Ìṣòro Tó Lè Wáyé
KÒ BỌ́GBỌ́N mu láti rò pé ìgbéyàwó lè wà láìní ìṣòro. Ó ṣe tán, tọkọtaya tó mọwọ́ ara wọn pàápàá ò ní ṣaláì ní ibi tí wọ́n kù sí. Torí náà, kò lè ṣe kí ìṣòro má wà. Bí irin tí wọ́n fi ọ̀dà kùn ṣe lè máa dán lójú, síbẹ̀ kó máa dógùn-ún lábẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ṣe lè má yọ́ kẹ́lẹ́ ba ìgbéyàwó jẹ́. Ká bàa lè mọ ohun tá a lè ṣe láti mú kí ìgbéyàwó sunwọ̀n sí i, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó lè wáyé.
Àkókò Tí Ìṣòro Á Máa Gorí Ìṣòro
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lákòókò tá à ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn á jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:2-4) Bá a bá wá fi àìpé ẹ̀dá kún ohun tí Bíbélì ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, ńṣe lá á mú kí èdèkòyédè, àṣìsọ àti kòbákùngbé ọ̀rọ̀ máa pọ̀ sí i.
Olùṣèwádìí kan tiẹ̀ sọ pé: “Àkókò tó ń kọni lóminú jù lọ láti ṣègbéyàwó là ń gbé yìí. Torí pé bá a bá ní ká wò ó . . . , òbítíbitì ìsọfúnni tó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà lóǹkà ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó lórí ọ̀nà tá a lè gbà mú kí ìgbéyàwó wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ . . . Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìṣòro nípa ìbágbépọ̀ àti ọ̀ràn ìnáwó ń mú kó ṣòro fún wa láti gbé pọ̀ bíi tọkọtaya láìjà, láìta.”
Ríro Ìgbéyàwó Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ
Ẹnì kan tó máa ń báwọn èèyàn wá ojútùú sí ìṣòro ìgbéyàwó tiẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ríro ìgbéyàwó ju bó ṣe yẹ lọ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa ń fa àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú ìgbéyàwó.” Bí àlá ló máa ń ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tó ti ṣègbéyàwó nígbà tí wọ́n bá rí i pé ohun táwọn rò nípa ìgbéyàwó kọ́ làwọn bá níbẹ̀, àti pé ẹnì kejì àwọn ò rí báwọn ṣe lérò pó máa rí. Wọ́n á kàn máa fi orúnkún tẹ̀pá ìrònú ṣáá nípa àwọn àléébù ẹni kejì wọn tó fara sin fún wọn tẹ́lẹ̀ tàbí àṣìṣe tó burú jáì tí wọ́n rò pé àwọn lè gbójú fò dá.
Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ ṣe máa rí gan-an nígbà tó sọ pé ìgbéyàwó lè fa “ìpọ́njú.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Kí nìdí? Ìdí kan ni pé bí ẹni méjì tó jẹ́ aláìpé bá jọ ń gbé pọ̀, bó pẹ́ bó yá wọ́n á rí àléébù ara wọn.
Ohun mìíràn ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ láti máa jadùn ìgbéyàwó láì fara ṣiṣẹ́ fún un. Dídùn dídùn ṣáá ni wọ́n ń rò nípa ìgbéyàwó débi tí wọ́n á fi gbójú fo ojúṣe àti iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí ìgbéyàwó máa báa máa já sí òní eré, ọ̀la ìjà. Bí wọ́n bá wá rí i pé ìgbéyàwó ò já sí báwọn ṣe rò, ó ṣeé ṣe kí nǹkan tojú sú wọn kí wọ́n má sì mọ èwo ni ṣíṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí ohun tí wọ́n ń rí nínú ìgbéyàwó bá ṣe yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n ń rò nípa ẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa tojú sú wọn tó.
Wàhálà Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Ń Dá Sílẹ̀
Irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wo ló yẹ kí tọkọtaya yẹra fún kí àárín wọn lè gún? Ìṣòro àwọn tọkọtaya kan ni pé wọn kì í gbọ́ra wọn yé, wọ́n kì í sì í sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. Dípò kí wọ́n jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀ tẹ̀rín-tẹ̀yẹ, wọ́n á máa di kùnrùngbùn síra wọn. Èyí tí wọn ì bá sì fi sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣe gúnmọ́ tàbí kí wọ́n sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn, ńṣe ni wọ́n á máa jiyàn kùrà lórí ohun tí kò tó nǹkan. Àṣìgbọ́ á máa yọrí sí àṣìlóye; lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti gbé e gbóná fúnra wọn tan, ó di kí wọ́n máa yan ara wọn lódì.
Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni kì í kíyè sí ohun rere tí ẹnì kejì wọn ṣe, bí wọ́n bá sì kíyè sí i, wọn kì í fìmọrírì hàn fún irú ohun rere bẹ́ẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́, láyé tí ọkọ àti aya ti ń ṣiṣẹ́ yìí, inú máa ń bí ọ̀pọ̀ aya torí pé àwọn ọkọ máa ń dá wọn dá iṣẹ́ ilé lẹ́yìn tí wọ́n bá tibi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ dé. Òmíràn sì tún ni pé ọ̀pọ̀ aya máa ń ronú pé àwọn ọkọ kì í gbọ́ tàwọn.
Kí lo lè ṣe tí ìgbéyàwó rẹ ò fi ní máa jẹ́ òní eré, ọ̀la ìjà? Gbé àwọn ìmọ̀ràn tó gbámúṣé tó wà nínú Bíbélì yẹ̀ wò.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Àwọn tọkọtaya kan kì í gbọ́ra wọn yé, wọn kì í sì í sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ọ̀pọ̀ èèyàn ń fẹ́ láti máa jadùn ìgbéyàwó láì fara ṣiṣẹ́ fún un