Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Bí Ẹ̀gbọ́n Tàbí Àbúrò Mi Bá Para Ẹ̀ Ńkọ́?
Nǹkan tojú sú Karen lọ́jọ́ tí dádì ẹ̀ sọ fún un pé àbúrò ẹ̀ ti ṣaláìsí. Gbogbo ohun tí dádì ẹ̀ lè sọ nígbà yẹn ò ju pé: “Sheila ti lọ.” Àwọn méjèèjì dì mọ́ra, kò rọrùn fún wọn láti gbà póòótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Àbúrò Karen ti para ẹ̀.a
NÍGBÀ tẹ́nì kan tó kéré lọ́jọ́ orí bá ṣaláìsí, ọ̀rọ̀ àwọn òbí ẹ̀ ló sábà máa ń jẹ àwọn tó ń bá wọn kẹ́dùn lógún. Wọ́n sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni tó para ẹ̀ pé, “Ṣáwọn òbí yín ò bara jẹ́ jù?” àmọ́ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ béèrè pé, “Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ?” Ìyẹn fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í kọbi ara sí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni tó kú.
Ìwádìí ti fi hàn pé ipa kékeré kọ́ ni ikú ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò sábà máa ń ní lórí àwọn ọ̀dọ́. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ P. Gill White sọ nínú ìwé ẹ̀ kan tó pe àkọlé ẹ̀ ní Sibling Grief—Healing After the Death of a Sister or Brother, pé: “Àdánù tó kàmàmà yìí máa ń ṣàkóbá fún ìlera, iṣẹ́ iléèwé, ìwà, iyì ara ẹni, ìdàgbàsókè àti ìṣesí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ọmọ tó kú.”
Ọ̀rọ̀ yìí ò yọ àwọn ọ̀dọ́langba pàápàá sílẹ̀. Ọmọ ọdún méjìlélógún [22] ni Karen tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan nígbà tí Sheila, àbúrò ẹ̀ para ẹ̀. Síbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè fara da ẹ̀dùn ọkàn tó bá a. Ó sọ pé: “Mi ò lè sọ pé ó dùn mí ju bó ṣe dun àwọn òbí mi lọ o, àmọ́ mo rò pé àwọn mọ bí wọ́n ṣe lè yí i dá ju èmi lọ.”
Ṣé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò tìẹ náà ti ṣaláìsí bíi ti Karen? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣe ìwọ náà bíi ti Dáfídì, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù, ó ní: “Mo ti di aláìbalẹ̀-ọkàn, mo ti tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó; láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́.” (Sáàmù 38:6) Báwo lo ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn náà?
“Ká Ní . . . ”
Bí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ bá para ẹ̀, ìyẹn lè mú kó o máa dára ẹ lẹ́bi ṣáá. O lè bẹ̀rẹ̀ sí sọ fúnra ẹ pé, ‘ká ní mo ti ṣe nǹkan kan ni, ẹni yìí ì bá má sì ti para ẹ̀ o.’ Ó lè dà bíi pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] ni Chris nígbà tí àbúrò ẹ̀ tí ò ju ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] para ẹ̀. Chris gbà pé ọ̀rọ̀ ì bá máà rí bẹ́ẹ̀ ká lóun ti ṣe nǹkan kan ni. Ó sọ pé: “Èmi sì ni mo bá a sọ̀rọ̀ kẹ́yìn o, ó yẹ kí n ti mọ̀ pé nǹkan kan ń ṣe é. Ká ní mo ti jẹ́ kó sún mọ́ mi jù bẹ́ẹ̀ yẹn lọ ni, bóyá ì bá sì ti sọ tinú ẹ̀ fún mi.”
Ohun tó mú kí ẹ̀dùn ọkàn tó bá Chris túbọ̀ mu ún lómi ni pé àárín òun àtàbúrò ẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ gún. Ọkàn ẹ̀ bà jẹ́ gan-an bó ṣe ń sọ ohun tó rí nínú ìwé tí àbúrò ẹ̀ kọ sílẹ̀ pé: “Mi ò ṣe dáadáa tó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sóun, òótọ́ ni pé ó lè jẹ́ ohun tó ń ṣe é ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀ o, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ yẹn ò yé bà mí lọ́kàn jẹ́.” Béèyàn bá tún ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ líle téèyàn ti sọ sí ẹni yẹn kó tó para ẹ̀, ọ̀rọ̀ ọ̀hún ò ní tán lọ́kàn ẹni bọ̀rọ̀. Ọ̀mọ̀wé White tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ fún akọ̀ròyìn Jí! pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò àwọn tó ti para wọn ló ti sọ fún mi pé àwọn kì í yé dá ara àwọn lẹ́bi torí èdè àìyedè táwọn ti ní pẹ̀lú ẹni yẹn lóṣù tàbí lọ́dún bíi mélòó kan kó tó kú.”
Bíwọ náà bá ń dára ẹ lẹ́bi torí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ kan tó para ẹ̀, béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé, ‘Ṣé èèyàn kan wà tó lè darí gbogbo ohun tẹ́lòmíì bá ń ṣe?’ Karen sọ pé, “Ìwọ kọ́ lo máa mú ìyà tó ń jẹ ẹni tó para ẹ̀ yẹn kúrò, bẹ́ẹ̀ lo ò sì lè ṣe nǹkan kan sí pípa tó para ẹ̀.”
Àmọ́ tó bá dà bíi pé àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tó o ti sọ sí i ò kúrò lọ́kàn ẹ ńkọ́? Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ náà. Ó sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé.” (Jákọ́bù 3:2; Sáàmù 130:3) Ká sòótọ́, tó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ máa ronú lórí àwọn ìgbà tó o rò pé o ò ṣe dáadáa tàbí ìgbà tó o rò pé o ti sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ẹni tó ti ṣaláìsí yẹn, ńṣe ni wàá kàn máa dá kún ẹ̀dùn ọkàn tó ń dà ẹ́ láàmú. Bó ti wù kọ́rọ̀ náà burú tó, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìwọ kọ́ lo pa á.b
Bó O Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀dùn Ọkàn
Kò séèyàn méjì tí ọ̀rọ̀ máa ń rí bákan náà lára wọn. Pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lomi máa ń dà lójú àwọn ẹlòmíì tí wọ́n bá ń sunkún ní gbangba, kò sì sóhun tó burú ńbẹ̀. Bíbélì sọ pé Dáfídì “sunkún pẹ̀lú ẹkún sísun gidigidi” nígbà tí Ámínónì ọmọ rẹ̀ kú. (2 Sámúẹ́lì 13:36) Kódà Jésù pàápàá “da omijé” nígbà tó rí bí ọkàn àwọn èèyàn ṣe bà jẹ́ tó torí ikú Lásárù.—Jòhánù 11:33-35.
Àmọ́ àwọn ẹlòmíì kì í tètè sunkún, pàápàá tó bá jẹ́ pé ikú òjijì ló wáyé. Karen sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, ó ní: “Mi ò mohun tí ǹ bá ṣe. Ńṣe ni jẹbẹtẹ gbọ́mọ lé mi lọ́wọ́, gbogbo nǹkan sì wá tojú sú mi.” Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń ṣe nìyẹn nígbà tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wọn bá para ẹ̀. Ọ̀mọ̀wé White sọ fún akọ̀ròyìn Jí! pé: “Ńṣe ló máa ń báni lójijì, ohun kan lèèyàn sì máa kọ́kọ́ ṣe nígbà tó bá gbọ́, kó tiẹ̀ tó di pé ẹ̀dùn ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí dé. Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ògbóǹkangí nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tírú ìṣòro yìí bá wáyé sábà máa ń sọ fáwọn èèyàn ẹni tó kú náà pé kí wọ́n sunkún kí wọ́n sì dárò ẹni yẹn nígbà tí kò tí ì wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bọ́rọ̀ yẹn ṣe bá wọn lójijì kì í jẹ́ kí wọ́n mohun tí wọ́n máa ṣe.”
Ó máa gba àkókò díẹ̀ kọ́rọ̀ náà tó lè kúrò lọ́kàn ẹ torí pé ọ̀rọ̀ kékeré kọ́ lọ̀rọ̀ ikú ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni. Chris sọ pé: “Ìdílé wa dà bí àwo tó ti fọ́ tá a tún wá lẹ̀ pa dà, ìgbàkigbà ló tún lè fọ́, ojú àpá ò sì lè jọ ojú ara. Àtiwá fara da ohun tí kò tó nǹkan pàápàá wá dọ̀ràn.” O lè ṣe àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí kó o bàa lè kojú ìṣòro náà:
◼ Kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ń tuni nínú sílẹ̀, kó o sì máa kà wọ́n, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́.—Sáàmù 94:19.
◼ Finú han alábàárò kan tó láàánú lójú. Ara lè tù ẹ́ tó o bá sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fẹ́nì kan.—Òwe 17:17.
◼ Máa ronú lórí ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde.—Jòhánù 5:28, 29.
O tún lè kọ bọ́rọ̀ náà bá ṣe rí lára ẹ sílẹ̀, bí ò tiẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ, ìyẹn ò ní jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn mu ẹ́ lómi ju bó ṣe yẹ lọ. O ò ṣe fi àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí dánra wò?
Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:20) Ó mọ àwọn ohun tó fa ìrora ọkàn fún ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Ó tún mọ ìwọ alára dáadáa ju bó o ṣe mọra ẹ lọ. (Sáàmù 139:1-3) Torí náà, fọkàn balẹ̀, Ọlọ́run mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. Bó bá dà bíi pé ẹ̀dùn ọkàn fẹ́ mu ẹ́ lómi jù, máa fọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 55:22 sọ́kàn pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”
Tu Àwọn TóŃ Ṣọ̀fọ̀ Nínú
O tún lè mọ púpọ̀ sí i nípa ohun téèyàn lè ṣe bí èèyàn ẹni bá kú tó o bá ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé náà.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
b Bákan náà lọ̀rọ̀ rí bó bá jẹ́ pé àìsàn tàbí jàǹbá ló fà ikú onítọ̀hún. Kò sí bó o ṣe lè fẹ́ràn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ tó, o ò lágbára kankan lórí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.”—Oníwàásù 9:11.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Ta lo lè finú hàn, bó bá dà bíi pé ẹ̀dùn ọkàn fẹ́ mu ẹ́ lómi jù?
◼ Ìrànlọ́wọ́ wo lo lè ṣe fún ọ̀dọ́ kan tó bá ń ṣọ̀fọ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Bó o bá kọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ sílẹ̀, ìyẹn lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá ń ṣọ̀fọ̀. Fi èyí sọ́kàn nígbà tó o bá ń kọ ọ̀rọ̀ sínú àwọn àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí, tó o sì ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
❖ Àwọn nǹkan dáadáa mẹ́ta tí mo rántí nípa ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi rèé:
1 ․․․․․
2 ․․․․․
3 ․․․․․
◼ Ohun tí mo rò pé ǹ bá ti sọ fún ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi nígbà tó ṣì wà láàyè ni:
․․․․․
◼ Kí lo máa sọ fún ẹnì kan tí kò tó ẹ lọ́jọ́ orí, tó ń dá ara ẹ̀ lẹ́bi nígbà tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ̀ kú?
․․․․․
◼ Èwo nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ló tù ẹ́ nínú jù lọ, kí sì nìdí?
□ “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
□ “Òun kò tẹ́ńbẹ́lú bẹ́ẹ̀ ni kò kórìíra ìṣẹ́ ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́; kò sì fi ojú pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí ó sì kígbe pè é fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́.”—Sáàmù 22:24.
□ “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.