wọ́n bá gbéjà kò wọ́n. Kò burú béèyàn bá yẹra fún ẹ̀ṣẹ́, tó dá onítọ̀hún lọ́wọ́ kọ́, tàbí tó gbà á lẹ́ṣẹ̀ẹ́ kóun lè ríbi sá lọ níbi tí ọ̀daràn náà ti ń pa rìdàrìdà. Ìdí téèyàn fi máa ṣe bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ kónítọ̀hún má bàa ṣeni ní jàǹbá tàbí kó lè dáwọ́ ìjà yẹn dúró. Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé onílé yẹn ṣe ọ̀daràn náà léṣe tàbí tí ọ̀daràn náà gbabẹ̀ kú, a jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, kì í ṣe pé onílé yẹn mọ̀ọ́mọ̀ pa á.

Ààbò Tó Dára Jù Lọ

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé, kò burú láti gbèjà ara ẹni lọ́nà tó bẹ́tọ̀ọ́ mu nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti dáàbò bo ara wọn àtàwọn èèyàn wọn lọ́wọ́ ohunkóhun tó bá lè pa wọ́n lára tàbí tó lè la ikú lọ. Béèyàn ò bá rọ́nà àbáyọ, Bíbélì ò sọ pé kó má gbèjà ara ẹ̀ bó bá ṣe tọ́. Àmọ́, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé, ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti yẹra fún ìgbéjàkoni.—Òwe 16:32.

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “máa wá àlàáfíà, kí [á] sì máa lépa rẹ̀” nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. (1 Pétérù 3:11) Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà máa gbé ìgbé ayé àlááfíà nìyẹn.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Kí nìdí tí kò fi yẹ ká hùwà ipá?—Sáàmù 11:5.

◼ Kí ló bọ́gbọ́n mu pé ká ṣe nígbà tá a bá ń dáàbò bo àwọn ohun ìní wa?—Òwe 16:32; Lúùkù 12:15.

◼ Kí la lè ṣe tí ewu ò fi ní wu wá nígbà tí ìjà bá fẹ́ wáyé?—Róòmù 12:18.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè gbèjà ara rẹ̀ tàbí ìdílé rẹ̀ bí wọ́n bá gbéjà kò wọ́n

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́